Ẹ gbaradì! Ó ṣeéṣe kí Ebola padà wọ Naijiria lẹ́yìn tó ti búrẹ́kẹ ní DR Congo àti Uganda – NCDC kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, WHO
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC, ti kilọ pe Naijiria wa ninu ewu arun Ebola lẹyin ti arun naa ti pada n ṣoṣẹ ni Democratic Republic of Congo (DRC) ati Uganda.
Bo tilẹ jẹ pe ko si arun naa ni Naijiria lọwọ yii, ajọ ọhun sọ pe bi awọn eeyan ṣe n rinrinajo lati orilẹede kan si omiran le mu ki arun naa rapala wọ Naijiria.
Ninu atẹjade kan, adari ajọ naa, Jide Idris, sọ pe arun naa lewu gidi fun awọn eeyan ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Awọn ibudo ayẹwo kokoro aifojuri to le koju arun Ebola ti wa ni sẹpẹ lati bẹrẹ iṣẹ ti wọn ba kofiri rẹ ni Naijiria"
O ni "Ayẹwo wa fi han pe Naijiria wa ninu ewu arun Ebola latari bi arun naa ṣe n ṣọṣẹ ni DRC ati Uganda, irinajo lati orilẹede kan si omiran ati bi awọn eeyan ṣe n jẹ lu ara wọn, to fi mọ bi a ko ṣe mọ bi arun naa ṣe gbilẹ to ati bi ko ṣe tete maa farahan, nitori apẹrẹ rẹ le farajọ awọn aisan mii bii iba ati Lassa."
Ajọ naa ni awọn ti ṣakiyesi awọn ipinlẹ kan to wa ninu ewu arun naa julọ nitori wọn jẹ ala si orilẹede mii ni Afrika, ibi ti ọpọ ọkọ n gba kọja ati ibi ti ọpọ arinrinajo lati ilẹ okere n gba wọle si Naijiria.
Gẹgẹ bi NCDC ṣe sọ, iṣẹ ti n lọ lọwọ lawọn orilẹede ti arun ọhun ti n ṣọṣẹ lọwọ yii lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ti fara kan awọn to ni arun ọhun.
O ni bi wọn ṣe n ṣayẹwo ninu laabu ni wọn tun n ṣe awọn nnkan mii bi ṣiṣẹ idanilẹkọọ fun awọn araalu.
"A mọ pe Ebola ti burẹkẹ ni Democratic Republic of the Congo (DRC), a tun gbọ pe o ti wọle si Uganda."
Ni ti awọn ọna lati gbogun ti arun ọhun ni Naijiria, atẹjade naa ni ọọfisi to n gbọ nipa iṣẹlẹ pajawiri, Emergency Operations Centre (EOC) ti wa ni sẹpẹ lati gbọ ti arun ọhun.
O ni Naijiria ni iriri arun naa tẹlẹri, o si ti ṣẹtan lati koju rẹ to ba pada wa.
Ni afikun, NCDC sọ pe awọn laabu to le koju arun naa ti wa ni sẹpẹ lati bẹrẹ iṣẹ ti wọn ba kofiri rẹ ni Naijiria.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ti bẹrẹ eto itaniji fun awọn araalu lati bẹrẹ si n ṣora gidi.


























