BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìjọba Nàìjíríà, Atiku kẹ́dùn ikú Olu Jacobs
Aarọ Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn mọlẹbi Olu Jacobs kede ipapoda rẹ.
Kò sí gómìnà tó ní àṣẹ láti dá iṣẹ́ ẹgbẹ́ awakọ̀ NURTW dúró ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ - NURTW ṣèkìlọ̀ fún Gómìnà Adeleke l'Osun
Nibẹ ni wọn ti sọ pe igbesẹ Gomina Ademola Adeleke lati dawọ gbogbo iṣẹ NURTW nipinlẹ Osun ko ba ofin ati ilana ti wọn fi da ẹgbẹ wọn silẹ mu.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,58
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Fídíò, Mo fẹ́ ìyàwó mẹ́rin ni Ilorin, a sì jọ ń lo Ásìkí ara wa- Baba Aremu Alapata, Duration 2,51
Aremu ni oun gbagbọ oun ati awọn iyawo oun merin jọ n lo arísìkí ara wọn ti nnkan ti rọrun fun wọn titi di asiko yii.
A ò fẹ́ irú àjọṣepọ̀ tí ò ń bèèrè fún – Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlù APC kẹyìn sí Fayose lórí ìbò 2027
Nyesom Wike wa sọ pe Aarẹ Bola Tinubu loun ba da owo pọ kii ṣe awọn gomina APC.
Agbébọn darandaran pá ọlọ́pàá méjì, ṣe ọ̀gá ọlọ́pàá léṣe ní Benue
Aondongu ọ pe ọga ọlọpaa ẹkun ọhun lọ gba nnkan niluu Makurdi , ati pe asiko toun pẹlu ikọ akọwọrin rẹ n pada lọ si ibudo wọn, ni awọn agbebọn naa da wọn lọna.
Àwọn aráàlú faraya bí wọ́n ṣe ṣàwárí òkú obìnrin méje láàárín oṣù méjì síra wọn ní agbègbè kan náà
Minisita fọrọ awọn ọlọpaa ni South Africa, Firoz Cachalia fi aidunu rẹ lori ipaniyan naa han, to si ba ẹbi awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn kẹdun.
Ọwọ́ tẹ afurasí agbébọn márùn-ún lẹ́yìn ìkọlù silé iṣẹ́ ọmọ ogun ní Igbeti ní Oyo
Awọn afurasi marun-un naa ni wọn mu lasiko ti wọn ri wọn ninu aṣọ ọmọ ologun ninu igbo Ọba to wa ni agbegbe ọhun.
Ẹ ò gbọdọ̀ fá wàhálà kan - Imam mọ́ṣáláṣí tí wọ́n gún lọ́bẹ lẹ́yìn àdúrà fohùn ránṣẹ́
Ijọba ipinlẹ naa tun ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii to peye lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun pẹlu ikede pe mọṣalaṣi naa ti di ibi ti wọn ti wuwa ọdaran.
Igbó ni wọ́n ń gbìn dípò kòkó káàkiri oko ní ìpínlẹ̀ Edo báyìí - NDLEA
Ofoyeju sọ pe igbo ti awọn eeyan n gbin, lo ti n rọpo awọn ohun jijẹ to yẹ ki wọn maa fi oko ati igbo gbin bayii, leyi to si le ṣe akoba pupo fun alaafia ilu.
Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn lórí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun
Nibi ikọlu to waye ni garaaji Mayfair naa ni wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ naa, Olalekan Oyeymi, ẹni tọpọ mọ si Emir Ajagungbade.
Ìdí tí JAMB fi sún àkókò tí akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ dé gbàgede ìdánwò CBT síwájú
Gẹgẹ bii JAMB ṣe sọ, ẹredi atunṣe naa ko ṣẹyin ewu to le de ba awọn akẹkọọ ti wọn ba rinrinajo lọ kọ idanwo naa ni afẹmọju.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Àwọn olólùfẹ́ Kola Oyewo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìsìnkú rẹ̀, Duration 3,24
Tẹ o ba gbagbe, Oloye Oyewo jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii lẹni ọgọrin ọdun.
Ìjọba ṣèkìlọ̀ lórí jíjẹ ẹran ìgbé bí ààrùn 'anthrax' ṣe gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ẹranko
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni orilẹ ede naa sọ pe eeyan mejila lo ti lugbadi aarun naa lopin ọsẹ lẹyin ti wọn je ẹran igbo kan ni agbegbe Munyamadzi River.
