You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Àwọn ọlọ́pàá tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣèwọ́de l'Abuja lórí owó ìfẹ̀yìntì sísan, gbégi dínà ilé-iṣẹ́ Ààrẹ
Oniruuru iwe ilewọ ni wọn mu dani to fi mọ asia orilẹede Naijiria ati asia ileeṣẹ ọlọpaa.
Irọ́ ni pé a ti dá ẹ̀yáwó tí à ń ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dúró - NELFUND
Loju opo X ajọ NELFUND lo ti kede lọjọ Abamẹta to kọja, pe oun ko figba kankan gbe e jade pe oun dawọ ẹyawo duro na.
Fídíò, Àkọsílẹ̀ DNA ṣàwárí àwọn ọmọ tí bàbá wọn ti sọnù fún ọ̀pọ̀ ọdún, Duration 2,00
Lara irufẹ ọmọ naa ni Cathy ti baba rẹ jẹ ọkan lara awọn ọmọ ogun ilẹ Gẹẹsi to lọ kẹkọọ ni Kenya lọpọ ọdun sẹyin.
A ti yanjú aáwọ̀ láàárín Makinde àti Olubadan-Ìgbìmọ̀ ọmọ Ibadan
Atẹjade ni CCII fi sita lo kede eyi, Aarẹ wọn, Amofin Sulaimon Ajeniyi Ajewole si buwọ lu u.
Ẹ fura o! Ayédèrú ọṣẹ ìfọyín Colgate tó lé ṣàkóbá fún ara ti wà lórí igbá káàkiri - NAFDAC
Ajọ NAFDAC ni oṣiṣẹ awọn meji lo ṣabẹwo si ibi ti wọn ti n ta ayederu Colgate naa nibi ti wọn ti fi idi rẹ mulẹ pe otitọ ni ọrọ naa.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,59
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Fídíò, Wọ́n kó Rasheed mérò níbi ìwọ́de EndSARS lọ́dún 2020, ọdún mẹ́fà ló lò lẹ́wọ̀n, Duration 3,51
Olugbe ilu Ibadan ni Rasheed, ilu Ibadan loun pẹlu si ti darapọ awọn oluwọde yii ko to bọ si gbaga awọn agbofinro, latibẹ lo gba de ọgba ẹwọn nibi to ti lo ọdun mẹfa aye rẹ.
Alaafin ní kí Aare Onakakanfo gbé ìgbésẹ̀ lórí ètò àbò ilẹ̀ Yoruba, kí ni òfin sọ?
A gbọ pe Aba Asa, to wa lagbegbe Omi Adio, niluu Ibadan ni wọn ti gbẹmi oloye ọhun to jẹ agbẹ.
Ìdí rèé tí a fi ń ra màálù kan ní ₦2.5m báyìí, àwọn alápatà sàlàyé
Alaga awọn alapata nipinlẹ Eko ṣalaye siwaju sii pe ''ọkọ ayọkẹlẹ mi ti mo ra ni N2.1m lọdun 2020 ko to owo ti a fi n ra maalu kan mọ bayii.
Ṣé lóòótọ́ ni pé ìdìbó 2027 tó ń bọ̀ ló jẹ́ kí ètò ààbò mẹ́hẹ ní Naijiria? Ohun tí a mọ̀ rèé
Nigba to n ṣalaye ajọṣepọ to wa laaarin eto aabo ati idibo, Ọmọwe Kabiru Adamu, oludasilẹ ileeṣẹ eto aabo Beacon Security sọ pe iwadii ti fi han pe ajọṣepọ wa laaarin aabo ati idibo loootọ.
Wíwẹ̀ ní àárọ̀ tàbí alẹ́: Èwo ló dára jùlọ?
Fún ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, ohun tí wọ́n máa ń kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá jí ni láti bọ́ sí balùwẹ̀, kí wọ́n ṣá kànìnkànìn.
Amẹ́ríkà àti Iran ní ìjíròrò ń so èso rere àmọ́ kò tíì sí ìfẹnukò
Trump sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta pé Iran ń ṣe bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láti bíi ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta sẹ́yìn.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ìdẹ̀rùn dé báwọn òṣìṣẹ́ l‘Ogun, wọn yóò gba ìsinmi ọjọ́ kan láàrín ọ̀sẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó ọkọ̀ lóṣù
Olori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun, Kehinde Onasanya, lo kede eyi l'Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlogun,oṣu Kẹrin ọdun 2026.
