You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aráàlú fárígá, àwọn olùwọ́de já géètì sẹkitéríàtì ìjọba, ìpè fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso káàkiri Nàìjíríà
Awọn oluwọde to n pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso ti ja geeti olu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to wa l'Abeokuta wọle.
Awọn eeyan naa ti wọn ko ara wọn lati fi aidunnu wọn han si bawọn eeyan naa ṣe wa ni akata awọn ajinigbe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ti kọja, bẹnu ẹtẹ lu bi ijọba ko ṣe tii ri wọn doola.
Titi pa ni geeti olu ileeṣẹ ijọba naa nigba ti wọn de ibẹ, eyi lo si jẹ ki wọn fi ipa ṣi geeti naa wọle lati le fi aidunnu wọn han si ijọba.
Ọpọ eeyan lo ti pin fidio ifẹhonuhan naa kaakiri ori itakun ayelujara.
Ni ipinlẹ Osun, ẹgbẹ awọn olukọ ẹka ti ipinlẹ naa dara pọ mọ iwọde to n lọ lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa ni akata awọn ajinigbe.
Ifẹhonuhan naa lo waye ni ilu Osogbo to si gbera sọ ni deede agogo mẹwaa ku iṣẹju mẹsan an.
Iwọde naa bẹrẹ lati agbegbe Ataoja ti wọn si gbe e wọ inu ọfiisi ijọba ni Abere.
Pẹlu oju kikoro ati omije loju ni awọn olukọ naa fi ṣe iwọde naa ti orin aro si n jade lẹnu wọn bi wọn ṣe n ṣe iwọde naa lọ.
Awọn oluwọde naa kepe ijọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati ijọba gomina Ademola Adeleke lati pasẹ aabo to peye fun olukọ ati akẹkọ paapa fun gbogbo ara ilu.
''Bi ko ba si aabo fun wa, a ti ṣe tan lati bẹrẹ iyanselodi.
A fun ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ meje pere lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni akata awọn ajinigbe ni ipinlẹ Ọyọ silẹ.''
''Iyanṣẹlodi wa yoo tẹwsiwaju ti ijọba ko ba doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa lakata ajinigbe''
Babatunde Babalola, ẹni to jẹ alaga fun ẹgbẹ awọn olukọ ẹka ti ipinlẹ Osun, ti bu ẹnu atẹ lu bi ko ṣe si eto aabo to peye ni orile-ede Naijiria lọwọlọwọ bayii ati bi ipaniyan ati ijinigbe ṣe di lemọ lẹmọ.
Alaga naa wa sọ eyi daju pe, bi ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ba wa ọna abayọ lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ ti awọn ajinigbe ko lọ ni Ogbomoso si lọ, awọn ṣe tan lati bẹrẹ iyanselodi.
Alaga naa wa rọ gbogbo awọn olukọ ati akẹkọọ ki wọn wa ni oju ni alakan fi sọri ni gbogbo igba ati wi pe, ki onikaluku maa dira ogun ni gbogbo igba.
Muritala Jimoh, ẹni to jẹ akọwe fun ile-iṣẹ to ri si eto ẹkọ ni ipinlẹ Osun lo soju gomina Adeleke lati ba awọn olukọ ti wọn ṣe iwọde ifẹhonuhan lori eto aabo to mẹhẹ sọrọ.
Ninu ọrọ to ba awọn olukọ naa sọ lo ti sọ pe, gbogbo awọn ẹsọ alaabo to wa ní ipinlẹ Osun ni gomina Adeleke ti ba ṣe ipade lori bi aabo yoo ṣe wa fun gbogbo olugbe ipinlẹ Osun paapaa julọ awọn olukọ ati akẹkọ.
Ẹgbẹ olukọ Ipinlẹ Ọyọ pẹlu ifowosowopo naa ṣe bẹrẹ iwọde tako ijinigbe àwọn akẹkọọ àti olùkọ ti awọn ajinigbe jigbe ni ilu Ogbomoso.
Ẹgbẹ olùkọ ẹka Ipinlẹ Ondo darapọ mọ àwọn ojugba wọn lati se iwọde tako ijinigbe àwọn akẹkọọ àti olùkọ ni Esinele ati Yawọta l'Ogbomoso.
Ẹgbẹ olùkọ Ipinlẹ Kwara naa bẹrẹ iwọde tako ijinigbe àwọn akẹkọọ àti olùkọ Yawọta ni Ogbomọshọ