Wo atọ́kùn ètò móhùnmáwòrán tó ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe ń yin ìbọn AK-47 lórí afẹ́fẹ́
Atọkun eto ori mohunmaworan kan lorilẹede Iran ni awọn eeyan ri to n yin ibọn lu aṣia orilẹede UAE lasiko to fi n ṣe eto kan lori afẹfẹ ni ọjọ Ẹti ọjọ karundinlogun oṣu karun un lasiko to fi n ba akọṣẹmọṣẹ ibọn yinyin kan sọrọ ni ori eto rẹ.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe awọn isọri eto naa nii ṣe pẹlu igbaradi atọkun naa lati darapọ mọ eto " fi ẹmi lelẹ fun orilẹede Iran'.
O ti le ni miliọnu mọkalelọgbọn eeyan ti wọn ti fi orukọ silẹ fun eto naa pẹlu ogun tiIsrael ati Amẹrika n gbe ko orilẹede Iran. Awọn bata ologun ni wọn ti ko kaakiri awọn ibi ti awọn araalu ti le kọ nipa lilo ibọn AK-47
Awọn eeyan kan lori ayelujara lorilẹede Iran ti bu ẹnu atẹ lu lilo mohunmaworan lati kọ awọn eeyan ni ibọn yinyin eleyii ti wọn ni o n polongo wahala ati laasigbo





