Olu Jacobs, àgbà òṣèré wọ káà ilẹ̀ sún l'Ekoo

Oloogbe Oludotun Bayewun Jacobs lapa osi, awọn to gbe posi oku rẹ lọjọ isinku naa lapa ọtun.
Àkọlé àwòrán, Oloogbe Oludotun Bayewun Jacobs lapa osi, awọn to gbe posi oku rẹ lọjọ isinku naa lapa ọtun.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àwọn ẹbí àgbà osere nnì tó di olóògbé, Oludotun Bayewun Jacobs, tí ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fún un pelu ìsìnkú rẹ tó wáyé nílùú Eko.

Ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kejì oṣù Kẹwàá ọdún 2026 yìí ni wọn sìnkú Olú Jacobs si itẹ òkú Ikoyi, niluu Eko.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ èèyàn ló peju pese si 'The Present House ti wọn tun n pe ni Freedom House', ni Lekki tí eto ìsìnkú náà tí bẹrẹ, àwọn ẹbí àti ojulumọ nìkan ni ìdílé Jacobs gba láyè lati ba won lọ sí ìte.

Bẹẹ naa si ni wọn ko fi aaye gba awọn akọroyin to bẹẹ ju bẹẹ lọ lati ri ohun to n lọ ninu gbọngan ti orin kikọ ati adura fun oku ṣaaju itẹ ti waye.

Ṣáájú níbi eto ìsìnkú náà ni aya Olóògbé, Joke Silva, ti wa nikale nínú aṣọ aláwò aro tó wọ.

Ọpo èèyàn tó ń de lo ba mama naa nikalẹ ti wọn si ba a ya fọto, ko too wọle sinu gbọngan ti wọn gbe posi oku ọkọ rẹ si.

Oloogbe Olu Jacobs lapa osi, iyawo rẹ; Joke Silva lapa osi pẹlu awọn eeyan to yi i ka a nibi eto isinku naa lapa ọtun.

Nnkan bii aago mejila ọsan kọja diẹ ni wọn gbe oku Oloogbe Olu Jacobs jade pada lati inu gbọngan naa, wọn gbe e wọnu ọkọ ti yoo gbe e lọ si itẹ oku Ikoyi.

Lára àwọn eeyan pataki to wa ni gbọngan tie to naa ti waye ni:

Iyawo Gomina Eko; Ibijoke Sanwo-Olu, Igbakeji gomina ipinlẹ Eko; Obafemi Hamzat, Erelu Bisi Fayemi; Iyawo Kayode Fayemi ti I ṣe gomina tẹlẹ l'Ekiti, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn oṣere tiata Yoruba diẹ atawọn ti ẹya Igbo naa wa nibẹ pẹlu, kaluku wọn sọrọ iwuri nipa Oloogbe Olu Jacobs, wọn ni alafo to fi silẹ yoo ṣoro lati ri ẹni ti yoo dí i.

Ta a ni Olu Jacobs?

Ọjọ kọkanla, oṣu Keje ọdun 1942 ni wọn bi Olu Jacobs.

Ọmọ bibi ilu Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun ni baba ati iya rẹ, ṣugbọn ipinlẹ Kano lo ti ṣe kekere rẹ, to si lọ sile ẹkọ Holy Trinity nibẹ.

Gbara ti Olu Jacobs ti de ile-ẹkọ naa lo ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣere ti awọn akẹkọ nibẹ.

Lasiko to wa nibẹ, Olu Jacobs ni anfaani lati kopa ninu ere ori itage ti Hubert Ogunde lọ ṣe nipinlẹ Kano, iyẹn nile itura Colonial.

Ilu Kano naa ni Jacobs ti ri anfaani lati lọ siluu oyinbo, iyẹn orileede England, lati kẹkọọ nipa ere ori itage.

Nibẹ lo ti darapọ mọ ile-ẹkọ "The Royal Academy of Dramatic Arts" niluu London.

Ọkan lara awọn ipa to ko nigba naa ni 'The Boy', ninu ere 'A Taste of Honey' ni ile aworan Crucible Theatre to wa ni Sheffield, lọdun 1972.

Ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin ni Joke Silva sọrọ lori ailera ọkọ rẹ, Olu Jacobs.

Bi aisan ṣe bẹrẹ si Olu Jacobs

Bo tilẹ jẹ pe o ti to ọdun meloo kan ti Oloogbe Olu Jacobs ti kopa ninu ere tiata kẹyin ko to di pe o bẹrẹ aarẹ, amọ o yọju sibi ayẹyẹ ere ori itage kan, Africa International Film Festival Awards, AFRIFF, to waye niluu Eko lọdun 2021.

Nibẹ ni ọpọ eeyan ti ri pe gbajumọ osere tiata naa ti ru pupọ, eyi to fihan pe aisan n yọ ọ lẹnu, ti agba si ti de si i.

Ninu ifọrowerọ pẹlu awọn akọroyin nigba naa, Joke Silva sọ pe o ti to ọdun diẹ sẹyin ti Olu Jacobs ti n ba aisan to maa n mu ki eeyan gbagbe nnkan, Dementia, finra.

Ninu aisan naa ni ọlọjọ ti de si Olu Jacobs lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2026, ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin ni i ṣe.