Makinde lóùn ṣetán láti ṣàtúntò Nàíjíríà lọ́dún 2027

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo ti sọ pe ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Naijiria loun fẹẹ mu kuro ninu iṣẹ ati oṣi, eyi to ti n ba wọn finra lati bi ọdun mẹta le diẹ sẹyin, nitori agbekalẹ ti ko dara.
Makinde lo sọrọ naa nibi ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu All Peoples Movement, APC to waye nipinlẹ Bauchi l'Ọjọbọ, ọsẹ yii.
Gomina Oyo to n jade du ipo Aarẹ ilẹ Naijiria ninu eto idibo apapọ ọdun 2027 jẹ ko di mimọ pe oun yoo ṣiṣẹ ẹplu awọn to ni ọkan bii toun lati rii pe Naijiria de ipo ti awọn araalu n foju sọna fun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yii ni Makinde fi erongba rẹ han sita lati jade du ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo.
O kede yii nita gbangba nibi ipolongo to ṣe, nibi to ti ti fi to gbogbo eeyan leti pe oun ti kuro lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP to gbe oun wọle.
Makinde ni oun ko deedee jade fun ipo aarẹ, bi ko ṣe lati ṣe atunto ilẹ Naijiria, ati pe afojusọna bayii ni lati jẹ ki ipo naa ja mọ oun ati ẹgbẹ APM lọwọ.
Siwaju sii lo sọ pe kii ṣe iṣẹ kekere ni lati gba ipo lọwọ iṣakoso o wa nibẹ, to si ni iṣẹ nla ni eto idibo ọdun 2027 yoo jẹ.
O ni ohun to dara ni lati fun awọn ọmọ Naijiria ni oludije to kaju oṣuwọn lati gba wọn kuro ninu iya ati ipenija ti wọn n doju kọ, pẹlu ileri wi pe ọjọ iwaju Naijiria yoo dara labẹ iṣakoso oun.
Bẹẹ ni lo awọn yoo too gbe awọn inagijẹ fun eto idibo ọdun 2027 jade, bi ipolonogo ba bẹrẹ ni pẹrẹu, ati pe ki awọn araalu maa foju sọna lato yan ẹni to le mu wọn tẹsiwaju ninu ohun gbogbo.
"Bi a ti n sunmọ ọdun 2027, mo nigbagbọ pe ojuṣe nla lo wa niwaju wa, eyi to kọja ka bori idibo nikan. O wa lati fun awọn ọmọ Naijiria ni ọna abayọ lati fun ilẹ yii ni ọjọ iwaju rere," Makinde sọ bẹẹ ninu ọrọ rẹ.
Makinde kede Daura gẹgẹ bi igbakeji fun ipo aarẹ
Nibi eto naa lo tun ti kede Lawal Daura gẹgẹ bi ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ fun ipo aarẹ ninu eto idibo apapọ ọdun 2027.
Daura ni ọga agba fun ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS nilẹ Naijiria nigba kan ri.
Makinde sọ pe kii ṣe pe oun deedee yan Daura gẹgẹ bi igbakeji, bi ko ṣe lati bojuto ohun gbogbo to nii ṣe pẹlu ọrọ eto aabo nilẹ Naijiria.
Taani Lawal Daura?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 1953 ni wọn bi Lawal Daura, to si kẹkọọ gboye ni fasiti Ahmadu Bello to wa ni Zaria, bẹẹ lo tun kẹkọọ siwaju ni National Institute of Policy and Strategic Studies niluu Kuru.
Ọdun 1982 ni Daura darapọ mọ ajọ eleto aabo National Security Organization (NSO), eyi ti wọn pada yi orukọ rẹ si SSS, ko to tun pada di DSS bayii.
O ṣiṣẹ nileeṣẹ naa kaakiri Naijiria bii Kano, Sokoto, Edo, Eko, Osun ati Imo.
Lawal Daura ni ọga agba tẹlẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS nilẹ Naijiria, ati pe ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2015 ni Aarẹ Muhammadu Buhari to ti doloogbe yan an, ko to di pe igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo jawe gbele ẹ fun un lọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun 2015.
Daura ti figba kan ri jẹ oludije sipo gomina ipinlẹ Katsina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC.
Ọọ Aiku to kọja yii ni Daura kede pe oun ko le tẹsiwaju mọ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, ati pe oun ti ba ẹgbẹ oṣelu APM lọ.



























