Ìdí mẹ́rin tí nǹkan ọkùnrin ṣe máa ń nàró ní àárọ̀ tí wọn bá jí

Ìdí mẹ́rin tí nǹkan ọkùnrin ṣe máa ń nàró ní àárọ̀ tí wọn bá jí
Published

Nnkan asiri to wa lara an ọkunrin se pataki pupọ nitori ohun ni orisun ọmọ bibi to ba dapọ mọ obinrin.

Amọ ni araarọ ti wn ba ji, nnkan asiri awn ọkunrin yii yoo naro soke, ti yoo si duro tiiri eyi to maa n ya ọpọ eeyan lẹnu.

Koda, ọpọ awọn ọkunrin ati obinrin lo ti maa n beere ninu ara wn pe ki lo n fa a ti nnkan awọn ọkunrin yii se maa n duro wnnle ni owurọ ti wọn ba ji'

Ọna lati wa idahun si ibeere to jẹ ọpọ eeyan logun yii, lo mu ki BBC News Yoruba se iwadii nipa ohun mẹrin to n mu ki nǹkan ọkùnrin máa nàró ní àárọ̀ tí wọn bá jí.

Ohun mẹrin to fa a ti nnkan ọkunrin se maa n duro tiiri ni owurọ

Ohun akọkọ to maa n fa ki nnkan ọkunrin duro tiiri lasiko ti oorun ọkunrin naa ba n dun mọ lọwọ idaji.

Agọ ara ọkunrin maa n dari ẹjẹ pupọ sidi nnkan ọkunrin lasiko oorun asunde gongo yii.

Idi keji ni pe o seese ki hoomu ọkunrin gberasọ lwọ deere eyi to maa n mu ki nnkan ọkunrin le, ko si duro gbọọrọ.

Idi kẹta ni pe ati ọmọde, ati agba ọkunrin to ba n jẹ ounjẹ asaraloore daadaa, ti ko se aarẹ, ti omi ati ẹjẹ ara rẹ si n rin yika ara rẹ, o ni odiwọn ẹjẹ to yẹ ko lọ sidi isan nnkan ọmọkunrin rẹ nigba to ba sun lalẹ.

Eyi yoo si jẹ ki nnkan ọkunrin rẹ dide ni kete to ba ji ni owurọ.

Idi kẹrin ni pe ti itọ ba n gbọn ọkunrin, to si n pa itọ naa mọra, ti apo itọ rẹ si ti kun, o seese ki ara maa rin iru ọkunrin bẹẹ.

Idi si ree ti nnkan ọkunrin rẹ yoo fi duro, ko to tọ ni owurọ.

Amọ ti o ba jẹ ọkunrin, ti o ko ni iru iriri ki nnkan ọkunrin rẹ maa duro wanle ni owurọ, tete yara kan sawọn dokita akọsẹmọsẹ onisegun, aibaamọ nnkan ti se ọ.

BBC News Yoruba wa n gba ẹyin ọkunrin nimọran lati maa sọra se nipa ibi ti ẹ n fi nnkan ọkunrin yin bọ, ko ba le ni ilera to peye.