Òní ni ìsìnkú olùkọ́ tí àwọn agbébọn pa lásìkò tí wọ́n kọlú iléẹ̀kọ́ méjì ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oni ni eto isinku olukọni ti awọn agbebọn pa lasiko ti wọn kọlu ileẹkọ meji kan ni agbegbe Ahoro-Esinele ati Yawọta ni ọjọ Ẹti ọjọ karundinlogun oṣu karun un.
Awọn agbebọn naa yinbọn pa Ọgbẹni Joel Adesiyan ẹni to jẹ olukọni ni ile ẹkọ girama Community High School Ẹsinẹlẹ lasiko ikọlu naa.
Eto isinku olukọ ti wọn ṣekupa naa yoo waye ni ijọ onitẹbọmi Ayegun Baptist Church ni ilu Ogbomoṣọ
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko ti i le fi iye wọn mulẹ lọ nibi ikọlu naa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti naa, o ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ yii ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ.
Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de bo ṣe wi.
Bi wọn ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.
Ninu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn fun olukọ kan, ẹni ti iroyin sọ pe o ti jade laye, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.
"Awọn agbebọn ti wọ agbegbe Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo. Wọn gbe ọga ile ẹkọ ati awọn akẹkọọ ti a ko mọ iye won lọ"
Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.



