Obìnrin tí wọ́n ṣèèṣì san N100,000 sí àṣùwọ̀n rẹ̀ kọ̀ láti dáwó padà, àwọn èèyàn gbaná jẹ
Chukwuebuka ké gbàjarè pé èèyàn kan tó fẹ́ owó náà fún òun, tí òun sì ṣèèṣì tẹ nọ́mbà Opay ẹlòmíràn sí orí fóònù tó sì lọ bọ́ sí akoto owó obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Opeyemi Faridat Awodoyin.
Àṣírí tú lórí bí ọwọ́ ọlọ́páà ṣe tẹ afurasí 33 tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì CAC Oke Isegun, Eruku ní Kwara
Olusọ agutan Taye Rotimi to jẹ igbakeji pasitọ ijọ naa sọ fun BBC pe oun n fẹ ki awọn agbesunmọmi naa foju wina ofin ijọba.
"Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tí ẹ̀ ń kún pé bí Toun Soetan ṣe ń kọrin ń di yín lọ́wọ́ láti dárà nínú ìjọ, ó ti lọ, ẹ wá dárà yín ká rí i"
Ọpọlọpọ olorin ẹmi bii Bola Aarẹ, Funmi Aragbaye, Philip Adika atawọn mi-in si lo peju pesẹ sibi isinku gbajumọ akọrin ẹmi, Toun Soetan l‘Ọjọbọ.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́fà tó fẹ́ ju àdó olóró sí dúkìá ìjọba l'Ondo
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal, lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n ba awọn akoroyin sọrọ lonii Ọjọbọ, ọjọ kerindinlogun osu Kẹrin ọdun 2026.
Ìgbà ìkẹyìn tí máà díje fún ipò ààrẹ rèé, tí ń kò bá borí ìbò abẹ́nú, máa ṣe àtìlẹyìn fún ẹni tí ADC bá fà kalẹ̀ láti díje ipò ààrẹ - Atiku
Níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ni Atiku Abubakar ti sọ pé tí òun kò bá borí ipo ààrẹ níbi ètò ìdìbò ọdún 2027, òun kò ní dupò kankan mọ́.
Ipa wo ni àìsí aṣojú INEC níbi ìpàdé àpérò ADC yóò ní lórí ẹgbẹ́ òṣèlú náà?
Níbi ìpàdé náà ni wọ́n ti tún fọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà kan tó fi mọ́ Nafiu Bala Gombe, ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ náà tẹ́lẹ̀ rí, tó sì ń pe ìyànsípò David Mark gẹ́gẹ́ bí alága tuntun níjà nílé ẹjọ́ gíga.
Ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀ (Lassa Fever) wọ ìpínlẹ̀ Oyo, wo ọ̀nà márùn-ún láti dènà rẹ̀
Bí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ṣe kéde pé àrùn Ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀ (Lassa Fever) ti wọ ìpínlẹ̀ náà, BBC News Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ ọ̀nà márùn-ún láti dènà àrùn náà.
Ogun Abẹ́lé Sudan: Akọ̀ròyìn tó há sínú ogun fún ọdún mẹ́ta sọ ohun tójú rẹ̀ rí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Sudan ni wọ́n ti fọ́nká káàkiri báyìí, àwọn míì ti sá lọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn lójúnà àti bọ́ lọ́wọ́ ìpèníjà tó ń bá gbogbo ayé fínra.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìjọba ṣe yọ ẹ̀sùn fifi owó ṣèrànwọ́ fún ìgbẹ́sùnmọ̀mí kúrò nínú ẹjọ́ ti Malami ń jẹ́
Tẹ o ba gbagbe, Malami ati ọmọ rẹ; Abdul Aziz ni wọn jọ n jẹjọ to ni i ṣe pẹlu nini nnkan ija ogun lọwọ lọna aitọ, ati ti pe wọn n ran awọn agbesunmọmi lọwọ.
Kí ni Cute Abiola ṣe, tí omíjé fi ń dà lójú rẹ̀ àmọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ si?
Iṣẹ abẹ ni iyawo Cute Abiola torukọ rẹ n jẹ Khudrah Mosunmola fi mọ, ko si too di pe wọn gbe e wọ yara iṣẹ abẹ naa ni oun ati ọkọ rẹ ti bẹrẹ fidio to n ṣafihan bi igbesẹ oyun naa ṣe n lọ han.