Kí nídìí tí INEC kò fi kéde orúkọ àwọn olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Accord àti NNPP?
Ninu orukọ naa ti INEC gbe jade, eyi ti akọwe rẹ, Rose Oriaran-Anthony, buwọ lu lọjọ Abamẹta to kọja niluu Abuja, lo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn oludije naa ni ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun fi ranṣẹ si wọn.
Èèyàn mẹ́fà kú, 130 di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi dànù ní Indonesia
Eeyan 107 ni wọn ti doola ninu ijamba ọhun bayii lẹyin ti ọkọ oju omi Virgo Transport8 naa danu.
Wo ìdí tí Demond Elliot ṣe ń bẹ Femi Gbajabiamila lórí ìkúnlẹ̀
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni Elliot dalẹ Gbajabiamila, ẹkọ fi oju mimu han pe Elliot ti tẹ aṣọ agba mọlẹ ninu oṣelu ipinlẹ Eko lo ṣe n bẹbẹ lori ekun rẹ.
Fídíò, Àwọn dókítà ti sọ fún mi pé kí n dẹ́kun sígà fífà àti ọtí mímu-Tope Osoba. Nibo Laye Koju Si? , Duration 5,26
BBC Yoruba ti jade lọ sigboro lati beere ero awọn araalu nipa aṣa to gbode, eyi ti wọn n pe ni 'Olodo Uprising'.
Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tẹ afurasí tó po pàrágà tó gbẹ̀mí èèyàn 29
Ọwọ ọlọpaa tun tẹ awọn afurasi mẹrinla mii to n ta paraga lagbagbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Wọ́n ti sìnkú Iyeru, ọ̀gá NURTW Ogun tó jade láyé - ìjọba ìpínlẹ́ Ògùn kẹ́dùn
Latigba ti iroyin ibanujẹ ọhun ti jade, ni ọpọ awọn to mọ ọkunrin naa ti bẹrẹ sii kẹdun, ti awọn miran si n barajẹ.
Làásìgbò tún bẹ́ sílẹ̀ ní gáráàjì Ile Ife, èèyàn kan jáde láyé, Gómìnà Adeleke ní kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Iroyin ni Ajagungbade atawọn eeyan ti wọn jọ wa ni garaaji ni ija bẹ silẹ laaarin wọn, ti wọn yinbọn fun-un ṣugbọn ti idi ti wọn fi yinbọn pa ko i tii ye ẹnikẹni titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Ìdí tí ìjọba fi fòfin de títa ọtí tí kò bá ní nọ́mbà NAFDAC lára l'Ondo
Atẹjade ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ naa, Idowu Ajanaku fi sita lọjọ Abamẹta to kọja fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lati dẹkun iku awọn araalu lọna aitọ.
Àwọn agbébọn ti ń dúnkokò láti wọ ilẹ̀ Ibadan - Balogun ké gbàjarè
Ṣaaju ni lẹta kan ti n lọ lori ayelujara eyi ti eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ A M Sodiq kọ ranṣe si ileeṣẹ Ologun Naijiria lati fẹsun kan pe awọn agbebọn tun ti n gbero lati ṣekọlu sawọn aaye kan ni ẹkun ila oorun, iwọ oorun ati aarin gbungbun ariwa Naijiria to fi mọ guusu iwọ oorun Naijiria.
Ẹ wo ìlúbìnrin tó gbajúmọ̀ tí kò fi ààyè gba ọkùnrin láti máa gbé níbẹ̀
Gẹgẹ bi àṣà wọn nilubinrin yii, eewọ ni fun awọn obinrin naa lati ni ọkọ, àmọ́ wọn le mu ọkunrin wá lati abule mii, ko le fun wọn loyun.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìjọba jáwé ìkìlọ̀ fún South Africa bí ọmọ Nàìjíríà méjì míì ṣe tún pàdánú ẹ̀mí wọn
Atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Oluwafemi Adeniyi fi lede bu ẹnu atẹ lu iku awọn eeyan naa paapaa lasiko tawon eeyan ilẹ Africa ṣe n koju ipa ti ikọlu Xenophobic ati Aphrophobic n ni lara awọn eeyan ni South Africa.
