Àwọn agbébọn kọlù àgọ́ ọlọ́pàá, ààfin ọba ní Kwara lóru mọ́jú, jí èèyàn mẹ́jọ gbé, tó fi mọ́ ayaba méjì àti àwọn ọmọ ọba, dáná sun dúkìá

Se ni ibẹrubojo gbilẹ, tí onikaluku n sa asala fun ẹmi rẹ loru mọju ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Karun-un, ọdun yii.
Eyi ko sẹyin bawọn agbebọn se ya wọ iluu Yashikira, ni ijọba Ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji okere tan, eeyan mẹwaa gbe lọ.
Lara awọn ti wọn ji gbe lọ ni meji ninu awọn olori Ọba ilu naa, Alaaji Umaru Sariki Usman to fi mọ awọn ọmọ ọba ti a o ti fidi iye wọn mulẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Amọ iroyin kan ni gbogbo awọn eeyan ti wọn gbe lọ to mẹwaa niye.
Bẹẹ ba gbagbe, oru alẹ ọjọ Satide ijẹta ni awọn agbebọn yii naa tun kọlu sọọsi kan ti wọn ti n se isọ oru nijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara.
Wọn pa eeyan mẹta, ti wọn si ji eeyan mẹẹdogun gbe lọ

"Ẹmir naa moribọ sugbọn wọn dáná sun ọkọ̀, pa tòlótòló ọba méjì, ji awọn ayaba meji lọ, wọn si tun ko awọn ọmọ rẹ"
BBC Yoruba kan si asoju to n soju ẹkun Okuta Yashikira ni ile asofin Kwara, Họnọrebu Baba Saliu lori aago fun ẹkunrẹrẹ nipa iṣẹlẹ naa.
Baba Saliu sọ pe, nnkan bi aago kan si meji ni wọn ya wọ ilu, wọn si lọ taara si agọ ọlọpaa.
"Wọn ji awọn ohun ija kọọkan ni agọ ọlọpaa, ko to di pe wọn gba ile Emir lọ.
"Bi wọn ṣe de ile ọba ni wọn bẹrẹ si yinbọn soke ati si awọn ọkọ ti wọn ba nibẹ.
"Ẹmir naa moribọ sugbọn wọn ji awọn ayaba rẹ meji lọ, wọn si tun ko awọn ọmọ rẹ pẹluu ati awọn eeyan mii.
"A o le sọ iye eeyan ti wọn gbe lọ ni pato amọ yoo ma lọ bii mẹwaa.
Wọn dáná sun ọkọ̀, pa tòlótòló ọba méjì."
Baba Saliu fi kun un pe, awọn agbebọn naa ko gbẹmi eeyan kankan, amọ wọn dana si awọn ọkọ ayọkẹlẹ ọba, wọn si tun gbẹmi awọn tolotolo ọba meji.
Baba Saliu sọ pe, ijọba Kwara ti bẹrẹ igbesẹ ni kete ti iṣẹlẹ naa sẹ.
O ni koda, gomina ipinlẹ Kwara ti rọ Emir ilu naa lati fi ilu silẹ lasiko yii nitori aabo ara, titi ohun gbogbo yoo se pada bọ sipo.
"Ọlọpaa, ọdẹ asọgbo ati fijilante ti wọgbo lọ lati doola awọn araalu ti wọn jigbe"
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejire-Adeyemi Adetoun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, lọjọ Aje, ọṣẹ yii.
O ni iroyin de si eti igbọ awọn pe awọn agbebọn yabo iluu Yashikira, ni ijọba Ibilẹ Baruten, ni ipinlẹ Kwara, wọn ṣe akọlu si aafin ọba ati agọ ọlọpaa. ti wọn si ji eeyan mẹwaa gbe lọ.
O tẹsiwaju pe ni nnkan bi aago meji oru mọju ọjọ Aje, ni awọn ẹruku yabo ilu Yashikira, pẹlu ibọn ati awọn ohun ija oloro miran.
O ni wọn lọ agọ ọlọpaa to wa niluu ọhun sugbọn awọn ọlọpaa ti wọn wa lẹnu isẹ o jẹ ki wọn ri isẹ ṣe lori bi wọn ṣe koju wọn.
"Igba ti wọn kuro nibẹ ni wọn gba aafin ọba lọ nibi ti wọn ti dana sun apa kan aafin naa, ki wọn to ji iyawo ọba meji ati awọn ọmọ gbe lọ"
O fi kun un pe eeyan mẹwaa ni awọn agbebọn jigbe lọ sibi ti ẹnikéẹni ko mọ bayii.
O tẹ siwaju pe, Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo, ti ni ki iwadii bẹrẹ kiakia, ki gbogbo awọn ẹsọ alaabo wọgbo lọ lati lọ doola awọn araalu ti wọn jigbe lọ.
Kọmisanna, ni ati ọlọpaa ni, ọdẹ asọgbo, to fi mọ awọn fijilante ni wọn ti wọgbo lọ bayii, ki wọn le doola awọn araalu ti wọn jigbe.
O ni pe awọn agbesumọmi ti pe ogun bayii, wọn kede ogun lati maa da omi alaafia ilu ru ṣugbọn gbogbo wọn pata ni awọn yoo mu ti awọn yoo si fi wọn jofin.



























