You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí tí ilé ẹjọ́ fi ní ₦110bn tílé aṣòfin àpapọ̀ fi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, pín fún àjẹmọ́nú wọn, lòdì sófin
Ile ẹjọ giga kan niluu Eko ti gbe idajọ kalẹ pe ₦110b ti ile igbimọ aṣofin agba na lati ra ọkọ ayọkẹlẹ atawọn ajẹmọnu mii fun ara wọn ko ba ofin mu.
Idajọ naa lo waye niwaju adajọ Yellim Bogoro lẹyin ti ajọ ajafẹtọọmọniyan, SERAP pe ẹjọ lori pe ko ba ofin mu bi awọn aṣofin ṣe na owo naa.
Igbẹjọ yii ti tunbọ tun aṣiri bi awọn aṣofin Naijiria ṣe maa n bu owo fun ara wọn ti wọn a si maa fi owo ilu ṣe ara wọn loore ti araalu ko si ni mọ.
Ki ni wọn na ₦110b yii le lori?
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn ya ogoji biliọnu naira sọtọ lati ra ọkọ ayọkẹlẹ fun aṣofin ti iye wọn to 465.
Wọn si ya ₦70b mii sọtọ gẹgẹ bii owo ajẹmọnu fun awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lẹyin eto idibo ọdun 2023.
Owo ti wọn naa fun ara wọn yii lo bi ọpọ araalu ninu paapaa lẹyin ti wọn na owo ọhun lasiko ti ọwọngogo gbode lẹyin eto idibo ọdun 2023 ti ilu le koko.
Ki ni eredi ti SERAP fi gba ile ẹjọ lọ?
Nigba ti SERAP dele ẹjọ, lara ohun ti wọn sọ ni pe owo ti wọn na ọhun tako ofin to rọ mọ bi ijọba ṣe n ra nnkan, iyẹn "Public Procurement Act 2007."
Ajọ naa tun sọ pe o jẹ aṣilo ipo fun awọn aṣofin naa, eyii ti wọn pe ni riru ofin "Code of Conduct for Public Officers."
SERAP tun fidi rẹ mulẹ niwaju adajọ pe awọn aṣofin naa tapa si ẹjẹ ti wọn jẹ fun araalu lati sin ilu, amọ kaka ki wọn sin araalu, ara wọn ni wọn lọ sin nile aṣofin.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, niṣe lawọn aṣofin ọhun kan n bu owo ati ajẹmọnu fun ara wọn lai bikita fun ofin to de ṣiṣe bẹẹ.
O wa rọ ile ẹjọ ko sọ boya owo ti wọn na ọhun yẹ labẹ ofin Naijiria tabi bẹẹ kọ.
Idajọ ile ẹjọ ni ko yẹ ki awọn asofin maa sin ara wọn nikan lẹyin ti wọn ti bura pe araalu lawọn fẹ lọ sin
Adajọ Bogoro fidi rẹ mulẹ pe owo ti wọn na ọhun ko ba ofin mu gẹgẹ bii SERAP ṣe jiyan niwaju oun.
Ile ẹjọ ọhun tun fidi rẹ mulẹ pe, awọn olujẹjọ ko tẹle ilana to yẹ ki wọn tẹle ki wọn to gbe owo ọhun sita.
Adajọ sọ pe ko ba ofin mu bi wọn ṣe gbe owo naa jade ati pe awọn aṣofin ọhun ṣe bẹẹ fun anfani ara wọn nikan.
Lẹyin naa lo ni ko yẹ ki wọn maa sin ara wọn nikan lẹyin ti wọn ti bura pe araalu lawọn fẹ lọ sin.
Lara anfaani ti idajọ yii yoo ṣe fun araalu ni pe awọn ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan le lo idajọ naa, lati ka ọwọ awọn aṣofin ko, ti wọn ba fẹ ṣe irufẹ nnkan bẹẹ lọjọ iwaju
Bo tilẹ jẹ pe idajọ ile ẹjọ ti sọ pe gbigbe owo naa jade ko ba ofin mu ati pe awọn aṣofin gbọdọ maa tẹle ofin ki wọn to ṣe ohunkohun, ile ẹjọ naa ko paṣẹ ki wọn da owo ọhun pada.
Ṣugbọn lara anfaani ti idajọ yii yoo ṣe fun araalu ni pe awọn ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan le lo idajọ naa, lati ka ọwọ awọn aṣofin ko, ti wọn ba fẹ ṣe irufẹ nnkan bẹẹ lọjọ iwaju.
Wayii o, awọn aṣofin naa lẹtọ labẹ ofin lati pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ọhun.
Ẹwẹ, awọn araalu kan ti n sọ pe Eledua nikan lo mọ oniruru owo bẹẹ ti awọn aṣofin Naijiria n na fun anfani ara wọn nikan lai bun ọmọ Naijiria gbọ.