Wo bí àwọn alátìlẹyìn Arsenal ṣe ń ṣàjọyọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ife ẹ̀yẹ Premier League lẹ́yìn ọdún 22

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idunu ti ṣubu lu ayọ fun gbogbo awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal kaakiri agbaye lẹyin ti ikọ naa gba ife ẹyẹ Premier League fun igba akọkọ lati ọdun mejilelogun sẹyin.
Aṣeyọri yii lo waye lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City gba ọmi 1- 1 pẹlu Bournemouth lọjọ Iṣẹgun.
Lẹyin ti ikọ naa ti gbe ipo keji lati saa bọọlu mẹta sẹyin, ikọ Mikel Arteta pada sọriire lati gba ife ẹyẹ naa.
Lẹyin ti Arsenal fi ẹyin Burnley gbole lọjọ Aje ni wọn gba maaki koko marun un to gbe wọn gori Man City.
Wayi o, lati ilẹ Gẹẹsi, titi de orilẹede Naiijiria ati kaakiri agbaye lawọn eeyan ti n ba Arsenal ṣe ajọyọ oriire ife ẹyẹ naa lẹyin ọpọ ọdun.
Eyii ni bi awọn eeyan ṣe n ṣajọyọ aṣeyọri Arsenal kaakiri agbaye
Arsene Wenger
Akọnimọọgba Arsenal tẹlẹ, Arsene Wenger to ko wọn jẹ titi ti wọn fi gba ife ẹyẹ naa lọdun 2004 sọ pe "Ẹ ti ṣe e! Awọn aṣẹgun maa n tẹsiwaju nigba ti awọn mii ba ti sọ ireti nu. Asiko yin niyii. Oya, ẹ lọ maa gbadun rẹ.
Alan Smith
Atamatase ikọ naa tẹlẹ, Alan Smith ni tirẹ sọ pe inu oun dun lati ri pe ẹgbẹ agbabọọlu oun nigba kan ti si ṣe aṣeyori bo tilẹ jẹ lọpọ igba ti wọn ti de bebe aṣeyọri naa ni wọn maa n lulẹ ṣaaju asiko yii.
Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Sky Sports sọrọ, Smith sọ pe aṣeyọri naa yẹ ẹgbẹ agbabọọlu ọhun.
Dino Melaye
Ni Naijiria, lara awọn gbajumọ alatilẹyin Arsenal ni ọmọ ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, Dino Melaye to fi orin "wọn kere si nọmba wa" sẹnu lati ṣajọyọ aṣeyọri wọn.
Gẹgẹ bii Melaye sẹ sọ, ikọ Arsenal ni oun yoo maa ṣatilẹyin fun titi lai pada lẹyin ẹgbẹ naa.
O tun ni oun ko ni tẹle Manchester United, Chelsea, Liverpool ati Manchester City lai lai.
Lekan Kingkong
Olalekan Olaleye ti ọpọ mọ si Agba Inaki tabi Lekan Kingkong ti sọ pe ki gbogbo awọn ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ Arsenal kuro lori ayelujara nitori awọn yoo ṣe ajọyọ aṣẹyọri ẹgbẹ agbabọọlu naa laipẹ.
Pasitọ Dolapo Lawal
Ẹwẹ, gbajumọ oniwaasu ori ayelujara, pasitọ Dolapo Lawal ti tọrọ afọriji lọwọ awọn ololufẹ Arsenal fun ọrọ to sọ nipa wọn ṣaaju pe egbẹ agbabọọlu naa ko ni le gba ife ẹyẹ Premier League.
Lẹyin to tọrọ aforiji naa tan lo kede pe ijọ oun yoo ṣe isin idupẹ pataki fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa kaakiri ibi ti ijọ oun ba wa.
Iwọnyii lawọn nnkan ti awọn alatilẹyin Arsenal n sọ loju opo wa.






