Fídíò, Ṣé lóòtọ́ọ́ ni àwọn ẹ̀gbọ́n Ademola Adeleke ti já àkóso ìjọba Osun gbà mọ́ ọ lọ́wọ́? Àlàyé rèé, Duration 2,54
BBC News Yorùbá kàn sí gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke láti fèsì sáwọn ẹ̀sùn tí wọn fi kan àwọn ẹgbọn rẹ pé wọn ti já àkóso ìjọba gbà mọ́ ọ lọ́wọ́.
Ǹjẹ́ Trump le san ẹgbẹ̀rún márùn-ún dọ́là fún èèyàn kọ̀ọ̀kan ní Amẹ́ríkà?
Trump ko ytan imọlẹ si i nipa bi wọn yoo ṣe ṣagbatẹru owo naa, bo tilẹ jẹ pẹ igbakeji rẹ, JD Vance sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ileeṣẹ to n gba owo ori ni yoo san owo naa, ati pe awọn olowo nilẹ Amẹrika ko nii lanfaani si owo naa.
Wo àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láti kékeré tí àyẹ̀wò DNA sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n
Ile ọmọ alainiya ni obi ọtọọtọ ti gba Meena Geltink ati Minal Tijssen tọ ni nnkan bi ogoji ọdun o le diẹ sẹyin ni orilẹede Netherlands.
Fídíò, Àwọn sinimá kan wà tí mo ṣe tí àwọn òbí mi kò lè wò nítorí… - Bolaji Ogunmola, òṣèré tíátà, Duration 4,02
O ṣalaye pe ko rọrun fun oun lati gbe ipinnu oun kalẹ niwaju awọn obi oun pe iṣẹ sinima loun fẹ ṣe jẹun, wọn ko tẹwọ gba a rara.
Akẹ́kọ̀ọ́ 24 jóná mọ́lé níléẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀, 21 míràn wà lẹ́sẹ̀-kan-ayé-ẹsẹ̀-kan-ọ̀run
Ọmọdebinrin mọkandinlogun ati ọmọdekunrin marun un ni ina naa jo pa.
Orí mi ni Garuba fẹ́ gé féú, ọwọ́ tí mo fi dáàbòbo ara mi, ló padà fi àdá ọwọ́ rẹ̀ gé – Adájọ́ tí olújẹ́jọ́ fi àdá gé lọ́wọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́ sọ̀rọ̀ síta
Awọn eeyan to wa ninu yara igbẹjọ lo ka ọkunrin naa lọwọ ko, gba ada ọwọ rẹ ti wọn si gbe adajọ lọ sile iwosan fun itọju
APC fagilé ẹjọ́ tí wọ́n pè tako èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ́ Osun tó gbé Adeleke wọlé fún sáà kejì
Amofin Seyi Oyagbile lo pe ẹjọ naa lọjọ kẹjọ oṣù Kẹsán an yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ati lorukọ oludije ẹgbẹ naa, Bola Oyebamiji.
Kí ló dé tí iléeṣẹ́ ọmọogun fi gbé adarí ikọ̀ tó ń gbógun ti Boko Haram àtàwọn agbébọn kúrò pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun 15 míràn? Ohun tí a mọ̀ rèé
Awọn ti ọrọ naa kan lawọn ọgagun ti wọn wa nipo Major General ati Brigadier General.
Ìṣẹ́ alájótà, àtàwọn ohun tuntun míràn tí o kò mọ̀ nípa Temitope Osoba, gbajúmọ̀ òṣèré tí wọ́n ń sin òkú rẹ̀ lónìí
Ṣaaju iṣẹ tiata, tipẹtipẹ ko too bẹrẹ sii farahan ninu awọn ere agbelewo, lo ti n ṣiṣẹ alajota, to si tun n jo ninu awọn awo orin loriṣiriṣi.
Kò sí orúkọ Oriyomi Hamzat tàbí Gudugudu gẹ́gẹ́bí olùdíje sípò Gómìnà fẹ́gbẹ́ Accord nínú àkọsílẹ̀ INEC ní ìpínlẹ̀ Oyo - Ìwádìí BBC
Iwadii BBC News Yoruba si ọfiisi ajọ eleto idibo INEC ẹka ipinlẹ Oyo fi han wi pe ko si orukọ oludije sipo gomina lati inu ẹgbẹ oṣelu Accord kankan ninu orukọ awọn oludije sipo gomina to wa ninu akọsilẹ INEC fun eto idibo ọdun 2027.














































































