Ìgbésẹ̀ tó dáa ni ikọ̀ Ìrù Ẹkùn ti Sunday Igboho dá sílẹ̀, àmọ́ ìbọn kò gbọdọ̀ di tọ́rọ́ fọ́n kálé láàrin ilú - Onímọ̀ ààbò

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Ikọlu awon agbebọn to n gbilẹ si I lorilẹede Naijiria, ati ibẹru bojo to n pọ si i fun araalu lo fa idasilẹ ikọ alaabo kan ti a mọ si Iru Ẹkun.
Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho lo da Iru Ẹkun silẹ.
Ni bayii, Igboho ti n pe fun awọn ọmọ Yoruba tootọ to ba ṣetan lati darapọ mọ ikọ naa pe ki wọn maa bọ wa.
O ni eyi wa fun lati yabo awọn igbo ilẹ Yoruba tawọn agbesunmọmi ti fi ṣe ibuba, ki agbajọ ọwọ si di ohun tawọn yoo fi le gbogbo wọn jade.
Lori eyi, BBC Yoruba ba onimọ nipa eto aabo lorilẹede yii, Akin Adeyi, sọrọ, oun si ṣalaye awọn ohun to rọ mọ idasilẹ Iru Ẹkun bayii pe:

Oríṣun àwòrán, SUNDAY ADEYEMO IGBOHO FOUNDATION/CFACEBOOK
"Erongba daadaa ni ta a ba ṣe amulo ẹ ni ibamu pẹlu ohun ti wọn tori rẹ gbe e kalẹ"
"To ba jẹ bi wọn ṣe gbe e kalẹ ni a tẹle, o daa. Ṣugbọn bawo ni ko ṣe ni I yawọ mọ wa lọwọ nipasẹ iru awọn ti won ba ko o le lọwọ ati awọn ti wọn ba pe si I?
"Bawo ni ọwọ awọn oloṣelu ko ṣe ni I tẹ ẹ, ti ko ni I di ti ẹlẹyamẹya, ti wọn yoo maa koju ija ati ogun sira wọn.
"Nisinyi ti ipenija aabo wa kaakiri, gbogbo nnkan ti eeyan ba le ṣe ni yoo fẹ maa sa loogun, ṣugbọn ka ma fi iwanwara tẹ adiẹ to tẹ wa mọlẹ pada, nitori bi a ba ṣe bẹẹ, a maa tẹ adiẹ naa rẹ́ ni.
"Ọrọ yii n fẹ amojuto."
Akin Adeyi sọ pe agbekalẹ yii nilo ayẹwo daadaa, o ni o n fẹ amojuto ati ohun ti oloyinbo n pe ni 'Experience'' ti I ṣe iriri. O ni kawọn ta a fẹ fi ṣe aṣoju wa lori rẹ, atawọn ta a fẹ fi jẹ Balogun, ma pada di Aarẹ mọ wa lọwọ.
Amọtẹkun, fijilante, ọdẹ aṣogbo ati araalu to fẹẹ nibọn lọwọ
Nigba to n dahun ibeere lori awon ẹṣọ alaabo ibilẹ to ti wa lorilẹede yii bii Amotẹkun, awọn ọdẹ aṣọgbo, fijilante, Agbekoya ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn n lo ibọn, ati awon araalu tawọn naa n beere fun aṣẹ ijọba lati le gbe ibọn ti wọn yoo fi maa da aabo bo ara wọn lọwọ agbesunmọmi, Onimọ nipa aabo yii sọ pe:
"O daa fun awọn ẹṣọ bi wọn ba ni ẹ̀kọ́ ati akọsilẹ ohun ti ijọba ko le wọn lọwọ, amọ ti araalu lo gba ero ju.
"Bi obinrin ba tori pe ki ọbẹ oun le dun ju ti orogun lọ, to ba ṣe bẹẹ bu iyọ sọbẹ, ọbẹ naa yoo pada bajẹ ni.
"O rọrun lati ko ibọn le awọn eeyan lọwọ, ati gba a pada nkọ? Ta a ba tiẹ ri I gba pada, aburu ti ibọn yoo ti ṣe lọwọ awọn eeyan kaakiri nkọ.?
"Loooto ni oloyinbo pe ibọn ni 'Instrument of finality'' iyẹn ni pe oun naa lo maa pada yanju ọrọ, sibẹ, ko ṣee ṣe bẹẹ ko le araalu lọwọ.
"Asiko yii lo di pe bi ẹ ba fẹẹ gba ọdẹ sile lati maa ṣọ yin, yoo maa beere pe ibọn toun yoo lo n kọ.
