Oriyomi Hamzat ṣàlàyé àjọsẹpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Sheikh Gumi, ìgbésùnmọ̀mí àti akatakítí ẹ̀sìn

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi ẹnikan ba wa ti ọpọ ọmọ Naijiria gbagbọ pe o n da nnkan pọ pẹlu awọn agbesunmọmi ati ajinigbe, Sheikh ilu Kaduna nni, Ahmad Gumi, ni.

Titi di asiko yii ni ẹnu ṣi n kun Aafaa naa, bo tilẹ jẹ pe Gumi ko yee sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa awọn agbebọn ju pe oun ko fẹ kijọba fi agidi ba won lo lọ.

Ijọba ilẹ Saudi Arabia paapaa le Gumi pada lasiko to fẹ ṣiṣẹ Hajj lọdun to kọja, lori ọrọ dida nnkan pọ pẹlu awon agbesunmọmi yii naa ni.

Bi eeyan ba wa n ṣe ọrẹ ẹni ti ọpọ araalu ko yọnu si, oju iru ẹni naa ni wọn yoo fi maa wo ẹni ti wọn ba ri pẹlu rẹ

Eyi ni ohun to n ṣẹlẹ si gbajumọ sọrọsọrọ to fẹ dupo gomina ipinlẹ Oyo ni 2027, Alhaji Oriyomi Hamzat bayii.

Ẹni ti ẹnu ti n kun tipẹ pe ọrẹ Sheihk Gumi ni, ati pe iwajọwa lo n jẹ ọrẹjọrẹ ni ọrọ awọn mejeeji.

Ki lo da Oriyomi ati Gumi pọ?

Loootọ lo ti pẹ ti ẹnu ti maa n kun Oriyomi Hamzat pẹlu iwa ati iṣe rẹ, paapaa julọ nipa jijẹ alakatakiti ẹsin Islam.

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe bi Gumi ṣe jẹ alakatakiti ẹsin Islam ni Oriyomi naa jẹ bẹẹ pẹlu.

Afiwe ti wọn maa n ṣe fun eyi ni pe Gumi wa sibi eto kan ni yunifasiti ilu Ibadan, Oriyomi Hamzat naa si wa nibẹ pẹlu bi wọn ṣe maa n fi ẹsun naa kan an.

Awọn kan tilẹ sọ pe Oriyomi lo pe Gumi wa, ati pe nitori rẹ ni wọn ṣe jọ jokoo ti ara wọn nibi eto naa.

Ṣaaju lo ti jẹ pe Oriyomi ko tako eyi, fidio kan si wa ti sọrọsọrọ ori redio naa ti n sọ pe Gumi ki I ṣe ọdaran, nitori ijọba apapọ ko pe bẹẹ, wọn ko si sọ pe o ṣe awọn lẹṣẹ kankan.

Ṣugbọn ni lasiko yii ti Oriyomi n gbiyanju lati di gomina ipinlẹ Oyo lodun to n bọ, labẹ akọmọna rẹ ti I ṣe 'Oyo n pe ọ, ọpọ ẹnu ti bẹrẹ si I kun un ju ti tẹlẹ lọ lori ajọṣepọ rẹ pẹlu Gumi to wọ Ibadan wa ṣeto, ati lorii pe ọta Kristẹni, ọrẹ Gumi ni Oriyomi n ṣe.

Alaye Oriyomi

Lati fọ orukọ ara rẹ mọ, ati kawọn eeyan ma baa maa pe awọn ọmọ rẹ ni 'Bandiiti, ọmọ ọrẹ Gumi' ni Oriyomi ṣe fi fidio kan sita bayii, nibi to ti sọ ọpọ ọrọ lori ohun ti aye gbagbọ nipa rẹ.

"Mi o ri Gumi ri laye mi, emi kọ ni wọn ri nibi eto ti Gumi ṣe ni Yunifasiti Ibadan.

"Emi gan-an maa n ba wọn bu Gumi lọpọ igba ni, mo maa n beere pe ki lo de ti ijọba apapọ ko ṣe mu un.

