Awakọ̀ bàálù gún ara wọn lọ́bẹ lójú òfurufú, ẹ̀jẹ̀ dà sílẹ̀; àlàyé rèé lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà

Baalu to wa loju ofurufu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Baalu kan to n lọ si Tel Aviv lorilẹede Israel lo ṣadeede dari si ọna Saudi Arabia lẹyin ti ija bẹ silẹ laarin awọn awakọ baalu naa.

Ileeṣẹ iroyin Israel lo fi idi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Baalu Flydubai to gbera ni papakọ ofurufu Dubai lonii Ọjọru ọgbọnjọ oṣu Kẹsan an, lo sare fi iṣẹ pajawiri ranṣẹ sori itakun agbọrọkaye Flightradar24 tawọn eeyan fi maa n mọ nipa awọn baalu to n rinrin ajo lọwọ.

Lẹyin iṣẹju diẹ lawọn oṣiṣẹ inu baalu naa tun sọ pe awọn eeyan kan lo fẹ ja baalu ọhun gba.

Amọ, o nigba to ya ni o pada si iṣẹ pajawiri to kọkọ fi ṣọwọ sori itakun agbọrọkaye ọhun.

Ileeṣẹ iroyin ni Israel gbagbọ pe awọn oṣiṣẹ inu baalu naa fi iṣẹ pajawiri ranṣẹ sori itakun agbọrọkaye Flightradar24 latari ija to bẹ silẹ laarin awọn awakọ baalu naa.

Ohun to ṣẹlẹ ninu baalu FlyDubai FZ1073

Baalu FZ1073 to ko ero 150 ti ọpọ wọn jẹ ọmọ orilẹede Israel lo yẹ ko balẹ si papakọ ofurufu Ben-Gurion, amọ, papakọ ofurufu Tabuk ni Saudi lo pada lọ balẹ si lorilẹede Saudi Arabia.

Iroyin sọ pe awọn eeyan bẹrẹ sii kọminu lẹyin ti ija bẹ silẹ laarin awọn awakọ baalu naa.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ero inu baalu naa sọ pe awọn to n ṣiṣẹ pẹlu awọn awakọ baalu naa kepe awọn ero lati ṣeranwọ fun wọn ki wọn le la ija laarin awọn awakọ baalu naa.

O ni awọn ero naa lo ṣeranwọ ti wọn fi ri ija ọhun la ti wọn si so ọkan ninu awọn awakọ baalu naa mọlẹ.

Ẹwẹ, Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu, ti sọ pe awọn ti pẹtu si ọrọ naa, ati wi pe awọn ero inu baalu naa ti wọn wa ni Saudi Arabia yoo pada si Israel laipẹ.

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Flydubai ti sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ kan ṣẹlẹ ninu baalu naa, ṣugbọn gbogbo awọn ero inu ọkọ baalu naa lo wa lai lewu.

''Flydubai tun fidi rẹ mulẹ pe iṣẹlẹ kan waye ninu baalu FZ1073 to gbera ni papakọ ofufuru DXB ni Dubai to n lọ si papakọ ofurufu Ben Guriom ni Israel ni ọgbọnjọ oṣu Kẹsan an,'' atẹjade kan ti wọn fi sita lo sọ bẹẹ.

''Baalu naa balẹ si papakọ ofurufu Tabuk ni Saudi Arabia, gbogbo ero to wa ninu rẹ lo pe pere pere.

Wiwa lai lewu awọn onibaara wa lo jẹ wa logun nileeṣẹ wa.

A ṣi n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaṣẹ ki a to le sọ ẹkunrẹrẹ nnkan to ṣẹlẹ gan an.''

Yasmin Abu Kasis sọ fun ileeṣẹ iroyin kan pe ọmọbinrin oun wa ninu baalu ọhun, ati wi pe gbogbo eeyan lo gbọ bi o ti n pariwo ninu baalu naa.

