Àlàyé lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ku ọjọ́ márùn ún tí Ogogo yóò jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan/Facebook
Abdulazeez Ayinde Onifade, Olu Ayinde, ibatan ati ọrẹ kori o sun si gbajugbaja oṣere to doloogbe, Taiwo Hassan, tawọn eeyan mọ si Ogogo ti ṣalaye bi Ogogo ṣe pada mọ pe aisan jẹjẹrẹ lo n ba oun finra.
Ọgbẹni Ayinde ti inagijẹ rẹ n jẹ Olu Ogogo ṣe ọrẹ pẹlu Ogogo fun ọdun mẹẹdọgbọn ki Ogogo to jẹ Ọlọrun nipe.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu iwe iroyin City People, Ayinde sọ pe ''mo ranti igba kan ti ara Ogogo ko fi kọkọ ya, Corporate Picture lo pe Imaamu rẹ to ṣe adura fun un niluu Ilorin, Ọlọrun si gbọ adura naa.
Ilaro ni mo kọkọ n gbe ti mo ti n ṣiṣẹ aranṣọ, nitori Ogogo ni mo fi ko wa siluu Eko.
Mo gbero lati gba ile funra mi, amọ, Ogogo sọ pe oun fẹ ka jọ maa gbe papọ ninu ile kan naa.
Bayii ni mo bẹrẹ sii maa tẹle e lọ sibi kibi ti wọn ba ti pe e fun iṣẹ ere ori itage.
Ti wọn ba fi Ogogo si ile itura nla kan, o maa sọ fun wọn pe ki wọn fi emi ati Shina naa si ile itura kan naa.
Bakan naa tun ni o maa n pin gbogbo nnkan ti wọn ba fun un nibi to ba ti lọ ṣere pẹlu wa.''
Ohun to kọkọ ṣẹlẹ ṣaaju ọjọ iku Ogogo
Ọgbẹni Ayinde ṣalaye pe lọjọ kan ni Ogogo lọ si Ilaro ti o si sọ pe aya n dun oun.
O ni bayii ni wọn gbe e lọ si ile iwosan ti wọn si tọju rẹ.
Amọ, Ogogo ni aya naa si tun n dun oun lọjọ keji, eyi lo si jẹ ko lọ si ile iwosan Apena ni Ikorodu.
Bayii ni dokita ṣe oniruuru ayẹwo fun un ti o si fun un ni abẹrẹ ki irora naa le din ku.
''Lati ile iwosan yii ni wọn tun ti ni ki a lọ si ile iwosan mii, amọ, wọn tun pada ni ki a maa lọ si ile iwosan LASUTH nibi ti wọn ti sọ fun wa pe Ogogo ni arun jẹjẹrẹ.
Inu wa bajẹ nigba ti wọn sọ fun wa pe Ogogo to ni jẹjẹrẹ.
Ibatan wa kan Mutiat to n ṣiṣẹ nile iwosan LASUTH lo sọ fun kabiyesi Ilaro ati Sẹnẹto Solomon Adeola tawọn eeyan mọ si Yayi nipa aisan to n ba Ogogo finra.
Sẹnẹtọ Yayi ni ki wọn gbe Ogogo lọ si India fun itọju, amọ, fisa ko tete jade.
Aisan naa ti wọ ọ lara ki fisa rẹ to jade, ko lagbara lati le rinrin ajo naa mọ lọ si India.
Ṣugbọn Sẹnẹtọ Yayi gbe dokita wa lati India pe ko wa tọju Ogogo ni Naijiria.
Dokita yii lo sọ pe ki wọn gbe e lọ si ile iwosan St Nicolas ni Lagos Island nibi ti o ti n gba itọju oriṣiiriṣii.
Ọgbẹni Ayinde ni bayii ni Ogogo bẹrẹ sii gbadun diẹ diẹ ti o si n jẹun.
Ṣugbọn o ni gbogbo nnkan yi pada lojiji nigba to ku ọjọ karun un ti yoo ku.
Ọgbẹni Ayinde wa gbadura pe ki Eledua tẹ Ogogo si afẹfẹ rere.





























