Nkechi Blessing ṣubú yakata, Phyna fẹ̀ṣẹ́ fọ́ ọ lẹ́nu gba ẹ̀bùn ₦50m

Asiko ti Nkechi sun gbalaja ki ija to pari
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹni to gbegba oroke ninu idije Big Brother Naija nigba kan ri, Ijeoma Josephina Otabor, ti ọpọ mọ si Phyna ti fi agba han oṣere tiata, Nkechi Blessing, ninu idije ẹṣẹ kikan wọn to waye niluu Eko.

Asiko ti ija naa to waye nile itura Federal Palace, to wa lagbegbe VI, niluu Eko, de ipele kẹrin ni Phyna fi ẹṣẹ ranṣẹ si Nkechi ti Nkechi si ṣubu lulẹ rọgbọndọn.

Ija naa ni akọkọ iru rẹ fun awọn gbajumọ obinrin ni Naijiria, eyii ti ileeṣẹ Balmoral Promotions ṣe agbatẹru rẹ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Balmoral Promotions yoo ṣagbatẹru ẹṣẹ kikan laarin awọn gbajumọ ori ayelujara, eyii ti wọn n pe ni 'Chaos in the Ring' to maa n waye loorekoore.

Ere Phyna lẹyin to na Nkechi

Owo ti iye rẹ to aadọta miliọnu naira ni Phyna yoo gba lẹyin aṣeyọri naa, to fi mọ igbanu mo yege ati ọkọ ayọkẹlẹ tuntun.

Ija naa jẹ ọkan lara awọn nnkan ti ileeṣẹ ọhun fi ṣajọyọ ayajọ ominira Naijiria, eyii ti ilẹẹṣẹ Bet9ja ṣe onigbọnwọ rẹ ti awọn eeyan si wo lori ikanni SuperSport bo ṣe n lọ lọwọ.

Ninu ija naa, Phyna ja fafa ni ibẹrẹ nigba ti Nkechi kọkọ n gbe sunmọ alatako rẹ.

Nigba ti yoo fi di ipele kẹrin ni Phyna fi ẹṣẹ kan ṣọwọ si Nkechi ti ẹmi Nkechi ko si gbaa mọ.

Lẹyin ti Nkechi balẹ to si sun gbalaja ni rẹfiri to n ṣakosa ija naa bẹrẹ si n ka onka lati ẹni amọ o ti bọ sori nigba ti Nkechi yoo fi pada dide.

Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ija yii?

Lẹyin to fẹyin Nkechi gbolẹ tan ni Phyna bẹrẹ si n fi oko ọrọ ranṣẹ to oṣere tiata mii, Etinosa Idemudia lẹyin to ni Etinosa ti n fi ọrọ ranṣẹ si oun ṣsaju.

Etinosa, ti oun naa wa ninu gbagede ti ija oun ati Nkechi ti waye fesi pe ẹru ko ba oun, ati pe oun ṣetan lati koju Phyna lori papa.

Eyii n tumọ si pe o ṣeeṣe ki ija Phyna ati Etinosa waye laipẹ.

Phyna ti sọ ṣaaju pe yoo wu oun lati maa ja ẹṣẹ bii iṣẹ oojọ lọjọ iwaju.

Ẹwẹ, ni gbagede ija kan naa ni Carter Efe ti na Speed Darlington, ti ọmọ orilẹede Ghana nni, Seth 'Freezy Macbones' Gyimah si na Godday 'Zodsolo' Appah.