Ọmọbinrin naa sọ pe ọkunrin kan to mu ọbẹ dani ba ọkan lara awọn awakọ baalu naa wọ iya ija, ti ẹjẹ si da silẹ.

Ọkan lara awọn ero ọkọ baalu naa sọ fun iwe iroyin Jerusalem Post wi pe awakọ baalu kan gun omiran lọbẹ.

Amọ, o ṣalaye pe awọn ero to jokoo sun mọ ibi ijokoo awọn awakọ baalu lo ti awakọ baalu to gun ekeji rẹ lọbẹ kuro nibi ijokoo wọn.

Ero ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe awakọ baalu meji mii ti wọn jokoo ṣeyin baalu naa pariwo mawọn awakọ baalu naa pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn ni kiakia.

Eeyan miran to tun wa ninu baalu naa ṣalaye wi pe dokita kan onimọ nipa eyin to wa ninu baalu naa lo sare tọju awakọ baalu to ṣeṣe.

'Ẹjẹ pọ nilẹ': Awọn ero ṣalaye bi ibẹru-bojo ṣe gbalẹ ninu baalu ọhun

Yasmin Abukasis sọ fun ileeṣẹ Reuters pe ọmọbinrin oun to wa ninu baalu ọhun sọ pe ọkunrin kan to mu ọbẹ dani mu ọkan lara awọn awakọ baalu naa mọlẹ; ti ẹjẹ si kun ilẹ kaakiri.

Ọmọbinrin naa sọ pe awọn awakọ baalu meji mii ni wọn sare lọ dari ọkọ ofurufu naa bi

Ọpọ ero inu baalu ọhun ni wọn ba oniruuru ileeṣẹ iroyin sọrọ, amọ, BBC News ko tii ṣayẹwo tan lori awọn to n sọ nipa iṣẹlẹ naa.

''Lẹsẹ kẹsẹ ni ọkọ baalu naa bẹrẹ sii ni maa ja lọọlẹ, tawọn ero inu baalu ọhun si bẹrẹ sii pariwo,'' Abukasis lo sọ bẹẹ fun AP.

Obinrin kan to wa lara awọn ero inu baalu naa sọ pe ẹru ba awọn ero lasiko naa tori baalu ti bẹrẹ si ni ja lọọlẹ.

''Awa ero gan an ti ri i pe baalu naa ti n lọọlẹ diẹ diẹ, awọn kan wa ninu wa ti ẹjẹ wa lara aṣọ wọn.

Amọ, ko si ewu fun wa mọ bayii, a ṣetan lati pada sile wa,'' obinrin naa lo sọ fun iwe iroyin Israel Hayom bẹẹ.

''A ti fọwọ ṣinkun ofin mu awakọ baalu to gun ekeji rẹ lọbẹ''

Ni bayii, Olootu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu, ti sọ pe ijọba ti fọwọ ṣinkun ofin mu awakọ baalu to gun ekeji rẹ lọbẹ tori o fẹ ja baalu naa lulẹ ni.

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu FlyDubai sọ pe ọkọ baalu ọhun to n lọ si ilu Tel Aviv ni Israel lati Dubai ti ja lọọlẹ pẹlu 17,000ft laarin iṣẹju meji pere ki wọn to dari ọkọ baalu naa si Saudi Arabia.

Ero kan ninu baalu naa sọ pe niṣe lawọn ero inu ọkọ ofurufu naa n pariwo kawọn ọkunrin kan to lọ fipa mu ọkan lara awọn awakọ baalu naa kuro nibi ijokoo awọn awakọ baalu ọhun.

Eeyan mii to wa ninu baalu ọhun sọ pe awọn ero inu baalu lo ja baalu naa gba lọwọ awakọ baalu to mu ọbẹ lọwọ.

Netanyahu wa gboṣuba fawọn eeyan to fipa mu awakọ baalu to gun ekeji rẹ lọbẹ kuro nibi ijokoo awọn awakọ baalu.