A gbàgbọ́ pé àlàáfíà yóò jọba ní Cameroon lẹ́yìn àbẹ̀wò Pope Leo XIV- Aráàlú
Awọn olori ẹsin ati araalu rẹpẹtẹ to ti n duro de Papa naa ni wọn fi tilu-tifọn ki I kaabọ.
Ìròyìn Pàtàkì
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
'Òkú mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni mo kà láàárín ìlú, ọ̀pọ̀ ló fọ́nká sínú igbó'
Bí àdó ikú látọ̀dọ̀ àwọn ológun Nàíjíríà tún ṣe balẹ̀ sórí aráàlu ní ọjà kan tó wà láàrin ààlà ilẹ̀ ìpínlẹ̀ Borno àti Yobe, BBC News Yoruba se akojọpọ awọn akoko mẹfa ti baalu ologun ti seesi kọlu araalu.
Amẹ́ríkà gbégi dínà Strait of Hormuz láti dí Iran lọ́wọ́ gbígbé epo gba ibẹ̀, China figbe ta pé ewu ń bẹ̀, bí owó epo ṣe wọ́n sí ní àgbáyé
Ijọba ilẹ Iran daba wiwọgile ipese Uranium fun ọdun marun un lati fopin si ogun to lọ lọwọ naa.
Àwọn ọmọ Iran kọminú lórí bóyá ogun Amẹ́ríkà lè tẹ̀síwájú tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ lẹ́yìn tí ìpàdé àláfíà forí ṣánpọ́n
Ibaṣepọ ti ko dan mọran to wa laarin Iran ati Amẹrika tunbọ buru siwaju si lẹyin ti ipade alaafia laarin orilẹede mejeji to waye ni Pakistan lulẹ.
Lẹ́yìn ìwọ́de tako ìjínigbé, Aiyedatiwa ṣàbẹ̀wò sáwọn agbègbè tí ààbò ti mẹ́hẹ, ó ní ajínigbé 100 tó ń ṣọṣẹ́ l‘Ondo ní ọwọ́ ti bà
Gomina sọ awọn ọrọ yii lasiko abẹwo ibanikẹdun to ṣe si Aafin Olumafon tilu Imafon, Oba Samuel Adegbehingbe Aliu lọjọ Isẹgun.
Àbọ̀ ìwádìí BBC lórí ikú ìyàwó Wòlíì olùdásílẹ̀ ìjọ tó ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn ní kàyééfì
Lẹyin ọdun mẹwaa ti Charmain ti ku, iwadii BBC fi kudiẹkudiẹ han ninu ọrọ ti Adusah, ọkọ rẹ̀ sọ.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ààrẹ Trump àti Pope Leo XIV ṣe ń tahùn síra wọn
Poopu sọ fawọn akọroyin nigba to n lọ si orilẹede Algeria wi pe oun ko ni ṣe arohun-bọhun pẹlu Trump, amọ, oun ko ni dakẹ lati maa sọrọ tako ogun.
Ìdí rèé tí Iyabo Obasanjo ṣe gba kámú bí gbogbo ẹgbẹ́ APC l‘Ogun ṣe fa Yayi kalẹ̀ bíi olùdíje gómìnà
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Abiodun fa Yayi kalẹ, lasiko ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun.
Ọkọ̀ tó kó àwọn agbábọ́ọ̀lù pàdé àwọn adigunjalè lọ́nà, wọ́n yìnbọn pa agbábọ́ọ̀lù kan
Ikọ agbabọọlu Berkum Chelsea ti Dominic wa lo ko awọn adigunjale lọna lọjọ Aiku ọsẹ yii.
Ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá afurasí mẹ́tàlá tó ń ṣagbátẹrù ìgbésùnmọ̀mí
Igbesẹ yii gẹgẹ bi ajọ SEC ṣe ṣalaye da lori ofin ọdun 2022 to tako igbesunmọmi eyi to sọ pe ijọba gbọdọ gbẹsẹ le owo, dukia ati nnkan ọrọ aje ẹnikẹni to ba n ṣagbatẹru fun igbesunmọmi lai sọ fun wọn tẹlẹ.
Àwọn ìdí rèé tí gómìnà kan fi le yọ ọba nípò lábẹ́ òfin
BBC News Yorùbá kàn sí onímọ̀ nípa òfin láti mọ̀ nípa ohun tó le ṣokùnfà kí ìjọba fi àṣẹ gba adé lórí ọba àti ìlẹ̀kẹ̀ lọ́rùn rẹ̀.