Ta ló wọlé ìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú Accord láti dupò Gómìnà l'Oyo láàrin Oriyomi àti Gudugudu? Ohun tí a mọ̀ rèé

Họnarebu Busari Olakunle wọ aṣọ buba dudu ati fila dudu, Oriyomin Hamzat wọ ẹwu olomi buluu, o si mu iwe ẹri moyege lọwọ ati ẹrọ gbohungbohun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Eto idibo abẹnu lati mọ oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ Accord ti ipinlẹ Oyo, to waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un yii, lo ti pin ẹgbẹ oselu naa si meji bayii.

Idi ni pe a ko le sọ ni pato oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu ibo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027.

Hamzat Oriyomi ni a kọkọ gbọ pe o wọle idibo abẹnu ọhun niluu Ibadan.

Koda, BBC Yoruba tun ri fọnran atawọn aworan ti wọn ti gbe ọwọ Oriyomi soke, ti wọn si fun un ni iwe ẹri gẹgẹ bii oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo.

Lẹṣẹ kẹsẹ ni iroyin mii tun tan kalẹ lori itakun ayelujara tawọn eeyan si bẹrẹ sii gbe e kiri pe Olakunle Busari, ti ọpọ eeyan mọ si Gudugudu, lo jawe olubori. .

Ṣaaju eto idibo naa ni ọkan lara awọn oludije mẹta sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Accord, Ọgbẹni Fatai Owoseni, juwọ silẹ fun Alhaji Oriyomi lati ṣe atileyin fun un.

Àlàyé Fatai Owoseni ree lori idi to fi ni oun ko kopa mọ ninu idibo abẹle fun ipo gomina

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe Fatai Owoseni le sọ pe oun ko ni i tẹsiwaju ninu idije naa mọ, o si ya wọn lẹnu bo ṣe gbe igbesẹ naa lojiji.

Ninu atẹjade ti Owoseni fi kede idi ti ko fi tẹsiwaju mọ loju opo Facebook rẹ lo ti ni:

"Mo de ikorita apero" ‎‎

‎Owoseni to ti figba kan ri ṣe kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, ṣalaye pe awọn nnkan kan toun ri, to n sẹlẹ ninu ẹgbẹ Accord fi han pe ẹgbẹ naa n gbe sẹyin ẹnikan ju awọn iyoku lọ.

‎O ni awọn kan tun lo awọn janduku ati ọmọ iṣọta nigba ti eto idibo abẹnu n lọ lọwọ, lati ri i pe gbogbo eto naa ko kẹsẹ jari.

Owoseni sọ pe pẹlu gbogbo ohun ti oju oun ri yii, oun yẹba ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu Accord.

Amọ ṣaa, kọmiṣanna ọlọpaa tẹlẹ naa sọ pe boun ṣe loun ko ṣe mọ ko tumọ si pe ojo loun. Owoseni sọ pe yiyọ Ẹkun, tojo kọ.

Atejade ti Owoseni fi ni oun yẹba.

Oríṣun àwòrán, Fatai Owoseni

Bawo ni eto idibo abẹnu naa ṣe lọ?

Adebukola Ajaja, Akọwe apapọ ẹgbẹ Accord pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ INEC la gbọ pe wọn wa nibi eto idibo abẹnu to waye, ibudo ti wọn wa si yatọ si ibi ti Oriyomi wa.

Wọn si woye rẹ bo ṣe lọ, ki wọn too kede Olakunle Busari bii ẹni to jawe olubori.

Aṣoju eto idibo, Olayinka Dairo to wa fun akojọpọ onka ibo ti awọn oludije ni, ṣalaye nigba to n kede esi ibo naa, pe Busari ni ibo 29,427.

O ni Oriyomi Hamzat ni ibo 18,716, nigba ti Fatai Owoseni to ṣikẹta ni ibo 11,922 .

Ninu iwoye rẹ, Akọwe apapọ ẹgbẹ Accord sọ pe idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ, o si fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ajọ INEC wa nibẹ titi ti wọn fi pari rẹ ni.

"Mo fẹ ka mọ pe nigba ti idibo yii ti waye ni irọwọrọsẹ, a gbọdọ gba abajade yowu to ba mu wa ni.

"Ẹ jẹ ka bẹrẹ bayii ka si wo ibi giga ti a le gba ẹgbẹ Accord de."

Ki ni ẹgbẹ Accord sọ lori Olakunle Busari ati Oriyomi Hamzat?

Atẹjade ti ẹgbẹ Accord fi kede pe Olakunle Busari ko le dije fun ipo gomina.

Oríṣun àwòrán, Accord Party Oyo state

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu Accord lati ilu Abuja, ti igbakeji akọwe agba ẹgbẹ naa, Họnarebu Abdulrahman Danladi, ko sodi ni wọn wa nibi ti Oriyomi Hamzat wa.

Họnarebu Abdulrahman ṣalaye pe oludije kẹta, Ọgbẹni Busari Olakunle kuna lati pari awọn ayẹwo ti ẹgbẹ oṣelu Accord gbe kalẹ.

Idi si niyi ti Ọgbẹni Busari ko se kunju oṣuwọn lati dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord ninu eto idibo to n bọ.

Leyin naa ni Abdulrahman kede pe Alhaji Oriyomi ni oludije to koju oṣuwọn julọ, to si kede rẹ gẹgẹ bi oludije sipo Gomina nipinlẹ Ọyọ fun ẹgbẹ Accord ninu eto idibo to n bọ ni odun 2027.

