Afurasí tó gún ₦56.4m owó Hajj tó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́bẹ n'Ibadan fojú ba ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Ajọ EFCC to n gbogunti iwa jibiti lorilẹede Naijiria ti fi oju ọkunrin kan, Lawal Babale Musa, ba ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo, lori ẹsun gbigba N56.4m lọwọ awọn eeyan kan gẹgẹ bii owo irinna fun iṣẹ Hajj, lorilẹede Saudi Arabia.
Ọjọbọ, ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni Musa jẹjọ lori ẹsun mẹtadinlọgọta (57) to ni i ṣe pẹlu ole jija ati iwe yiyi.
Gẹgẹ bi EFCC ṣe ṣalaye, awọn ti olujẹjọ lu ni jibiti owo naa ni: Jibril Adamu, Suleiman Aminatu, Musa Haruna, Suleiman N. Abdullahi, Audu Bello, Yusuf Umaru, Saidu Musa, Idris Suleiman, Musa Yunusa ati Usman Haruna.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ gan-an?
Gẹgẹ bi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan Lawal Babale Musa, ṣe wi, wọn ni o gba N56,491,000 lọwọ awọn eeyan naa laaarin ọjọ keji oṣu Kọkanla ọdun 2022, si ọjọ kejilelogun oṣu Keje ọdun 2024.
Ohun ti wọn lo sọ fun wọn ni pe oṣiṣẹ ajọ to n ri si irinajo Mecca nipinlẹ Kaduna, ((Kaduna State Pilgrims Welfare Agency) ni oun.
EFCC sọ pe Musa gba owo naa lati fi ba wọn ṣeto irin ajo Hajj ọdun 2023, eyi to ni ipasẹ ajọ to n ri si irinajo Mecca nipinlẹ Kaduna loun yoo fi ko wọn lọ.
Wọn fi kun un pe Musa tun yi iwe ẹri owo sisan ajọ to n ri si irinajo Mecaa nipinlẹ Kaduna.
EFCC sọ pe o yi iwe naa ti nọmba rẹ jẹ 0013041, orukọ ti wọn lo si wa nibẹ ni Jibril Adamu.
Iwe ẹri owo sisan keji ti wọn lo tun yi ni 012654, o si mu un fun Adamu gẹgẹ bii ojulowo.
Awọn eeyan ti EFCC sọ pe Musa lu ni jibiti yii jẹ darandaran lagbegbe Oke Ogun, ipinlẹ Oyo bi wọn ṣe sọ.
Amọ ko si eyi to ri Mecca naa lọ ninu wọn lẹyin ti Musa gba owo lọwọ wọn gẹgẹ bi alaye EFCC.
Musa loun ko jẹbi awọn ẹsun yii.
Aṣẹ ile ẹjọ
Lẹyin ti olujẹjọ ni oun ko jẹbi, agbẹnusọ fun EFCC, Bashir Shamsuddeen, rọ kootu lati fi i pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ yoo tun fi waye.
Amọ agbẹjọrọ rẹ, Kehinde Adegbola, ni ki kootu fi aaye gbigba oniduuro rẹ silẹ, nitori oun ti gbe igbesẹ lati ri i pe adajọ fi aaye beeli silẹ fun un.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Olusola Adetujoye, paṣẹ pe ki wọn fi Musa pamọ si ọgba ẹwọn Agodi.
O sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ yii.



























