Kókó ọ̀rọ̀ tí Arike Ẹrọ sọ léyìn tí olùdíje APC lulẹ̀ nínú ètò ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, G. S. Babatunde/X
Alhaja Falilat Yusuf ti ọpọ mọ si Ero Arike to tun jẹ adari awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti sọrọ fun igba akọkọ lẹyin ti Bola Munirudeen Oyebamiji, oludije APC ninu eto idibo gomina ipinlẹ Osun to waye lanaa ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ lulẹ.
Ero Arike kọkọ ki awọn awọn ololufẹ rẹ atawọn alatilẹyin Oyebamiji fun aduroti wọn ninu eto idibo naa.
Alhaja Yusuf sọrọ yii ninu fọnran kan eyi to ti lu ori ayelujara pa bayii.
''Mo ki gbogbo ọmọ Naijiria nile, loko ati lẹyin odi, mo si tun ki ẹyin ololufẹ wa nipinlẹ Osun ati gbogbo ẹyin afẹnifẹre.
Ẹyin ti ẹ dide lanaa lati dibo fun baba wa Munirudeen Oyebamiji, mo tun ki lọba lọba, mo ki ijoye.
Mo ki awọn pasitọ, awọn alfa atawọn ẹlẹbọ.
Lori ọrọ to n lọ kaakiri bayii nipa eto idibo gomina Osun ni mo fẹ sọ nipa rẹ.
Bi ọrọ oṣelu ṣe maa n ri niyẹn, ni ṣe lo da bii tẹtẹ, ẹni ti Ọlọrun ba ni ko jẹ ni.
Nigba ti a dibo ti baba wa Gboyega Oyetola ati baba wa Nurudeen Jackson Ademola Adeleke jọ dije ninu ibo gomina ipinlẹ Osun, ẹyin Adeleke ni mo wa.
Mo duro fun wọn daadaa de bi wi pe awọn naa mọ, amọ, a pada lulẹ nigba yẹn pẹlu Adeleke tori Oyetola lo wọle,'' Ero Arike ṣalaye.
Ero Arike ni ko si ẹni to lepa oun kaakiri nigba naa lati ṣekupa oun.
O ni ko sẹni to mọ pe oun tun le pada ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC lonii.
Ero Arike wa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC lati fọwọ wọnu ki wọn si ṣe ọkan akin tori bi ọrọ ibo ṣe maa n ri nigba mii niyẹn.
Alhaja Yusuf ni kii ṣe tuntun kawọn oloṣelu maa bu ara awọn, ẹni ti Ọlọrun ba ni o jẹ lọ ni.
Ero Arike tun sọ pe Oyebamiji ko le sọ ireti nu ''tori o ti ṣe Anabi kan bẹẹ naa ri.''
Bakan naa ni Ero Arike tun sọ pe ifẹ tawọn ni si Oyebamji ko yi pada rara.
O ni Oyebamiji naa maa pada ṣe gomina ipinlẹ Osun lagbara Ọlọrun.


























