Èèyàn mẹ́rin wọ gàù fún jíjí ọmọ ọjọ́ mẹ́rin gbé lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ tó ní àrùn ọpọlọ

Oríṣun àwòrán, Abia Police
Awọn eeyan mẹrin kan ti wọn jẹ ọkunrin meji ati obinrin meji ti bọ sọwọ ọlọpaa nipinlẹ Abia, fun ẹsun pe wọn ji ọmọ ikoko gbe lọwọ iya rẹ to ni arun ọpọlọ.
Yatọ si pe wọn ji ọmọ naa ti ko ju ọmọ ọjọ mẹrin gbe bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe sọ, wọn tun ta a pẹlu.
Awọn afurasi to ṣiṣẹ naa gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Abia, Maureen Chinaka, ṣe kede lọjọ Aje ni:
Gladys Nathaniel, ẹni ọdun mejidinlaadọta (48); Victor Udochukwu, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta (47); Chijioke Obunwa, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59) ati Onyeonoro Chinwe, ẹni ọdun mẹtalelogoji (43).
Alaye ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa
Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Abia ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, o ni ikọ to n ri si iwa ọdaran to mu ipa dani lo mu awọn eeyan naa lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026, lẹyin ti olobo ta wọn lati ibi otitọ to fẹsẹ mulẹ ṣinṣin.
Alukoro Chinaka sọ pe iwadii fi han pe awọn mẹrin yii gbimọ pọ lati ji ọmọ ọjọ mẹrin naa lọwọ iya rẹ, wọn si pada ta a fun ẹlomi-in.
"A gbọ pe awọn afurasi naa gbimọpọ lati ji ọmọ ọjọ mẹrin ọhun lọwọ iya rẹ ti aisan ọpọlọ pe nija, wọn si ta a fun ẹlomi-in lẹyin naa."
Bẹẹ ni atẹjade naa ka lapa kan.
O ni ọwọ ba wọn lẹyin iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ, awọn ọlọpaa si gba ọmọ naa pada gẹgẹ bi wọn ṣe da aabo bo iya naa.
Alukoro sọ pe ọlọpaa ti yọnda obinrin ti ọpọlọ pe nija naa fawọn ẹbi rẹ lati fun un nitọju to peye.
O ni wọn ti gbe ọmọ ikoko naa fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ obinrin nipinlẹ Abia lati maa tọju.
Ni ti awọn afurasi tọwọ ba, wọn ṣi wa lahaamọ gẹgẹ bi Chinaka ṣe wi, bẹẹ ni iwadii n tẹsiwaju.


























