You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
DSS lọgun pé àgbébọn fẹ́ kọlu iléẹ̀kọ́ l‘Edo, ìjọba ti iléẹ̀kọ́ mẹ́ta pa
Ijinigbe to n gbilẹ si i lorilẹede Naijiria ko yọ ipinlẹ kankan silẹ, ti ipinlẹ Edo lo si jọ pe o tun fẹ ṣẹlẹ bayii, bi ko ṣe pe awo ọrọ naa ya.
Iwe kan lo lu sita lori ayelujara lojiji, eyi ti ikọ alaabo DSS fi sin ileeṣẹ NSCDC ti a mọ si aabo ara ẹni ni aabo ilu ni gberẹ ipakọ, pe awọn afurasi n mura lati kọlu awọn ile ẹkọ l'Edo.
Iwe aṣiri ni DSS fi ranṣẹ si NSCDC, ninu rẹ ni wọn ti ṣalaye fun wọn pe iwadii ọtẹlẹmuyẹ fi ọrọ ti ikọ ajinigbe meji ba ara wọn sọ lati kọlu awọn ile ẹkọ nipinlẹ Edo han.
Ṣugbọn iwe naa pada lu sori ayelujara.
Ohun tawọn ajinigbe bara wọn sọ
Ninu iwe ikilọ ti DSS fi ranṣẹ si NSCDC Edo, eyi to ti ṣeṣi bọ si ori ayelujara bayii ni wọn kọ 'secret'', iyẹn aṣiri si.
Wọn ṣalaye sibẹ pe awọn afurasi agbesunmọmi meji kan, Bawa ati Nuhu, ba ara wọn sọrọ nipa ikọlu ti wọn fẹ ṣe sawọn ile ẹkọ nipinlẹ Edo.
Ijọba ibilẹ Ariwa Edo ni DSS sọ pe awọn ikọ naa ṣọ pe awọn fẹ kọlu.
Ọjọ karun-un oṣu Kẹfa yii ni DSS fiwe naa ransẹ, o si nọmba S66/A/3972 lara.
DSS ṣalaye pe awọn ajinigbe naa sọ ninu ọrọ wọn, pe bawọn ba ji awọn agbalagba gbe, ki i yọ owo bii tawọn ọmọ ile ẹkọ.
Ati pe ti ijinigbe tawon ọmọde maa n ka ijọba atawọn tọrọ kan lara ju tawọn agba lọ.
Fun idi eyi, DSS kilọ fawọn ẹṣọ lati gbe igbesẹ, wọn ni kawọn ile ẹkọ naa si ṣe ohun to yẹ, ki erongba awọn ajinigbe maa ba wa si imuṣẹ.
Bawo ni iwe DSS ṣe lu sita?
Lẹyin ti iwe aṣiri naa de ori ayelujara, ikọ DSS fidi ẹ mulẹ pe ki i ṣe agbelẹrọ iwe, wọn ni ojulowo ni.
DSS sọ pe ikilọ lasan to yẹ kawọn ẹka tọrọ kan ṣiṣẹ lori rẹ lawọn ṣe fawọn ileeṣẹ alaabo tawọn fi iwe naa ranṣẹ si.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe niṣe ni NSCDC Edo jẹ ko lu jade ni tiwọn.
Wọn fi kun un pe iru awọn iwe aṣiri bẹẹ ko yẹ lati lu jade, nitori o le ṣakoba fun aṣeyọri.
Ijọba ipinlẹ Edo ti ile ẹkọ mẹta pa
Bi iwe aṣiri ijinigbe naa ṣe ti di ohun ti aye ri, ọpọ eeyan lo tun ti n ko aya soke, paapaa nipinlẹ Edo.
Lati dena ijinigbe naa ko ma baa waye, ijọba ipinlẹ Edo paṣẹ ki wọn ti awọn ile ẹkọ girama mẹta kan pa nijọba ibilẹ Akoko-Edo.
Aṣẹ ile ẹkọ titipa naa wa ninu atẹjade ti ọga agba fun ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ l'Edo, Enodolomwanyi Otamere, kọ lọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa yii.
Ṣugbọn ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe awọn ajinigbe tilẹ le ma ṣe ikọlu si apa ibi ti aṣiri rẹ ti tu yii mọ.
Wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ apa ibomiran ni wọn yoo ti ṣọṣẹ nigba ti ẹnikẹni ko le sọ.
Ṣe ọrọ ti Gomina Monday Okpebholo sọ pe kawọn ajinigbe maa tẹsiwaju, amọ ko si aaye ni Aso Rock lo fa a ti ajinigbe ṣe fẹ wa s'Edo?
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni Gomina ipinlẹ Edo,Monday Okpebholo sọ awọn ọrọ kan ti ọpọ eeyan n tori ẹ koro oju, ti wọn si n sọ pe gomina naa ko sọrọ ire lẹnu.
Nibi eto ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo waye ni Gomina Okpebholo ti sọ lọjọ Iṣẹgun pe:
"Ko si aaye ni Aso Rock." Wọn tiẹ le ji gbogbo wa gbe, bẹẹ ni, ko si aaye ni Aso Rock."
"Iṣẹ ọwọ awọn alatako ni ohun to n ṣẹlẹ yii, wọn si ti kuna. "Abi wọn ko lulẹ ni?
"Ṣe jiji awọn ọmọde gbe ni wọn fi n ṣe e ni?
Ta lo wa ku ti wọn fẹ ṣe ilu le lori?
"Ko ni i sẹni kankan ti wọn yoo dari rẹ. Fun idi eyi, ki wọn fun wa ni alaafia ka le ṣelu daadaa."
Bẹẹ ni Gomina Okpebholo wi. O fi kun un pe Aarẹ Tinubu ti ṣe daadaa ju awọn to ṣiwaju rẹ lọ.
Ọrọ rẹ yii ni ọpọ eeyan ti n tori rẹ bu ẹnu atẹ lu u, wọn ni idibo ọdun 2027 lo ka a lara ju aisi ifọkanbalẹ to n daamu ipinlẹ rẹ lọ.
Awọn ajinigbe ti ṣọṣẹ l'Edo tẹlẹ
Ẹ o ranti pe ipinlẹ Edo naa wa lara awọn ilu tawọn agbesunmọmi ti fọwọ ba ri, ti wọn ko si ti i duro.
Loṣu Keji ọdun 2026, eeyan 87 ni ọlọpaa ko nipinlẹ Edo, fun ẹsun jijẹ afurasi ajinigbe, wọn si gba eeyan ọgbọn (30) ti wọn ji gbe lọwọ wọn.
Oṣu Kẹrin 2026: Awọn agbebọn kọlu ọkọ akẹro loju ọna Eko si Benin, wọn pa awakọ, wọn si ko awọn ero ọkọ lọ.
Loṣu Karun-un, ileeṣẹ ọlọpaa Edo kede pe awọn ti mu afurasi ajinige marundinlọgọta (55), awọn si gba eeyan mejidinlọgọta (58) kalẹ.