Ṣé lóòótọ́ ni Oluwo wù òkú àwọn ọba tí wọ́n sin sí ààfin Iwo kúrò, táwọn ọmọ ọba fi wọ ọ́ lọ sílé ẹjọ́? Àlàyé rèé

Oluwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi

Oríṣun àwòrán, @Oluwo Abdulrosheed Adewale Akanbi's palace

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Kabiyesi kan ti ọrọ ọlọkan-o-jọkan saba maa tori rẹ jade nilẹẹ Yoruba ni Oluwo ilẹ Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi.(Emperor Telu 1).

Ni bayii, iroyin to tun gbode nipa Oluwo lori ayelujara ni pe Ọba Abdulrosheed Akanbi ti di ero ile ẹjọ.

A gbọ pe eyi n waye latari oku awọn ọba to ti jẹ kọja niluu Iwo, ti wọn sin si aafin, ti wọn ni Kabiyesi Oluwo si wu awọn oku naa danu.

Iroyin naa sọ pe awọn ọmọ ọba kan lo fẹsun kan Oluwo, ti wọn wọ ọ lọ sile ẹjọ, ti wọn si tun n pe fun iyọnipo rẹ kuro nipo ọba Iwo.

Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe wi, ile ẹjọ giga ilu Iwo ni awọn ọmọ ọba mẹta naa wọ Oluwo Akanbi lọ lati jẹjọ lori ẹsun naa.

Awọn ọmọ ọba wo lo pe Oluwo lẹjọ?

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch ṣe fi orukọ awọn ọmọ oye naa lede, awọn ni:

Olalekan Lamuye, Adedoja Osunwo, Alade Ismaila, Ganiyu Saheed, Kosiru Kolawole ati Wasiu Abolusodun.

A gbọ pe wọn pe ẹjọ naa lorukọ idile ọmọ ọba mẹta n'Iwo, ti I ṣe Ogunmakinde Ande, Adegunodo ati Alausa .

Wọn fi kun un pe yatọ si Oluwo, awọn ti wọn tun fẹsun kan ni Gomina ipinlẹ Osun, Akọwe ijọba ibilẹ Iwo, Kọmiṣanna fun ọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, Olootu idajọ ipinlẹ Osun, ọga ọlọpaa pata ni Naijiria ati Adari ẹka to n ri si iwa ọdaran lori ayelujara niluu Abuja.

Lara ohun ti wọn n beere ni pe ki ile ẹjọ paṣẹ pe ki Oluwo Abdulrosheed Akanbi fipo silẹ, ki kootu kede rẹ bii eni ti ko yẹ lori itẹ, ki won kede pe ipo ọba Iwo ṣofo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣe Oluwo wú awọn oku naa loootọ?

Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe ọpọ igba ni iroyin oriṣiriṣi maa n jade nipa Oluwo Akanbi Abdulrosheed, paapaa lori iha to kọ si awọn nnkan bii iṣẹṣe, ọpọ eeyan lo ti n bu ẹnu atẹ lu Kabiyesi naa.

Lori ayelujara ti ọrọ naa ti n ja ran-in, ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe o ṣee ṣe ki Oluwo wu awon oku naa loootọ.

Ṣugbọn lati fidi okodoro mulẹ, BBC Yoruba kan si Oluwo lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, pẹlu awọn oloye ati aṣoju awọn Baalẹ niluu Iwo, eyi ni ohun ti wọn sọ fun wa.

Ọmọ ale ni awọn to ba ni Oluwo wu oku awon ọba - Akọwe iroyin Oluwo; Alli Ibrahim

Ninu alaye Akọwe iroyin fun Oluwo ilẹ Iwo, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Alli Ibrahim, o sọ pe:

"Ẹ jọọ, awọn wo lo sọ bẹẹ, awọn to ba sọ bẹẹ yẹn, ọmọ ale ni wọn, wọn ki I ṣe ojulowo ọmọ ọba.

" Ko si nnkan to jọ ohun ti wọn n sọ yẹn, ṣugbọn awọn baba wa maa n pa owe pe ọwọ to ba dilẹ ni Esu maa n ran niṣẹ.

" Ẹni ti ko ba ti niṣẹ, iṣẹkuṣe naa ni yoo maa ṣe, gbogbo iṣẹ tawọn ọtaa ba fi lọ ọ ni yoo maa ṣe.

"Ko too di pe Oluwo jẹ, ọpọ awọn baba yii ni wọn ko mọ oju saaree wọn, nigba ti Oluwo si jẹ, o pe gbogbo awọn ọmọ yii pe ki wọn waa fi oju saaree baba wọn han.

