Wo ìrúfẹ́ obìnrin tó lè ṣẹ́ oyún lábẹ́ òfin tílé ìgbìmọ̀ Ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati le mu adinku ba didi obi ojiji lai ro tẹlẹ, ati mimu adinku ba ki awọn eeyan maa gbe ọmọ ikoko ju danu nitori aile tọju wọn, ijọba ipinlẹ Ogun ti buwọ lu aba to fontẹ lu oyun ṣiṣẹ.
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lo buwọ lu aba naa nibi ijokoo wọn to waye l'Ọjọbọ, ọsẹ yii.
Awọn aṣofin naa sọ pe ohun to ṣe pataki ni lati dena oyun ninu lai ro tẹlẹ, ati yiyọ awọn oyun ojiji danu lọna to ni aabo.
Aba naa ti wọn pe nọmba rẹ ni "H.B. No. 036/OG/2026 – Ogun State Safe Termination of Pregnancy Law, 2026," ni olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa to wa ni Oke-Mosan niluu Abeokuta, Ọnarebu Oludaisi Elemide buwọ lu.
Ta ló dábàá náà?
Ọnarebu Wahab Haruna to jẹ alaga igbimọ ilẹ igbimọ naa lori eto ilera lo gbe aba naa kalẹ, nigba ti Ọnarebu Omobola Bakare keji aba ọhun, ko to di pe gbogbo awọn aṣofin yooku tẹwọ gba a wọle.
Inu oṣu Keje, ọdun 2026 ni aba ọhun de ipele keji, nibi ti gbogbo awọn aṣofin ti sọ pe awọn yoo ṣagbeyẹwo rẹ finnifinni.
Ninu aba naa, wọn sọ pe ohun to dara ni lati mu adinku ba bi awọn eeyan ti ko tii ṣetan lati di obi, ṣe n loyun airotẹlẹ, to si jẹ pe lẹyin ti wọn ba bi ọmọ naa tan, wọn ko nii ri owo lati tọju ọmọ ọhun.
Ọnarebu Babatunde Tella lo gbe aba naa dide nibi ijokoo wọn to waye lanaa, ko to di pe Ọnarebu Lukman Adeleye keji rẹ.
Alabojuto ile igbimọ aṣofin ọhun, Ọgbẹni Sakiru Adebakin lo ka aba naa jade fun igba kẹta, ko to di pe olori ile naa, Ọnarebu Elemide sọ pe ki wọn fi ranṣẹ si Gomina Dapo Abiodun lati buwọ lu.
Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ buwọ́lu àbá náà
Ninu oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni awọn alẹnulọrọ lẹka eto ilera kaakiri ipinlẹ Ogun sọ pe ohun to dara ni aba ti wọn gbe kalẹ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun.
Nibi ipade ti awọn alẹnulọrọ naa ṣe niluu Abeokuta l'Ọjọbọ, ọgbọn ọjọ oṣu Keje, ọdun 2026, ni wọn ti sọ pe awọn fọwọ si aba ọhun.
Gbogbo awọn aṣoju ninu ẹgbẹ NMA ati NANNM, to fi mọ Ọba Morufu Adebayo to je Onitafin tiluu Otafin ni wọn sọ pe iwuri ni aba ọhun jẹ.
Awọn miran to tun wa nibẹ ni awọn aṣoju lati ajọ CSAHRSD, SOGON, CDHR ati CCEEGA, to fi mọ awọn miran atawọn agbofinro lo wa nibẹ.
Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ogun, Tomi Coker jẹ ko di mimọ pe aba naa ti wọn buwọ lu yoọ jẹ ki wọn mọ ilana lati daabo bo awọn obinrin to fẹẹ ṣẹyun, to fi mọ awon elero ilera.
Bakan naa lo sọ yoo mu adinku ba ironu ati iriri ti awọn ọmọbinrin maa n ni, nigba ti wọn ba loyun airotẹlẹ.
Ṣaaju asiko yii ni Ọnarebu Wahab Haruna ti sọ pe "ọpọ awọn iya wa, awọn ẹgbọn ati aburo wa lobinrin ti maa n padanu ẹmi wọn tabi koju ailera to pọ nipasẹ oyun ti wọn n ṣe, ati lasiko ibimọ, to si jẹ wọn ṣee dena."
Àwọn ìpínlẹ̀ wo ló ti gbé irú ìgbésẹ̀ báyìí tẹ́lẹ̀?
Lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2025 ni ileeṣẹ eto ilera nipinlẹ Ekiti ṣagbekalẹ eto ilanilọyẹ kan ti wọn pe ni ST'P, iyẹn Safe Termination of Pregnancy for Legal Indications Guidelines.
Eto yii ni wọn gbe kalẹ lati fi daabo bo gbogbo awọn ọmọbinrin ti wọn n ṣẹ oyun, lati le ni aabo oyun ṣiṣẹ labẹ ofin.
Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ naa, Dokita Oyebanji Filani, ẹni ti akọwe agba nileeṣẹ eto ilera, Arabinrin Olusola Gbenga-Igotun ṣoju fun, lo lewaju eto naa.
Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna ọhun sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati mu adinku ba bi awọn obinrin ṣe n ku lasiko ti wọn ba ṣẹ oyun.
"A wa nibi lati daabo bo ẹmi...nipa pipese ilana akọṣẹmọṣẹ ti yoo jẹ ki aabo wa fun oyun ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ofin. Ipinlẹ EKiti n ṣe adinku si ewu to wa ninu oyun ṣiṣẹ lọna to lewu, leyi to maa n ge ẹmi awọn obinrin kuru.
Ìjọba Eko dá òfin oyún ṣíṣẹ́ dúró
Ninu oṣu Keje, ọdun 2022, Gomina Babajide Sanwo-Olu da igbesẹ ilana oyun ṣiṣẹ ti awọn kan gbe dide duro.
Sanwo-Olu sọ pe ilana oyun ṣiṣẹ ti wọn gbe jade, ni ko nii di mimulo nipinlẹ Eko, iyẹn boun ba ṣi wa lori ipo gẹgẹ bii gomina.
Ilana naa, ti wọn pe ni "State Guidelines on Safe Termination of Pregnancy for Legal Indications", ni awọn alakoso ẹka ileeṣẹ eto ilerato n ri sọrọ ilera mọlẹbi ati ounjẹ to ṣe ara loore gbe jade.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto ilera, Ọjọgbọn Akin Abayomi lo ti fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ Eko ko le fọwọ si iru awọn ilana oyun ṣiṣẹ tuntun yii.
O ni dida erongba naa duro, yoo jẹ ki ilanilọyẹ to pe ye waye, ati pe ijororo yoo tun waye laaarin awọn alẹnulọrọ, ko to di pe wọn fẹnuko lori oya wọn yoo fontẹ lu aba naa.
Titi di asiko yii, ni ohunkohun ko tii ṣẹlẹ latigba naa.
Ìpínlẹ́ Oyo nkọ́?
Ọjọ manigbagbe ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 jẹ ninu itan fun ipinlẹ Oyo, nigba ti wọn gbe aba dide nipa aabo fun oyun ṣiṣẹ.
Ajọ kan ti wọn pe ni PLAN Health Advocacy and Development Foundatipn ni wọn gbe aba naa dide lati jẹ ki aabo wa fun oyun ṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa.
Ọpọ awọn alẹnulọrọ bii awọn aṣoju lati ileeṣẹ to n ṣabojuto ọrọ eto ilera, ilee to n ri sọrọ eto ilera, ileeṣẹ eto ẹkọ, ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn obinrin, to fi mọ ileeṣẹ to n ri sọrọ eto idajọ ni wọn jokoo lati kọ itan tuntun lọjọ naa.
Yatọ si awọn wọnyi, awọn aṣoju ẹsin, olori agbegbem awọn oṣiṣẹ eleto ilera, to fi mọ awọn ẹgbẹ bii olukọ, obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ kaakiri ile-ẹkọ ni ko gbẹyin nibẹ.
Nibẹ ni wọn ti gbe aba dide nipa awọn ilana ti yoo jẹ ki aabo wa fun awọn ọna ti awọn obinrin n gba ṣẹ oyun airotẹlẹ.
Ṣugbọn ṣa, ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii, ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ lori aba nipa aabo fun oyun ṣiṣẹ, ati pe awọn ko nii fi aba naa falẹ rara.
Awọn igbimọ ile igbimọ naa to n ri sọrọ eto ilera lo ṣagbatẹru eto ọhun to waye nile awọn oloye, iyẹn House of Chiefs to wa lagegbe Secretariat niluu Ibadan.
Nigba to n sọrọ, alaga igbimọ naa, Ọnarebu Rilwan Saminu sọ pe awọn gbe aba naa kalẹ lati le ṣagbekalẹ awọn ilana ipolongo ilanilọyẹ, idanilẹkọọ, ati atilẹyin ti yoo ba ofin mu, lati mu adinku ba oyun airotẹlẹ laaarin ilu.
Ṣugbọn sibẹ, ori igbesẹ yii ni ile igbimọ aṣofin Oyo ṣi wa titi di asiko yii.
Kí ni òfin Nàíjíríà sọ nípa oyún ṣíṣẹ́?
Lorileede Naijiria, oyun ṣiṣẹ lodi si ofin, bẹẹ lo si ni ijiya to to ọdun mẹrinla, ayafi to ba jẹ pe wọn yọ oyun ọhun lọna ti ko pa iru obinrin bẹẹ lara.
Sibẹsibẹ, oniruuru oyun yiyọ lo ti waye lojoojumọ, to si jẹ pe pupọ ninu rẹ lo maa n mu ipenija ailera dani lẹyin ti obinrin ba ṣẹ oyun, paapaa lọna ti ko ni aabo to pe ye.




