"Ibọn ko wọpọ bayii nigba kan, Fulani ki I gbebọn daran, bi ẹ ba ri ibọn gan-an, ẹ o maa wo o bi nnkan ajeji ni. Ṣugbọn nisinyi, ibọn ti fẹẹ rọpo pọpa itẹlẹ tawọn eeyan n mu dani kaakiri.
"Kijọba rọra lori ati maa ko ibọn fun gbogbo eeyan, ko ma di pe a o pada kọju ibọn sira wa"
Akin Adeyi tẹsiwaju pe bijọba yoo ba ko ibọn fun awọn ọdẹ ibilẹ tabi agbofinro, wọn gbọdọ ṣe idanilẹkọọ ṣaaju fun wọn.
"Ṣe ẹ ti ṣe idanilẹkọọ fun wọn nipa ibọn ti ẹ fẹ ko fun wọn?
Ṣe wọn mọ ki lo le fa ki eeyan yinbọn, ta a la le kọju ibọn si, asiko wo ni eeyan n yinbọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.
"Ṣe ẹni ti ẹ fun nibọn ṣi n ba yin ṣe abi o ti darapọ mọ ibomi-in? Gbogbo eyi yẹ lati mojuto.
Adeyi sọ pe bi araalu ba ṣe bẹẹ maa gbe ibọn dani, "Ẹlomi-in gan- an yoo yinbọn para rẹ nipasẹ aimọ tabi ko yin in pa araale rẹ."
O ni ilu ti ibọn ba si ti pọju, ogun lo maa n kẹyin wọn.
O tẹsiwaju pe kijọba gbiyanju wa ọna mi-in ti wọn yoo fi yanju ọrọ yii.
'Loootọ ni awon to n doju kọ wa n gbebọn, ṣugbọn ti ijọba ba ni eto, won a wa ọna ati gba awọn ibọn yẹn pada lọwọ wọn.
Awọn ijọba orilẹede to laami laaka maa lo ọgbọn lati gba a pada, ijọba lo ni eyi lati ṣe, araalu yoo kan maa ta wọn lolobo nipa awọn ibi ti ibọn wa naa ni.
"Were la fi n wo were, ibọn to le ju ti agbesunmọmi lọ lo yẹ kijọba fun awọn ikọ Iru Ẹkun to fẹẹ koju agbebọn"
Lori awọn ikọ Iru Ẹkun to fẹẹ koju awọn agbesunmọmi ninu igbo yii, Onimọ nipa aabo naa sọ pe ki I ṣe ibọn ṣakabula ni wọn yoo gbe wọbẹ o.
"Ni ti Iru Ẹkun yii, were la fi n wo were ni, mo nigbagbọ pe ki I ṣe ṣakabula ni wọn maa ko le wọn lọwọ, bẹẹ ni ki I ṣe ibọn oloju meji.
"Wọn gbọdọ ko awon ibon jagamu gidi, iru eyi ti awọn ajingbe gbe lọwọ tabi to lagbara ju u lọ le wọn lọwọ. Ki wọn gbagbe pe ẹnikan gbọdọ gba aṣẹ tabi licence kan ko too lo ibọn.
Adeyi sọ pe ohun to ba mu Fulani to fi n lo AK-47, AK-49 to fi n daran, bawo ni ọbọ ṣe ṣori ti Inaki o ṣe.
O ni ṣugbọn idanilẹkọọ gbọdọ wa. O ni gbogbo ibọn wọnyi naa lo si ni nọmba bii mọto, ki wọn mọ awọn ti wọn ko o fun, nib oni wọn wa, ki ni wọn fi n ṣe.
Ṣugbọn ni ti araalu, o ni ki ijọba wa ọna aabo mi-in.
Adeyi sọ pe o le dohun ti inu yoo bi eeyan lọjọ kan, ti yoo wọle lọ gbebọn.
"Ki ibọn ma di ohun ti a le bọ sọja ti a le ra, ki ibọn ma di ohun ti ewurẹ Baba Rabi yoo jẹ oko Baba Sunday, ti Baba Rabi yoo kan lọ yọ ibọn, ti yoo pa Baba Sunday danu."
Bẹẹ ni Akin Adeyi ṣalaye.
Sunday Igboho ní Tinubu ti fòńtẹ̀ lu ikọ̀ aláàbò Iru Ekun, ṣàlàyé báwọn èèyàn ṣe le darapọ̀

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu ẹṣọ eleto aabo Iru Ẹkun toun da silẹ.
