You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kókó ọ̀rọ̀ méje tí Tinubu sọ láti sàmì àyájọ́ June 12 àti àwọn tó gba àmì ẹ̀yẹ fọ́dún kẹtàdínlọ́gbọ̀n ìjọba àwaarawa
Oni ọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 lo pe ọdun mẹtadinlọgbọn (27) ti ijọba awaarawa ti a mọ si Demokresi ti n lọ geere ni Naijiria pẹlu ilana ibo didi.
Lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun-un ọdun 1999 ti Oloye Olusegun Obasanjo ti bẹrẹ ijọba tiwa-n-tiwa pada lo ti n lọ bẹẹ titi di oni yii ti Aarẹ Bola Ahmed n dari Naijiria.
Eyi naa lo mu Tinubu ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laaarọ oni, lori bi ijọba awaarawa ṣe n ba a bọ, bi nnkan ṣe ri loni ati ireti ọtun ti Naijiria ni.
"Demokresi yii ko gun rege, amọ tiwa-n-tiwa"
Nigba to n ṣide ọrọ rẹ, Aarẹ Tinubu sọ pe bo tilẹ jẹ pe ijọba awaarawa asiko yii ko gun rege, sibẹ, oun lo pẹ ju, tẹni si ni tẹni.
O ni awọn eeyan Naijiria gbọdọ da aabo bo o, ki wọn si maa ro o lagbara si i.
- Ẹ le ma gba temi, ṣugbọn ẹ ma ṣai nigbagbọ ninu Naijiria:
Aarẹ Tinubu ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn aṣofin apapọ, awọn eleto idajọ, awọn oniroyin, ẹgbẹ awujọ le ma gba toun, wọn si le tako ero oun pẹlu, ṣugbọn ki wọn ma ṣalai gbagbọ ninu Naijiria gẹgẹ bii orilẹede.
- Ẹyin ọ̀dọ́: Naijiria yii ni ile yin ati ọ̀la yin, ẹ ṣiṣẹ yin nibi."
Mi o le waa ku ki i joye ile baba rẹ ni Aarẹ sọ fawọn ọdọ.
- Awọn ọmọ wa ti wọn gbe lọ l'Oyo ati Borno mu nnkan ri bakan lasiko yii:
Ijinigbe ti wọn fi ko awọn akẹkọọ atawon oluko wọn lọ nipinlẹ Oyo ati eyi to ṣẹlẹ ni Borno lọjọ kan naa ni Aarẹ sọ pe o ṣi n fa ibanujẹ.
O ni ṣugbọn iṣakoso oun ti ṣafikun awon ọlọpaa pẹlu agbofinro ẹgbẹrun lọna aadọta mi-in atawọn ṣọja, bẹẹ ni N5.41 trillion ni owo tijọba yii ya sọtọ fun aabo.
- Ipaniyan ti dinku ni ida 81% lati 2015
Aarẹ ṣalaye pe iṣekupani nilana igbesunmọmi ti dinku nilọpo mọkanlelọgọrin (81%) lati 2015, bẹẹ lo ni o ti le ni agbesunmọmi ẹgbẹrun mẹtala (13,000) ti won ti piwada lọdun yii.
"O le ni agbebọn 124,000 to ti ronupiwada lati 2023"
Gẹgẹ bi Tinubu ṣe wi, o ni anfaani wa fawọn agbebọn to ba ṣi fẹẹ ronupiwada lati ṣe bẹẹ, nitori o le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan ati mẹrinlelogun ninu wọn to ti yiwa pada bayii lati 2023.
- Ẹyin bandiiti, ajinigbe atẹyin tẹ n ran wọn lọwọ, ẹ jawọ tabi kẹ ẹ kan ijọgbọn lọwọ Naijiria:
Aarẹ kilọ yii fawọn agbesunmọmi, pẹlu alaye pe anfaani ayipada ko ni I lọ titi lae.
