Ìjì òjò líle sí òrúlé, da ògiri wó nílé ẹ̀kọ́ girama ọgbọ̀n l‘Ogbomoso, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ n kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ilé àlàpa
Ni ọjọ Kẹjọ osu Kẹrin ọdun 2026, ojo nla kan rọ ni agbegbe Ogbomoso, eyi to mu iji lile lọwọ.
Lẹyin iji naa, ọpọ ile ni orule wọn si, awọn kan da wo lulẹ, eyi ti ko yọ ile ẹkọ ijọba ipinlẹ Oyo silẹ.
Ni apapọ, awọn ileẹkọ to da wo lulẹ le ni ọgbọn, ti ọpọ akẹkọọ atawọn Olukọ si n kẹkọ labẹ ile alapa.
Idi ree ti BBC News Yoruba fi gba ilu Ogbomoso lọ lati mọ bi ipa ọsẹ ojo lile naa ni lori awọn araalu naa, paapaa awọn ileẹkọ ijọba.

"A da awọn akẹkọ wa papọ lati kẹkọ, ti gbọngan nla ileẹkọ naa si ti di ẹgẹrẹ miti, a ko si ri lo, gẹgẹ bi a ti maa n lo o tẹlẹ"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, awọn ọga ile ẹkọ lawọn ile ẹkọ to fara gba ninu ọsẹ iji ojo naa salaye pe o le ni ọgbọn ile ẹkọ ti ọrọ naa kan.
Awọn ile ẹkọ ti ọrọ yii kan ni ile ẹkọ Ogbomoso Grammar School, Muslim Comprehensive school, Baptist High School, Emmanuel Agboola Baptist Grammar School ati ọpọlọpọ ile ẹkọ miran.
Ọga agba ile ẹkọ girama Emmanuel Agboola, Femi Ogunlana, sọ fun BBC News Yoruba pe iji lile naa gbe orule yara ikawe meji, to si wo apa ogiri meji lara gbọngan tawọn akẹkọjade wọn ti n se idanwo WAEC.
"A ko ni awọn yara ikawe to to tẹlẹ lati lo, a kan sa n yi gbogbo rẹ mọra wọn ni amọ bi orule yara ikawe meji mii tun se wa si lọ yii, o tun din awọn yara ikawe wa ku.
A wa da awọn akẹkọ wa papọ lati kẹkọ, ti gbọngan nla ileẹkọ naa si ti di ẹgẹrẹ miti, a ko si ri lo, gẹgẹ bi a ti maa n lo o tẹlẹ."
Ogunlana wa fidi rẹ mulẹ pe o ti to awọn leti pe ijọba ti n gbe igbesẹ lati se atunse awọn ileẹkọ naa, laipẹ, laijinna, atunse naa yoo waye.
"Bi kii ba se isẹlẹ ikọlu agbebọn to waye ni Ogbomoso laipẹ yii, pẹlu nnkan ti a gbọ, awọn eeyan ti ijọba ran jade ko ba ti wa si Ogbomoso lati se atunse awọn ileẹkọ naa.

"A nilo iranlọwọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo, ki wọn ranti wa, a si tun nilo iranwọ lati ọdọ awọn obi ati ẹgbẹ awọn akẹkọjade ileẹkọ wa"
Bakan naa ni olukọ agba ile ẹkọ girama miran, Tolani Adewumi sọ fun BBC News Yoruba pe awọn yara ikawe kan wa to wo lulẹ nile ẹkọ toun.
"A nilo iranlọwọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo, ki wọn ranti wa, a si tun nilo iranwọ lati ọdọ awọn obi ati ẹgbẹ awọn akẹkọjade ileẹkọ yii.
Ninu ọrọ tiẹ, Olukọ agba fun ile ẹkọ girama miran, Dele Omololu ni salaye pe ẹru bukata awọn ile ẹkọ yii pọ ju.
O ni lootọ lo jẹ pe ijọba ipinlẹ Oyo lo ni awọn ile ẹkọ girama to bajẹ yii, sibẹ, awọn si nilo iranwọ awọn obi ati ẹgbẹ akẹkọjade nile ẹkọ naa.

Ki ni asoju ijọba sọ?
BBC News Yoruba wa lọ sileesẹ eto ẹkọ nipinlẹ Oyo lati mọ bi ijọba se mu atunse awọn ile ẹkọ yii ni ọkunkundun si.
Ọgbẹni Tiami Abiodun to ba wa sọrọ ni awọn ti n gbe igbesẹ lori atunse awọn ile ẹkọ to bajẹ naa.
"A ti ran awọn ikọ atọpinpin wa sita lati lọ wo awọn ileẹkọ to bajẹ naa lati mọ iye ti yoo na wa lati se atunse awọn ile ẹkọ to da wo naa.
Ni kete ti a ba ti gba asẹ lati lọ sisẹ lori awọn ileẹkọ naa, la bẹrẹ atunse lori wọn."






