Èló lowó oṣù táwọn ọmogun Naijiria tó wà lójú ìjà ń gbà? Àlàyé rèé

Awọn sọja meji to wọ aṣọ ologun gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan lo ti gboṣuba fun ijọba apapọ lẹyin to kede afikun owo oṣu awọn ọmogun Naijiria lọsẹ to kọja.

Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, ṣalaye ninu atẹjade kan ti o fi sita pe ko din ni ọmogun 250,000 ti yoo jẹ anfaani ẹkunwo owo oṣu naa.

Onanuga sọ ninu atẹjade naa pe ẹkunwo owo oṣu yii yoo na ijọba ni afikun N924bn lọdun.

Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu sọ pe ijọba gbọdọ ṣe atilẹyin fawọn ẹṣọ eleto aabo bi wọn ṣe n ṣiṣẹ ilu.

Elo ni owo oṣu tuntun awọn ọmogun Naijiria bayii?

BBC ti ṣe atupalẹ bi owo oṣu tuntun awọn ọmogun Naijiria yoo ṣe ri ati iye ti wọn yoo maa gba.

Iṣẹ wọn yatọ sira amọ ipo wọn jọ ara wọn, ati pe bakan naa ni owo oṣu wọn ṣe ri.

Oriṣii ọmogun mẹta lo wa nileeṣẹ ologun Naijiria - ọmogun oriilẹ, ọmogun ofurufu ati ọmogun oju omi.

Gẹgẹ bi ajọ Statisense to maa n ṣewadii ati iṣiro ṣe sọ, o kere tan ọmogun kọọkan n gba N104,000 gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ.

Ọmogun kan ti ko fẹ ki a darukọ rẹ sọ fun BBC pe owo oṣu ọmogun to kere julọ bẹrẹ lati N103,000 si N105,000.

Eyi tumọ si pe owo oṣu to kere julọ fawọn ọmogun oriilẹ bẹrẹ lati N189,000 si N192,000.

Eyi tumọ si pe owo oṣu iru ọmogun bẹẹ lọdun jẹ N2.26m si N2.30m.

Elo lowo oṣu tawọn sọja to wa loju ogun n gba?

Awọn owo ajẹmọnu kan wa fawọn ọmogun yatọ si owo oṣu ti wọn n gba.

Owo ajẹmọnu kan wa ti wọn n pe ni RCA tawọn sọja to wa loju ogun maa n gba.

Omiran tun wa ti wọn pe ni ''grumbe'' tawọn sọja to wa loju ogun maa n gba bakan naa.

Sọja kan ti ko darukọ ara rẹ sọ fun BBC pe N45,000 ni owo ajẹmọnu RCA tawọn ọmogun to wa loju n gba bayii.

Bakan naa ni o tun sọ pe N50,000 ni owo ajẹmọnu ''grumble'' tawọn ọmogun n gba.

Eyi tumọ si pe ọmogun Naijiria kọọkan to wa loju ija n gba owo ajẹmọnu N95,000 yatọ si owo oṣu ti wọn n gba.

Ti a ba ro N95,000 pọ mọ N189,000, o tumọ si pe ọmogun Naijiria to wa loju ija le maa gba N284,000 loṣu.

Elo lowo oṣu awọn ọga ninu iṣẹ ologun?

Ajọ Statisense ṣalaye pe awọn ọga ninu iṣẹ ologun ti wọn ti de ipo Maj Gen, Rear Admiral tabi Air Vice Marshal n gba N1.5m gẹgẹ bii owo oṣu.

Ida 30% ni afikun owo oṣu awọn ọga lẹnu iṣẹ ologun bẹrẹ lati Brigadier lọ si ipo General.

Fun apẹẹrẹ, ọga agba ninu iṣẹ ologun le maa gba owo oṣu ti ko din ni N1.49m si N1.5m.

Eyi tumọ si pe Maj Gen n gba owo to to N17.9 si N18m lọdun.