Wo àwọn ilẹ̀ àti dúkìá tí ìjọba àpapọ̀ ṣèkìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ rà ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ ti ṣekilọ fawọn olugbe ipinlẹ Oyo ati agbegbe lati ṣe iwadii ki wọn to ra ilẹ tawọn kan n polongo rẹ ni ipinlẹ naa lẹnu ọjọ mẹta yii.
Ninu atẹjade kan ti Shuaib Belgore, ẹni to jẹ akọwe agba fun ileeṣẹ to n ri si igbasoke agbegbe ati ibugbe fun ijọba apapọ, iyẹn Federal Ministry of Housing and Urban Development ni wọn ti ṣekilọ naa.
Belgore ninu atẹjade naa ṣalaye pe gbogbo awọn ibi ti won darukọ ninu atẹjade ọhun lo jẹ dukia ijọba apapọ, awọn ileeṣẹ ijọba apapọ atawọn alabaaṣiṣẹpọ ijọba apapọ nilẹ okeere.
O ni awọn dukia ati ilẹ naa ni ko si fun tita, pe ẹnikẹni to gbiyanju lati ra a tabi to ti ra a n ṣe owo ti ko tọna ni.
Atẹjade naa fi kun pe ijọba apapọ ko gbiyanju lati ta ilẹ tabi awọn dukia naa, ti wọn ko si fun ẹnikẹni ni aṣẹ lati dunaadura lori awọn dukia naa.
Wọn rọ awọn eeyan lati ma gbiyanju lati ra awọn ilẹ naa lọwọ ẹnikẹni nitori wọn ko si fun tita.
Lara awọn ibi ti wọn kede pe ko si fun tita, ti wọn si ki awọn eeyan nilọ nipa rẹ niyi:
- Dukia Africa Regional Centre for Engineering Design and Manufacturing
- (ARCEDEM), ti ilẹ rẹ to hẹkita 73.95, to wa ni agbegbe Iwo Road, Olodo ni ijọba ibilẹ Lagelu, Ibadan.
- Ilẹ ati dukia Federal Low-Cost Estate and Site and Services ti ilẹ rẹ wọn to hẹkita 51.982, to wa ni agbegbe Idi- Ayure ni ilu ibadan.
- Ilẹ ati dukia to wa fun eto ile gbigbe ti ijọba apapọ fẹ kọ iyẹn Federal Housing Scheme program ti ilẹ rẹ to hẹkita 90.61to wa ni ilu Saki.
- Ilẹ ati dukia ajọ National Strategic Grain Reserve Programme to jẹ dukia ileeṣẹ to n ri si eto ọgbin fun ijọba apapọ ti ilẹ rẹ to hẹkita 10.002, to wa ni agbegbe Iyande Church Area, ilu Ibadan.
- Ilẹ ati dukia ileeṣẹ redio ijọba apapọ, Radio Nigeria ti apapọ ilẹ rẹ jẹ hẹkita 4.89, to wa ni agbegbe Basorun, ilu Ibadan.
- Ile ati dukia National Horticultural Research Institute Property to wa ni agbegbe Alalubosa, Alesinloye ni ilu Ibadan.
Gbogbo awọn ilẹ ati dukia yii ni ijọba ka pe wọn jẹ dukia ijọba apapọ ti wọn ko si gbiyanju lati ta ọkọọkan ninu, ti wọn si rọ awọn araalu lati ma da a ẹnikẹni to ba n gbiyanju lati sọ fun wọn pe ki wọn ra a, ki wọn ma ba a fi owo jona.



