"Ti wọn o ba ki n ṣe ọmọ ale ni, ṣe bi eeyan maa n tun oju oori baba rẹ ṣe ni. Ọpọ wọn ni ko mọ saaree baba wọn, awọn agbalagba lo ṣẹṣẹ n tọka rẹ si wọn.

"Gbogbo awon saree yẹn ni Oluwo ti ṣe 'taisi' si, to sọ wọn di tuntun"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Agbẹnusọ to sọrọ lorukọ Oluwo naa ṣo pe gbogbo awọn saree ti awọn ọmọ ko mọ yii ni Oluwo ti ṣe taisi si.

O ni oju orori baba ẹlomi-in ti di aatan ninu wọn, wọn si n wo o bẹẹ.

"Jankariwọ ti wọ awọn ibomi-in ninu wọn, ninu ọmọ to tun orori baba rẹ ṣe, ateyi tawọn oloriṣa maa n ṣe ti wọn a ta ogogoro le e lori, ewo lo daa ju?

Alli sọ pe Oluwo tun saaree naa ṣe ni, o gbe ododo le e lori, o pọn ọn le. O ni ta a ni baba maa ṣadua fun ninu awọn mejeeji.

"Ko si nnkan to jọ ọ, wọn fẹẹ ṣe ara wọn ni.

"Ẹni to ba le sọ pe Oluwoo wu oku ko waa sọ ọ, awọn alainiṣẹ atawọn alailọpọlọ lo n gbe ahesọ bẹẹ kiri.

"Bi ogun bayii ba ti dide si Oluwo, igbega kan n bọ ni"

Nibi ti ọrọ yii da Alli Ibrahim loju de, o ni ni gbogbo igba ti awọn eeyan ba gbe ogun dide si Oluwo Akanbi bi eyi, igbega lo maa n jẹ fun un.

"Bi ogun kan ba ti dide si Oluwoo bayii, igbega kan n bọ niyẹn, ẹ gbagbe ẹ.

"Kawọn maa ṣe ẹjọ, k'awa maa ṣejọba. Wọn o le ri Oluwo mi-in laye wọn.

"Oluwo eleyi yoo pẹ, ẹni ti ko ba ti gba fun un, yoo jẹ maye ni."

Bẹẹ ni Agbẹnusọ aafin ilu Iwo wi.

Ọna alabala meji ti Gomina Adeleke n ṣe lọwọ fẹ jẹ ibi tawọn saaree yẹn wa, Oluwo ni ko gba - Agbẹnusọ awọn Baalẹ Iwo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati le tun gbọ ti ẹnu ẹlomi-in to jẹ alẹnulọrọ lẹka awọn Baaalẹ niluu Iwo, BBC Yoruba kan si Olalekan Bojuri, ọkan lara awọn agbenusọ fun Oluwo ati agbẹnusọ iroyin fun awọn Baale nilẹ Iwo.

Bojuri kọkọ bu si ẹrin ko too dahun pe:

"Ẹ duro na, ẹ jẹ ki n gbọ yin ye, emi naa gbọ ohun to jọ bẹẹ, ṣugbọn ọjọ ti ẹ ba ri aaye, tabi tẹ ẹ ba le wa si Aafin Oluwo, ki emi ati yin atawọn eeyan jọ wo ibi ti wọn sin awon oku yẹn si, ki n fi han yin.

"Awọn ọba mẹrin to jẹ gbẹyin, ti ko le din ni ọgọrun-un ọdun bayii ti wọn ti sin wọn, awọn ni wọn sin sinu aafin ti Oluwo Akanbi wa bayii.

"Igba ti Kabiyesi Adewale Akanbi de ni 2015 mọ 2016, awọn ibi ti wọn sin awọn ọba mẹrin igbẹyin yẹn si ti n di ilẹẹlẹ.

" Ṣugbọn lati jẹ ki wọn da ibẹ mọ, kabiyesi ṣe taisi sibẹ lati le maa fi da wọn mọ."

Bojuri tẹsiwaju pe awọn ọba mẹwaa si mọkanla ti wọn jẹ ṣaaju awọn mẹrin yen, oju kan naa ni wọn sin wọn si, to sọro fawọn eeyan lati mọ ibi ti ẹni bayii wa ninu wọn, nitori gbogbo rẹ ti di ilẹẹlẹ.