O ni ko ni I si aanu fawọn to n fi ẹjẹ ọmọ Naijiria wẹ.
Tinubu ko ṣai ranti ifarajin Oloogbe MKO Abiola ati iyawo rẹ, Oloogbe Kudirat Abiola.
O ranti agba lọọya, Oloogbe Gani Fawehinmi, Olooogbe Bola Ige,Baba Alfred Rewane, Alagba Abraham Adesanya, Oloye Anthony Enahoro, Alhaji Balarabe Musa, Commodore Dan Suleiman, Dokita Beko Ransome-Kuti, Frank Kokori, Arthur Nwankwo, Chima Ubani, Shehu Musa Yar'Adua ati ọpọ akọni Naijiria ti wọn ṣiṣẹ manigbagbe fun ominira ta a n jẹ ọrọ̀ rẹ lonii.
- Atunto lati 2023
Awọn ilana atunto to gunle lati 2023 to ti gbajọba ni Tinubu sọ pe o ti gbe ọrọ aje Naijiria dide, ti ọgbọn inu si n tẹsiwaju fun aṣeyọri.
- Ominira awọn ijọba ibilẹ 774
Tinubu sọ pe Demokresi ko kun to bawọn eeyan ko ba ri anfaani rẹ, eyi lo ni oun ṣe wa fun awọn ijọba ibilẹ 774 lominira ati da duro labala owo ti wọn yoo fi ṣejọba wọn.
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu kede ami ẹyẹ fawọn ọmọ Naijiria kan ti wọn ti foju wina iya ki Demokresi waye, awọn kan nilẹ yii atawọn ti wọn lọ sile okeere lọ ṣe atipo nigba ti nnkan ko fararọ.
Awọn ti Aarẹ Tinubu fun ni ami ẹyẹ orilẹede yii ni:
Barrister Ayoka Lawani
Tunde Fagbenle
Oladele Alake
Olatunji Bello
Louis Odion
Segun Babatope
Sam Omatseye
Sir Ademola Osinubi
Bola Bolawole
Lade Bonuola
Femi Kusa
Debo Adeniran
Chief Ayo Opadokun
Chief Ralph Obiora
Ose Osayande
Awọn mi-in ni
Barrister Osa Director
Prof. Sylvester Odion-Akhaine
Dr Arthur Nwankwo (O ti ku)
Dr Osagie Obayuwana
Dr Joe Okei-Odumakin
Barrister Titus Mann
Joe Igbokwe
Richard Akinnola
Ben Charles-Obi (o ti ku)
George Mbah
Dr Niran Malaolu
Major-General Ishola Williams (rtd)
Femi Aborisade
Jenkins Alumona
Gbemiga Ogunleye
Muyiwa Adekeye
Babajide Kolade-Otitoju
Ike Okonta
Bakan naa lo fun awọn ṣọja to ja fun June 12 lami ẹyẹ, lara wọn ni:
Major General MA Garba
Brigadier General Lawal Jaafaru Isa
Col Umar Farouk Ahmed;
Col Sambo Dasuki;
Col Lawan Gwadabe;
Brigadier Jonathan Ndam Temlong
Col Musa Shehu;
Major General Chris Eze;
Major General Harris Dzarma;
Col Isa Jibrin;
Maj. General Joseph Oshanupin;
Col Olusegun Oloruntoba, Olugbede of Gbede Kingdom)
Lieutenant Colonel Happy Kefas Bulus
Col J Okai;
Col Emmanuel Ndubueze;
Lt Col Yakubu Muazu ati
Brigadier Yahaya Abubakar to jẹ Etsu Nupe lọwọlọwọ,to si ti gba oye CFR tẹlẹ.
Oloogbe Sheu Musa Yar'Adua ni Tinubu kede pe oun ti fi orukọ rẹ sọ ile ẹkọ Institute of Petroleum Studies, Kaduna.
O ni General Shehu Musa Yar'Adua University of Geological Sciences and Engineering Technology ni yoo maa jẹ bayii.