Igboho sọ ninu fidio kan to fi lede lori itakun ayelujara wi pe lẹyin toun gbe ẹṣọ eleto aabo Iru Ẹkun de iwaju Tinubu ni aarẹ tẹwọ gba a.
Oloye Igboho wa kepe gbogbo ọmọ Yoruba to jẹ Akinkanju lati darapọ mọ ẹṣọ Iru Ẹkun lati le jọ ṣiṣẹ pọ wa ojutuu si iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan to n pọ si i lawọn ipinlẹ Yoruba bayii.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram
"Wọn fẹ da ijọba Tinubu laamu, ki awọn eeyan le maa sọ pe ilu o fararọ, to fi de ilẹ Yoruba gan an ti aarẹ ti wa"
''A ko gbọdọ faye gbawọn janduku agbebọn ti wọn ti bẹrẹ sii ṣọṣẹ lawọn ipinlẹ wa bayii.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan ti wọn ṣe gan an niyi lasiko ti Aarẹ Goodluck Jonathan wa lori oye.
Nigba yẹn ni wọn lọ ko awọn Boko Haram jade lati maa da ijọba Jonathan laamu.
Nnkan ti wọn si fẹ ṣe lasiko yii ni pe wọn fẹ da ijọba Tinubu laamu, ki awọn eeyan le maa sọ pe ilu o fararọ to fi de ilẹ Yoruba gan an ti aarẹ ti wa.
Awa la o nii gba fun wọn lati da ijọba Tinubu ru, tori ọmọ ẹni ko ni ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomiran,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
Owo Baba Dami ni ilẹ Yoruba ko gbọdọ faye gba awọn oloṣelu ti wọn ko awọn janduku agbebọn sabẹ.
Ajigbara fun idasilẹ Yoruba Nation sọ pe agbesunmọmi ni ẹnikẹni to ba n pa eeyan to si tun n ji eeyan gbe pawo.
Igboho ni o ṣee ṣe ko ma jẹ pe awọn Fulani nikan lo n ṣiṣẹ laabi yii.
Oloye Adeyemo sọ pe ọdaran ni ẹnikẹni ti oun atawọn ẹṣọ Iru Ẹkun ba le ba ninu igbo ọba nilẹ Yoruba.
Sunday Igboho ni ko si nnkan kan to le mu ki eeyan maa gbe ninu igbo, o ni igboro lo yẹ ki gbogbo eeyan maa gbe gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.
Ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ Iru Ẹkun ko ni lati sanwo fọọmu kankan - Igboho
Owo Baba Dami ni awọn oloṣelu kan lo wa nidii awọn janduku to n ji awọn eeyan gbe pawo ni Naijiria.
O wa rọ gbogbo awọn ọmọ Yoruba wi pe ki wọn ma jẹ kawọn janduku agbebọn ba ilẹ Yoruba jẹ.
''Ko si giri kankan, ọrọ to wa nilẹ yii kii ṣe ọrọ ija ẹsin tori onigbagbọ lemi naa.
Iyawo mi keji ti lọ si Mecca tori musulumi ni, o si maa n kirun ninu ile.
Mi o dẹ binu si i nitori pe emi gan an maa n lọ si ṣọọṣi, awọn oniṣẹṣe si lawọn obi mi.
Ki ni a wa fẹ maa bara wa ja fun? Kii ṣe ọrọ ẹsin, ẹ jẹ ka gbe ọrọ ẹsin si ẹgbẹ kan.
Ẹ jẹ ka doju kọ awọn janduku ti wọn n ji awọn ọmọ wa gbe lọ.
Ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ Iru Ẹkun ko ni lati sanwo fọọmu kankan.
A maa fi nọmba foonu awọn alakoso Iru Ẹkun ni ipinlẹ kọọkan lede fun ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ wa lati pe.
Ijọba naa maa ṣe atilẹyin fun wa ti a ba ti n ba iṣẹ lọ, tori ọmọ to ba ṣi apa ni baba maa n gbe.
Awa ni a ni nnkan wa, ọmọ oniluu ti ko ni fẹ ki ilu rẹ tu ni wa, ẹ jẹ ka jọ fọwọ sowọ pọ,'' Oloye Adeyemo ṣalaye.
Igboho ni awọn oloṣelu to wa nidii ọrọ awọn janduku ajinigbe yii fẹ ba ijọba Tinubu jẹ ni.
Owo Baba Dami ni ilẹ Yoruba ko ni gba kawọn oloṣelu kan ba ijọba Aarẹ Tinubu jẹ.




























