Ibo ni ìwádìí dé dúró lórí àgúnmu tó gbẹ̀mí èèyàn 49 l'Ondo?

Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Ondo ti ke gbajre sita pe awọn kan ti ṣi ileeṣẹ kan ti wọn gbe tipa tẹlẹ, nibi ti kẹmika ti wọn fura si pe kẹmika to wa ninu agbo jẹdi to gbemi eeyan to le ni ogoji ni Odigbo ti ṣe wa.

Gẹgẹ bii ijọba ipinlẹ naa ṣe sọ, awọn kọlọrọsi to ja agadagodo ti wọn gbe sẹnu ọna ileeṣẹ naa ti ko awọn kẹmika ti awọn fẹ ṣeadii le lori lọ ki iwadii naa le fori ṣọpan.

Akọwe agba ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ naa, Ayodele Ojo Adiji, lo fidi iroyin naa mulẹ.

Adiji sọ pe awọn agba kan wa ninu ileeṣẹ naa ti wọn kọ 'ethanol' si lara ti ijọba gbọdọ ṣe iwadii rẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko le fidi rẹ mulẹ pe eroja 'ethanol' lo wa ninu awọn agba ọhun, awọn kan ti lọ ja ileeṣẹ naa ki iwadii awọn to bẹrẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, iwadii ajọ to n gbogun ti egboogi oloro lilo, NAFDAC, ti kọkọ gbeṣe le awọn agbo jẹdi kan lagbegbe naa, eyiii ti wọn ni eroja 'methanol' wa ninu rẹ.

Eroja methanol ọhun buru to bẹẹ to le fọ eeyan loju to si le gbẹmi eeyan laipẹ ọjọ to ba wọ inu agọ ara ẹda.

Ẹwẹ, ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan mẹta lagbegbe ti ileeṣẹ naa wa lẹyin ti wọn ja ibẹ tan.

Lara awọn ti ọwọ tẹ ni ọgbeni kan ti orukọ rẹ n jẹ Matthew to sọ pe oun ni oluranlọwọ pataki si adri ileeṣẹ ọhun.

Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ondo ninu atẹajde kan sọ pe gbogbo awọn ti wọn mu ti wa lakata agbofinro fun iwadii, iṣẹ ti ti bẹrẹ lati mọ awọn to ni ileeṣẹ naa, ati lati mọ ibi ti wọn ko awọn kẹmika inu rẹ lọ ki wọn le mọ oibaṣepọ to wa laarin rẹ kẹmika naa atawọn to padanu ẹmi lẹyin ti wọn mu agbo jẹdi tan ni Odigbo.