Ààrẹ Iran sọ òkò ọ̀rọ̀ sí Trump níbí ìpàdé àwọn olórí orílẹ́èdè àgbáyé UNGA tó ń lọ lọ́wọ́ l'Amẹrika

Donald Trump wọ kootu olomi buluu, Masoud Pezeshkian wọ aṣọ dudu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede Iran, Masoud Pezeshkian, ti sọ oko ọrọ si Ààrẹ Donald Trump Amẹrika nibi Ipade awon olori orile-ede to n lọ lọwọ nílùú New York l'Amẹrika.

Pezeshkian ni Iran ko ni gba fún Amerika lori ija to n lọ laarin awọn orilẹede mejeeji.

Amọ, o ni Iran ṣetan lati sọ asọyepọ láti fopin si ogun to n lọ laarin Iran ati Amerika.

Ààrẹ Pezeshkian sọ pe gbogbo ijiya ti Amerika n kede ati ipa tí wọ́n n lo n fun Iran lagbara sí í ni.

Pezeshkian fikun ọrọ rẹ pe o gbọdọ wa ninu adehun t'awọn ba fẹ ṣe pé Amerika gbọdọ ṣi oju ọna t'awọn ọkọ oju omi Iran maa n gba koja pada.

"Ko ṣee ṣe kí ẹnikẹni maa jẹ anfaani ọna ori omi Strait of Hormuz, ki Iran si ma lanfaani sí ònà naa."

Láti oṣù Keji ti ija ti bẹrẹ laarin Amerika àti Iran ni ọpọ ọkọ oju omi ko ti le gbe epo rọ̀bì kọja níbẹ mọ pẹlu bi Iran ṣe n yín ado oloro sáwọn ọkọ oju omi ti Amerika naa sí di ọna ọhun.

Ààrẹ Pezeshkian tun fidi rẹ múlẹ pe Iran ko salọ.

''Ọkan la o fọwọ mu nínú ka jọ daabo bo ẹkun wa papọ, tabi ka jọ foju wina eto aabo to mẹhẹ''

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pezeshkian ni "ko s'ẹni to le da pese aabo funra rẹ lẹkun ti a wa yii.

Ọkan la o fọwọ mu nínú ka jọ daabo bo ẹkun wa papọ, tabi ka jọ foju wina eto aabo to mẹhẹ."

Aarẹ Iran tun koro oju si iha tawon orilẹede agbaye kọ si ọrọ Iran.

O ni awọn ohun ija oloro to lágbára wa ni Israel.

"Israel ni ibùdó ado oloro rẹ, amọ, ko seni to yẹ wọn lọwọ rẹ wò.

Ṣugbọn wọn n ṣ'ayẹwo Iran nigba ti Israel n ṣekúpa awọn eeyan lọ.

Amọ, Iran lo n gba oríṣìíríṣìí ijiya sara," Pezeshkian lo sọ bẹẹ.

O tun fikun ọrọ rẹ pe Iran ko ni jáwọ kuro ninu lilọ ado oloro ti wọn ti ṣe.

Pezeshkian sọ pe Trump pe awọn ni agbésùnmọ̀mí eleyii ti ko ri bẹẹ torí awọn agbésùnmọ̀mí gan an lo n koju ija s'àwon eeyan Iran.

Pezeshkian mu fọto adari Iran tẹlẹ, Ayatollah Ali Khamenei to ku lasiko ti Amerika ati Israel ju ado oloro sile rẹ loṣu Keji ọdún yìí.

O tun mu aworan awọn ọmọde 175 ti wọn ku nigba ti ado oloro balẹ sile ẹkọ kan ni Minab dani. .

Amerika ní awọn kọ ló wa nidii ikọlu náà.

Pezeshkian ni oniruuru ikọlu ni won n ṣe sí Iran eyi to ni o ti mu kí àwọn èèyàn Iran pinnu lati daabo bo ara wọn.

Mi o mọ̀ bóyá kí n pa Iran run ni, tàbí ká jọ sọ àsọyépọ̀ - Trump

Ṣaaju ni Trump beere nibi ipade awọn olori orilẹede niluu New York bo ya adehun pẹlu Iran le jẹ ki orilẹede naa dara si i ju ti atẹyinwa lọ.

O beere boya ki oun fi opin si orilẹede naa ni, abi koun tete ṣekupa awọn eeyan orilẹeede naa.

Aarẹ Amẹrika ni oun tun le pa gbogbo orilẹede naa rẹ ti ko si ni si orilẹede kankan ti wọn n pe ni Iran mọ lọjọ iwaju.

Amọ, Trump ni oun gbagbọ wi pe awọn yoo pada buwọlu iwe adehun lẹyin eto idibo Amẹrika oṣu Kọkanla to n bọ.