Afurasí tó fẹ́ kó àwọn ọmọdé lọ ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ní Ghana rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá he l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun ti ran ọkunrin kan, Chukwuemeka Iheamama, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), ni ẹwọn ọdun mejila, fun ẹsun pe o n fi awọn ọmọdebinrin ṣe iṣe aṣẹwo.
Awọn ọmọde naa bi kootu ṣe darukọ wọn ni Bright Edim, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun ati Mary Ekong toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹẹẹdogun (15) bakan naa.
Gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti kiko eeyan lọ silẹ okeere lati lo won fun iwa aitọ 'National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons, (NAPTIP) ṣe ṣalaye, ẹsun mẹta ni Iheamama jẹjọ rẹ, wọn si ni I ṣe pẹlu kiko ọmọ ọlọmọ lọ silẹ okeere fun iṣekuṣe.
Nibo ni afurasi n ko ọmọde lọ tọwọ fi ba a?
Adari NAPTIP nipinlẹ Ogun, Bose Jimoh, ṣalaye pe ọwọ ba Chukwuemeka lọjọ kejila, oṣu Kẹrin ọdun 2025.
O ni awon ọlọpaa lo mu un lagbegbe Agbara, ipinlẹ Ogun nigba to n ko awọn ọmọdebinrin naa lọ si ọna Badagry, nibi ti wọn yoo gba lọ si Ghana ti wọn yoo ti maa ṣiṣẹ aṣẹwo.
Awọn ọlọpaa dari ẹjọ naa si NAPTIP bi Adari ajọ yii ṣe ṣalaye, fun iwadii ati ijiya to tọ.
" Olujẹjọ farahan ni kootu lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹfa ọdun "2025, niwaju Adajọ A. A. Okeke.
" Igbẹjọ bẹrẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2025. Adajọ si gbe idajọ kalẹ logunjọ oṣu Karun-un ọdun 2026, lẹyin to ri I pe olujẹjọ jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an."
Bẹẹ ni Bose Jimoh, Adari NAPTIP nipinlẹ Ogun ṣalaye.
Idajọ kootu
Adajọ ran Chukwuemeka lẹwọn ọdun meji fun ẹsun akọkọ, pẹlu owo itanran ẹgbẹrun lọna igba ataabọ naira (250,000).
O ran an lẹwọn ọdun marun-un fun ẹsun keji pẹlu owo itanran ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (500,000).
Ati ẹwọn ọdun marun-un fun ẹsun kẹta.



























