Ta ló ni agbárí èèyàn 28 tí ọlọ́pàá rí nínú aginjù, èyí tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ báyìí?

Aworan awọn egungun kan.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn to ni agbari ati egungun ti ko din ni mejidinlọgbọn ti wn ri gba lọwọ lawọn igbo ibuba awọn afurasi ọdaran kaakiri ipinlẹ Abia lẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria.

Lasiko ti awọn agbofinro n kaakiri lati ṣeto abo ni agbegbe Isuochi ni ijọba ibilẹ Umunneochi nibi ti iroyin gbọnmọgbọnmọ iwa ijinigbe ati iwa ipa ti n waye.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia, Maureen Chinaka ṣalaye pe agbari eeyan mejidinlọgbọn atawọn egungun eeyan ni wọn ri lawọn ibuba awọn ọdaran ti wọn ọlọpaa tu ka ni igbo aginju Umuaku ati Nneato. Amọṣa, awọn to n ṣe iwadii iṣẹlẹ naa n sọ pe o ṣeeṣe ki awọn egungun agbari naa jẹ ti awọn eeyan ti wọn ji gbe, bi o tilẹ jẹ wi pe iwadi imọ ijinlẹ igbalode ṣi n lọ lati ṣe afihan agbari ati egungun awọn to jẹ ni pato ati ohun to so rọ mọ iku wọn.

Bawo ni ọlọpaa ṣe ṣawari awọn agbari naa?

Awọn ọlọpaa lati ẹka to n gbogun ti iwa ọdaran, ikọ to n gbogun ti ijinigbe, ikọ to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun, ikọ kogberegbe atawọn ikọ ọlọpaa miran lo wa lara awọn to ṣiṣọ loju eegun ọrọ̀ naa.

Gẹgẹbi awọn ọlọpaa ṣe sọ, igbesẹ lati kọlu awọn agbegbe naa waye lẹyin ti iwadii ọtẹlẹmuyẹ ti jade nipa awọn kọlọransi si kan ti wọn fi awọn aginju naa ṣe ibuba wọn.

"Nigba tawọn ọlọ ikọ kogberegbe de awọn ibuba to wa ninu igbo naa, awọn afurasi ọhun ti fi ẹsẹ fẹẹ. Eleyii to mu ki wọn ba gbogbo awọn ipagọ wọn lawọn ibuba naa jẹ. Egungun agbari eeyan mejidinlọgbọn atawọ̀n egungun miran ti a gbagbọ pe o ṣeeṣe ko jẹ tawọn ti wọn ji gbe, lawọ̀n agbofinro ri nibẹ."

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Abia tun ṣalaye siwaju sii pe ọwọ ọlọpaa ko tẹ ẹnikẹni lasiko ti ọlọpaa ya bo ibẹ nitoripe awọn ọdaran naa ti fere gee ki wọn to de awọn ibudo naa.

Ohun tuntun to jade yii ṣeeṣe ko tun ṣiṣọ loju eegun awọn ohun to n mi araalu lọkan lagbegbe naa nipa ọṣẹ tawọn ikọ ajinigbe n ṣe nibẹ paapaajulọ lawọn igbo ati aginju to wa kaakiri ẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria, nibi tawọn ikọ ọdaran kaakiri ti n figba gbogbo ji awọn awakọ, arinrinajo ati araalu to n gbe lẹkun naa lati pawo.

Awọn agbofinro ti wa ke saraalu nibẹ lati fi to ọlọpaa leti bi wọn ti kẹẹfin awọn iwa to mu ifura dani lawujọ wọn, pẹlu bi igbesẹ ṣe n lọ lati ṣe idanimọ awọ̀n egungun naa ati lati le mọ boya awọn agbari naa niiṣe pẹlu awọn iwadi ijinigbe ti wọn ko tii ri yanju lẹkun naa.