Ọmọ ogun ISIS 175 ni a ti ṣekupa –Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti kede pe oun ti ṣekupa ọmọ ogun ISIS márùndínlọ́gọ́sàn án pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika.
Ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, wọn ni ajọṣepọ naa pẹlu ajọ Africa Command (AFRICOM) ti ilẹ Amẹrika ba ibudo ati oniruru ohun ija oloro ISIS ati ISWAP jẹ.
Atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Samaila Uba fi lede sọ pe "Nigba ti yoo fi di ọjo kọkandinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2026, iwadii wa fi han pe ati ṣekupa agbesunmọmi ISIS 175 loju ija.
Orọ yi lo n jẹyọ lẹyin ti ajọ AFRICOM kede lọjọ Aiku pe oun kọlu ibuba ISIS, ti Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu naa tun kin ọrọ ọhun lẹyin ninu atẹjade tirẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, inu ikọlu naa ni wọn ti ṣekupa Abu Bilal al-Minuki to jẹ olori ẹgbẹ ISIS ni iwọ oorun Afrika.
Lẹyin iku Abu Bilal al-Minuki ni Tinubu fi ọrọ idupẹ ṣọwọ si Aarẹ Doland Trump fun iranlọwọ ati ajọṣepọ orilẹede rẹ fun aṣeyọri naa.
Lọjọ Iṣẹgun ni ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiiria tun kede pe oun ti ṣekupa Abd-al Wahhab, ti oun naa jẹ ọkan gboogi lara awọn adari ISIS.
Wọn ni Abd-al Wahhab yii atawọn meji mii, Abu Musa al-Mangawi ati Abu al-Muthanna al-Muhajir ni wọn maa n pinlẹ ikọlu ISIS ti wọn si maa n ṣe ipolongo rẹ lati ṣeruba araalu.
Lati igba ti ẹgbẹ naa ti lulẹ ni agbegbe Middle East, ni wọn ti di igba ati agbọn wọn wa si iwọ oorun Afrika ti ọpọ wọn si n ṣọṣẹ ni Naijiria.
Loṣu Keji ọdun yii, ijọba ilẹ Amẹrika ni oun fi awọn ọmọ ogun ṣọwọ si Naijiria lati gba awọn ologun rẹ nimọran.
Aṣeyọri ti ikọ ologun orilẹede mejeji ti ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii n ṣafihan pe wọn ti n ṣiṣẹ pọ daadaa.
Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti gboriyin fun ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ati ilẹ Amẹrika fun akitiyan wọn lati gbogun ti iwa igbesunmọmi ni Naijiria.


