Lati fidi ẹ mulẹ pe Busari ko peye lati dupo naa, ẹgbẹ Accord ipinlẹ Oyo fi atẹjade to kede eyi sita.

Bi igbesẹ naa se n waye, ni igun awọn Ajaja naa n seto idibo abẹnu fun ẹgbẹ oselu Accord, nibi ti wọn ti kede lẹyin o rẹyin pe Gudugudu lo gbegba oroke

Wayi o, Gudugudu ti wa tako ikede awọn asoju ẹgbẹ lati Abuja naa, to si ni oun ni oludije tootọ, koda ajọ eleto idibo ti a mọ si INECwa nibi eto idibo abẹnu ti oun wa.

Bayii lo si ṣe di pe Olakunle Busari ati Oriyomi Hamzat ni kaluku wọn n ke pe oun loun wọle ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu Accord l'Oyo.

Emi ni aṣoju ẹgbẹ Accord ninu eto idibo gomina to n bọ nipinlẹ Oyo - Olakunle

Busari Olakunle tawọn eeyan mọ si Gudugudu wọ asọ toketilẹ alawọ ewe, o fi ọwọ mejeeji mu kaadi idamọ ẹgbẹ oselu accord

Oríṣun àwòrán, Busari Olakunle

‎Ninu ifọrọwerọ ti Olakunle ṣe pẹlu BBC lo ti ni ko si ani-ani pe oun loun wọle ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu Accord to waye nipinlẹ Oyo lọjọ Iṣẹgun.

‎Olakunle sọ pe:

"Eto idibo abẹnu waye ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn kaakiri ipinlẹ Oyo, ‎nibi ti alaga ati akowe ẹgbẹ oṣelu Accord ipinlẹ Oyo ati awọn to ta fọọmu idibo fun wa ni ki n lọ naa ni mo lọ.

"Nibẹ si ni aṣoju ajọ INEC wa, ti wọn ti fa ọwọ mi soke. Boya wọn wa kede ẹlomiran lẹyin mi ninu ẹgbẹ Accord, emi ko mọ.

‎"Ko si igbesẹ mii ju pe mo ti di aṣoju ẹgbẹ ninu eto idibo to n bọ."

"Mo ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu gbogbo eeyan. A maa ṣiṣẹ pọ a si maa forikori fun itẹsiwaju ati idagbasole ipinlẹ Oyo."

Bẹẹ ni Olakunle Busari ṣalaye.

O fi kun un pe ẹgbẹ ni yoo sọ ilana ibi ti awọn n lọ, bi wọn ba si ti ṣe gbogbo ohun to yẹ tan lo ni eto ipolongo ibo yoo bẹrẹ pẹrẹwu.

Oriyomi Hamzat naa dupẹ fun aṣeyọri rẹ

Oriyomi Hamzat wọ asọ T-Shirt alawọ ofeefee ti wọn kọ Oyo n pe ọ siwaju rẹ, o si de fila rẹ bakan naa, o tun lo awo oju

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X

Ninu ọrọ to sọ lẹyin ti wọn kede rẹ bii oludije gomina fun ẹgbẹ oselu Accord nipinlẹ Oyo, eyi to wa loju opo X rẹ, Oriyomi Hamzat fi idunnu rẹ han si bi awọn àgbaagba ẹgbẹ ṣe wa si ipinle Ọyọ, lati ṣeto ibo abẹnu naa.

Oriyomi fi kun ọrọ rẹ pe, gbogbo ohun daradara ti oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni oun yoo pari, ati pe, oun ko ni doju ti ẹgbẹ Accord ati gbogbo eeyan ipinlẹ Ọyọ lapapọ.

O fi kun un pe, ẹgbẹ oṣelu Accord ko ni ba ẹgbẹ oṣelu kankan dunadura lati darapọ mọ ẹgbẹ mii.

O wa rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ, ki awọn alatako ma ba ri aye wọle si aarin ẹgbẹ naa.

Atẹjade ti Oriyomi Hamzat fisita lẹyin ti wọn kede rẹ bii oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu Accord nipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X

‎ ‎Ta ni ẹgbẹ wa fa silẹ bayii?

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ibi ti ọrọ ẹgbẹ oṣelu Accord Oyo dojukọ lori ẹni ti ẹgbẹ fi ọwọ si lati dije fun ipo gomina ko ti i fi ibi kankan ye ẹnikẹni.

Idi ni pe bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ Accord kede Oriyomi Hamzat, igun ti Gudugudu ni ajọ INEC fi si.

Gudugudu funra rẹ sọ fun BBC ninu ifọrọwerọ, pe iwe ẹri to wa lọwọ Oríyọmí Hamzat ko tumọ si pe Oriyomi lo jawe olubori.

O ni ibi ti Alaga ati Akowe ẹgbẹ Accord ti Ipinlẹ Oyo ati awọn to ta foomu idibo fawọn wa naa ni aṣoju INEC wa, ti wọn ti fa ọwọ oun soke.

Gudugudu ni eyi tumọ si pe oun ni ẹgbẹ ati INEC da mọ niyẹn.

Bakan naa si ni Oriyomi Hamzat naa ti gbe igba ọpẹ ni tiẹ, to si ti n leri pe oun yoo ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa fun bi ẹgbẹ ṣe fa oun kalẹ yii.

Ṣugbọn ohun to daju ṣaka ni pe eeyan meji lo n ri ara wọn bii oludije ti yoo dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Accord fun ipo gomina ni 2027, Oriyomi Hamzat ati Olakunle Busari ni.

Laipẹ, a mọ ibi ti igi ọrọ naa yoo wo si.