"Ki Oluwoo toni to dee, ibi ti wọn sin awon ọba yẹn si, ko jọ aatan, ko jọ aaye idọti ni.

"Igba ti Oluwo Akanbi de ni wọn ṣe fẹnsi ti ko ga pupọ yi I ka, ti wọn fi irin si I, ti wọn si kun ibẹ lọda.

"Wọn ni ta o ba tiẹ le da ọba to wa ninu saaree kan mọ, a ṣaa gbọ pe ibi ni wọn sin wọn si. Lati bu ọla fun wọn, ẹ jẹ ka yi ibẹ po, ka ya a sọtọ, ki ẹnikẹni ma gbabẹ kọja tabi ṣe ẹgbin sibẹ, ohun to jẹ ki Oluwo tun ibẹ ṣe niyẹn.

"Ọna jẹ apa ibi ti awọn ọba yẹn wa, titi alabala meji ti Gomina Ademola Adeleke n ṣe n'Iwo lọwọ fẹ gba ibẹ, ibọwọ fun awọn ọba lo jẹ ki Oluwo ṣiṣẹ dena rẹ.

"Bi Oluwo ba wu oku, nibo lo fẹ wu u lọ? Aafin ni wọn n sin ọba si nilẹẹ Yoruba"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Agbẹnusọ awọn Baalẹ ilu Iwo sọ pe Oluwo ko wu oku kankan.

O ni bi Kabiyesi Akanbi ba hu oku, nibo lo fẹ gbe e lọ.

Bojuri fi kun un pe aafin ni wọn n sin ọba si nilẹẹ Yoruba, bi ẹnikẹni ba n sọ pe Oluwo wu oku, wọn o ri ọrọ sọ ni.

"Ẹni ti yoo ba parọ ni yoo ni ẹlẹri oun n bẹ lọrun, ati pe ọmọ ale ni ọmọ ọba to ba loun ko dele ọba.

"Awọn ọmọ ọba to n ditẹ yii ti sa laafin tipẹ.

"Ẹni to ba ni Oluwo wu oku, ko waa sọ oku naa ati ibi ti wón ti wu u, ati ibi ti won gbe e lọ.

"Emi ṣetan lati mu yin lọ sibi tawọn oku yẹn wa. Ọrọ alaganna ni pe Oluwo wu oku."

Bẹẹ ni Bojuri Olalekan, agbẹnusọ awọn Baalẹ ilẹ Iwo ṣalaye.

BBC News Yoruba gbiyanju lati ba awọn tọrọ kan lẹka awọn ọmọ ọba naa sọrọ, ṣugbọn eyi ko kẹsẹ jari.

"To ba fi le jẹ pe Oluwo wu oku loootọ, èèwọ́ yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀"- Dokita Oluseyi Atanda, Aarẹ ẹlẹsin Ibilẹ l'Osun

Nigba to n dahun si ọrọ to gbode kan yii, olori awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun, Dokita onimọ iṣegun Oyinbo, Oluseyi Atanda, Aarẹ fun gbogbo ẹlẹsin ibilẹ ipinlẹ Osun, sọ pe afi ki ọrọ naa ma jẹ otitọ.

Dokita Atanda sọ pe Oluwo Akanbi ko ṣẹṣẹ maa ṣe awọn nnkan to jẹ eewọ nilẹẹ Yoruba, to si maa n fi gbowo nibi to ti n gba a.

O ni ṣugbọn bi eyi to ni I ṣe pẹlu oku wiwu yii ba fi le jẹ otitọ, aṣegbe kan ko si.

" O dabii pe awa ti fẹẹ pa Ọgbẹni Rasidi ti, nitori nigba mi gan-an, o maa n sọ ohun ti ko ṣe, yoo ni oun sẹ e, ki ariwo rẹ le gba ori iroyin kiri.

"Ko le rowo gba nibi to ti n gbowo.

"Ifa si ni bi ọmọde kan ba n jẹ eewọ, ti ẹnikan ko bi I, bo pẹ titi, ohun to n bi ni a maa bi ni, eewọ a si maa beere lọwọ rẹ.

"A ti sọrọ Oluwo tojọ mẹta, ijọba ko ni kinni kan lati ṣe lori ọrọ rẹ. Ibi to ba ba Iwo jẹ de, ọba to jẹ ti ilu toro, orukọ rẹ ko ni I parẹ, eyi to jẹ ti ilu daru naa, orukọ rẹ ko pari.

"Kangun-kangun-kangun, yoo kangun lọjọ kan".

Bẹẹ ni Aarẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ l'Osun wi.