Ọwọ́ ọlọ́pàá Hisbah tẹ ọkùnrin tó sá pamọ́ sínú àpò "Ghana Must-Go" nílé àlè

Awọn afurasi naa

Oríṣun àwòrán, Hisbah

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọlọpaa Sharia ipinlẹ Kebbi, Hisbah ti fi panpẹ ofin gbe ọkunrin kan to sa pamọ sinu apo "Ghana Must-Go" nile obinrin abilẹkọ kan niluu Birnin Kebbi.

Adari ajọ to n ri si ọrọ Sharia nipinlẹ naa, Sirajo Kamba, lo fidi iroyin naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria.

Gẹgẹ bii Kamba ṣe sọ, awọn olugbe agbegbe ọhun lo ke si Hisbah ni nnkan bii aago mejila kọja iṣẹju marundinlogun oru ọganjọ lọjọ kejidinlogun, oṣu Karun, ọdun 2026 yii pe ọkunrin naa wọ ile obinrin ọhun.

O ni "Awọn eeyan agbegbe naa gbagbọ pe awọn mejeji n ni ibaṣepọ to lodi si ilana ẹsin Musulumi, eredi ree ti wọn ṣe fi ọrọ naa to awọn alaṣẹ leti.

"Ni kete ti a gbọ iroyin naa, ajọ Hisbah Kebbi sare tete ran awọn agbofinro rẹ lọ sibẹ lati ṣewadii ohun to n ṣelẹ.

"Nigba ti awọn agbofinro wa de ibẹ, wọn bere fun aṣẹ lati yẹ ile naa wo amọ obinrin ọhun kọkọ sẹ wi pe ko si ẹnikẹni ninu ile oun."

Adari Hisbah naa sọ siwaju si pe lẹyinorẹyin, obirin naa gba ki wọn yẹ inu ile rẹ wo, asiko ti wọn n tu ile naa ni wọn ṣawari ọkunrin ọhun ninu apo "Ghana Must-Go" kan.

O fi kun pe iwadii awọn fi han pe ọkunrin naa n ba obinrin naa ṣere ifẹ bo tilẹ jẹ pe ile ọkọ lo wa.

O sọ siwaju si pe nigba ti wọn fi ọrọ wa awọn mejeji lẹnu wo, awọn mejeji jẹwọ pe lootọ ni wọn n ṣere ifẹ ati pe awọn mejeji yoo foju bale ẹjọ lati jẹjọ ẹṣẹ ti wọn ṣe labẹ ofin ẹsin Musulumi.

Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iṣẹlẹ naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe idajọ to yẹ awọn mejeji lo yẹ ki wọn gba labẹ ofin Sharia, bẹẹ lawọn mii n sọ pe ko si nnkankan to Hisbah nipa ibaṣepọ agbalagba meji ti wọn yan lati maa ṣere ifẹ pẹlu ara wọn.