Kà nípa kòkúmọ́ obìnrin tí wọ́n gún lábẹ́rẹ́ ikú nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àmọ́ tí kò kú

Oríṣun àwòrán, Ọgba ẹwọn Tennessee
Wọn ti gbe ọdaran ti wọn dajọ iku fun lọ sile iwosan bayii lẹyin ti igbiyanju lati gbẹmi rẹ pẹlu abẹrẹ iku lẹẹmeji fori ṣọpọn.
Ikọ agbẹjọro Christa Pike, niluu Tennessee pe ẹjọ pajawiri pe ki wọn da iku rẹ duro lasiko ti wọn n gbiyanju lati gbẹmi rẹ lọwọ pe ọdaran ọhun ti daku bo tilẹ jẹ pe o ṣi n mi, to si n hanrun.
Ọkan ninu awọn agbẹjọro rẹ sọ fun BBC pe Pike, to jẹ ẹni aadọta ọdun ti n gba itọju lọwọ nile iwosan lẹyin ti wọn ti kọkọ fun labẹrẹ iku nigba meji ọtọtọ.
Ọdun 1996 ni wọn dajọ iku fun Pike lẹyin to ṣekupa Colleen Slemmer to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun lọdun naa lọhun.
Lẹyin idajọ iku naa ni gbas-gbos waye amọ ile ẹjọ to ga julọ nilẹ naa fontẹ lu u pe ki wọ gbẹmi rẹ.
Ọmọ ọdun mejidinlogun pere ni Pike lọdun naa nigba ti ọrẹkunrin rẹ nigba naa, Tadaryl Shipp lu Slemmer niluu bara ko to gbẹmi rẹ.
Iya Slemmer, May Martinez wa lara awọn to n fẹ ki wọn tete gbẹmi Pike, koda o ba awọn ileeṣẹ iroyin bii NBC sọrọ nipa rẹ.
Nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni wọn kọkọ fẹ gbẹmi rẹ ninu ọgba ẹwọn Riverbend Maximum Security Institution to wa ni Nashville.
Ileeṣẹ iroyin AP jabọ pe ibẹ ni wọn ti fun Pike ni abẹrẹ iku 'pentobarbital' meji ki wọn to ni ki awọn akọroyin fi yara naa silẹ.
AP ni wọn fun labẹrẹ keji nitori o ṣeeṣe ki abẹrẹ akọkọ ma gbẹmi rẹ tan yan yan.
Gomina Tennessee, Bill Lee sọ ninu atẹjade kan pe oun ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ amọ ko si ohun ti yoo yẹ iku awọn to yẹ ki wọn ku lọdun yii.
Amọ awọn agbẹjọro Pike ti bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ naa pe wọn kuna ninu ojuṣe wọn lati gbẹmi ọdaran naa, eyi to ṣeeṣe ko fi sinu ironu.
Lati ọdun 1976 ti ile ẹjọ to ga julọ l'Amẹrika ti bẹrẹ idajọ iku pada, obinrin mejidinlogun pere ni wọn tii gbẹmi rẹ, nigba ti wọn ti gbẹmi ọdaran 1,663 ti wọn jẹ ọkunrin.




























