Èèyàn 27 jáde láyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlu ilé ìgbáfẹ́ méjì mọ́júmọ́

Awọn ọlọpaa to duro si ẹgbẹ ọkọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni eeyan mẹtadinlọgbọn (27) ti wọn ti padanu ẹmi wọn ni orilẹ ede South Africa ni ooru mọjumọ owurọ yii.

Ni ẹkun Guateng ati Western Cape ni iṣẹlẹ iṣekupani naa ti waye laaarin wakati marun-un sira wọn ni alẹ ọjọ Abamẹta mọju ọjọ Aiku.

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ ede naa ṣalaye pe nnkan bii aago mẹsan-an abọ alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn agbebọn kan yawọ ile igbafẹ ni Carletonville, ti ko ju ọgọrin kilomita si Johannesburg lọ ti wọn si gbẹmi eeyan mẹtadinlogun (17).

Bakan ni awọn eeyan to farapa ninu ikọlu naa jẹ mẹẹdogun (15).

Ninu ikọlu mii ni awọn agbebọn tun yawọ ile igbafẹ mii ni Lwandle ni Western Cape nibi ti wọn ti pa eeyan mẹwaa (10), tawọn mọkanla (11) mii si tun farapa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa ikọlu naa, ti wọn si ti faili fun ẹsun ipaniyan fun awọn afurasi to ṣe ikọlu ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa niṣe ni awọn afurasi agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ fun awọn eeyan ti wọn ba nibi ti wọn ti n mu ọti ni ita awọn ile igbafẹ naa.

Wọn ni lẹyin ti wọn ṣina ibọn bolẹ fun awọn eeyan naa tan ni wọn tun wọnu ile igbafẹ naa lọ, ti wọn si tun yinbọn mọ awọn eeyan.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọlọpaa sọ pe awọn afurasi naa wa awọn eeyan kan, gba foonu wọn ki wọn to kuro nibi ikọlu ọhun, ti wọn si tun sun ọkọ meji nina ki wọn to lọ.

Ọkunrin mẹtala (13) ati obinrin mẹrin (4) ni iroyin ni wọn padanu ẹmi wọn nibi ikọlu akọkọ nigba ti awọn marun-un (5) si padanu ẹmi wọn lẹyẹ o sọka nibi ikọlu keji, ki awọn marun-un (5) mii to padanu ẹmi wọn nile iwosan.

Ohun to ṣokunfa ikọlu yii ko i tii ye ẹnikẹni amọ ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lati nawọ gan awọn afurasi to ṣiṣẹ ibi naa.

South Africa wa lara awọn orilẹ ede ti ipaniyan ti n waye julọ ni agbaye, tawọn alaṣẹ si n koju ipenija lati fopin si iṣẹlẹ awọn ọmọ ganfe to maa n fi ibọn para wọn.

Ikọlu yii lo n waye lẹyin ọjọ diẹ tawọn agbebọn ṣekupa eeyan mọkanla (11) ninu ile igbe kan ni agbegbe Durban.

Nini ibọn lọwọ lọna aitọ kun South Africa, tawọn alaṣẹ si ni akọọlẹ iṣẹlẹ iṣekupani ọgọta (60) lo maa n waye lojumọ nibẹ.

Ikọlu lo saba maa n waye laaarin awọn igun ti wọn n gbe egboogi oloro atawọn to n wakusa lọna aitọ.

Ni oṣu Keji ọdun yii, Aarẹ Cyril Ramaphosa sọ pe iṣẹlẹ iṣekupani ni iwa ọdaran to n koju iṣejọba awaarawa, awujọ ati eto ọrọ aje orilẹ ede naa.