You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú jànkàn tó lè má kópa nínú ètò ìdìbò ọdún 2027
O tun ti n rugbo bọ lagbo oṣelu Naijiria bayii lẹyin ti ajọ eleto idibo, INEC, sọ pe oun ko ni yẹ alakalẹ bi idibo gbogbogbo ọdun 2027 yoo ṣe waye.
Eyii ko ṣẹyin awọn oniruru ipẹjọ to n waye lẹyin alakalẹ INEC naa.
Rogbodiyan naa ko ṣẹyin boya ajọ INEC lagbara lati fun awọn ẹgbẹ oṣelu ni gbedeke lati ṣeto idibo abẹnu wọn yatọ si ohun to wa ninu atunto ofin eto dibo ọdun 2026.
Ọrọ yii ti yọri si igbẹjọ ati idajọ to tako ara wọn, eyii to ti n mu ki awọn ẹgbẹ oṣelu kan kọminu lori ipo wọn lẹyin ti eto idibo abẹnu wọn waye lẹyin gbedeke ti INEC kede ṣaaju.
Idajọ keji to tako ara wọn
Rogbodiyan naa abẹrẹ lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu Youth Party lọ sile ẹjọ pe INEC kọja aye rẹ labẹ ofin lẹyin to kede gbedeke ọjọ ti awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ṣe eto idibo abẹnu wọn.
Ninu alaye rẹ, o ni abala 29, 31, 32, 82 ati 84 atunto ofin eto idibo ti ọdun 2026 ti kede gbedeke ọjọ ti awọn ẹgbẹ oṣelu ni lati ṣe eto idibo abẹnu, nitori naa, INEC ko lagbara lati yi i pada.
Ninu idajọ rẹ, adajọ M.G. Umar gba ohun ti YP sọ wọle.
Adajọ naa sọ pe INEC ko lagbara labẹ ofin lati kede tabi sọ ọjọ pato, tabi ko fun awọn ẹgbẹ oṣelu ni gbedeke ọjọ ti wọn gbọdọ ṣe eto idibo abẹnu wọn.
Ile ẹjọ ọhun wa wọgile atunto ti INEC ṣe si asiko ti awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ pari gbogbo eto idibo abẹnu wọn.
Amọ ṣa, idajọ mii to waye lẹyin ẹjọ YP tun ti sọ pe INEC lagbara lati ṣe ohun to ṣe ṣaaju gẹgẹ bii agbara ti ofin to da silẹ fun un.
Ọrọ ti da idarudapọ silẹ lọkan awọn araalu ti wọn n woye boya o yẹ ki awọn adajọ maa ta ko ara wọn ninu idajọ ti wọn n gbe kalẹ.
Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ẹgbẹ to ṣeto idibo abẹnu lẹyin ọgbọn ọjọ oṣu Karun un?
Ọpọ eeyan lo ti n woye ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn ẹgbẹ oṣelu to ti ṣeto idibo abẹnu wọn lẹyin ọgbọn ọjọ oṣu Karun un, ọdun 2026.
Idajọ ti YP gba n tumọ si pe awọn ẹgbẹ oṣelu yoo ni lati gbọkan le gbedeke to wa ninu iwe ofin eto idibo Naijiria dipo gbedeke ti INEC fun wọn.
To n tumọ si pe ireti ṣi wa fun awọn ẹgbẹ ti wọn ṣeto idibo abẹnu wọn lẹyin gbedeke INEC, iyẹn to jẹ lẹyin ọgbọn ọjọ, oṣu Karun un, ọdun 2026.
Amọ ṣa, ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti INEC wa bayii ba sọ pe aṣẹ INEC ni yoo leke, o n tumọ si pe oniruru igbẹjọ lo si ṣeeṣe ko waye lori ọrọ naa.
Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe, oniruru igbẹjọ wọnyii le ṣakoba fun eto ti INEC ti ṣe silẹ fun idibo ọdun 2027.
Awọn ẹgbẹ oṣelu ti ọrọ yii le ṣakoba fun
Akọkọ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu yii ni African Democratic Congress (ADC) ti igbimọ rẹ sọ pe wọn gbọdọ tun eto idibo abẹnu wọn ṣe.
Ọrọ yii yọ awọn ẹgbẹ oṣelu nla-nla bii All Progressives Congress (APC), Peoples Democratic Party (PDP), ati Nigeria Democratic Congress (NDC) silẹ latari pe wọn tete ṣe eto idibo abẹnu wọn ṣaaju gbedeke INEC ọhun.