"Emi kọ ni mo gbe Gumi wa si Yunifasiti Ibadan, emi si kọ ni wọn ri ninu fọto ti wọn ya nibẹ, ẹni yẹn de fila bii temi ni, emi kọ.

"Gumi gan-an kọ lo wa ninu fọto yẹn.

"Ọjọ ti Gumi wa si UI, emi o si nibẹ, ileeṣẹ wa lo wa nibẹ. "Bawo lawọn eeyan ṣe wa n sọ pe emi ni mo gbe e wa si Yunifasiti Ibadan.

"Ẹ ni kawon to ba n sọ pe mo mọ Gumi mu ẹri wa o, tori mi o ni I gba,mo maa gbe igbesẹ lori ọrọ yii.

"Wọn ni ki n ma dahun, ki n ma sọrọ, nitori awon ọmọ mi ni mo ṣe jade sọrọ yii, ki wọn le rin lawujọ. Ko ma di pe ti won ba da orukọ wọn ti won fi Oriyomi Hamzat si, won a wa maa pe won ni ọmọ ọrẹ Bandit."

Oriyomi sọ pe ṣe ijọba ipinlẹ ati yunifasiti Ibadan ti Gumi wa ko mọ pe o n bọ ni.

O ni Gumi to jẹ ọlọpaa ijọba lo ṣọ ọ de Ibadan, ti won ko bu u to jẹ oun ni wọn wa n fi ẹsun kan.

"Mi o ṣalaye ki ẹ ba le dibo fun mi o, mi o si ki n ṣe onisharia tabi alakatakiti ẹsin Islam"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Oriyomi Hamzat sọ pe oun ko ṣalaye ọrọ yii nitori ki araalu le dibo foun rara.

O ni ko si eeyan to le da oun duro bi asiko ba to.

Bakan naa ni Oriyomi ṣalaye lori jijẹ onisharia ati alakatakiti ẹsin Islam.

"Ṣe ti ṣokoto mi ti ẹ ni ko balẹ, designer ni, bi wọn ṣe ṣe e wa niyẹn.

"Ti mo ba wọ ṣokoto jinnsi tabi buba ati ṣọkoto, o maa n balẹ to tun maa n ka.Nigba ti ẹ si fi n bu mi ni mo ṣe lọ ra eyi ti ko balẹ yẹn jọ."

Sọrọsọrọ ori redio naa ṣalaye nipa bi Kristẹni ṣe pọ ninu awọn oṣiṣẹ rẹ, bo ṣe kọ ile ọmọ alailobii to jẹ pe ẹsin ti kaluku awon ọmọ naa n ṣe nibi ti wọn ti wa ni oun ṣi gba wọn laye ki wọn maa ṣe lọ.

Oriyomi so pe ọdun 2015 loun ti bẹrẹ si I ko awọn omo to n sun ita kiri Ibadan, toun da wọn pọ mo awọn ọmọ bibi inu oun.

O ni iku ọkan lara wọn ni 2017 lo kọkọ gbe oun de ẹwọn. oun ko si tori rẹ ṣiwọ bi aye ṣe daamu oun to.

Mejila ninu awon omo naa lo ni won ti wa ni yunifasiti kaakiri bayii, ti won n kọ ẹkọ ọlọkan o jọkan.

O ni oun n ran awon eeyan lọ si Mecca ati Jerusalem, aipe owo Jerusalem lọdun yii ni ko jẹ koun ran ẹni kan to fẹ lọ si Mecca lo bo ṣe sọ.

Pẹlu gbogbo eyi, Oriyomi sọ pe oun ko mọ idi ti won yoo fi maa pe oun ni alakatakiti, ọrẹ Gumi, ọta Kristẹni ati onisharia.

O loun mọ pe awon eeyan le maa sọ pe oun yoo ṣalaye titi (You go explain tire) amọ oun ko tori iru wọn sọrọ ẹnu oun.