Nàìjíríà kéde èròńgbà láti kó àwọn èèyàn rẹ̀ ní South Africa padà sílé bí ìwọ́de tako àwọn àjòjì ṣe tún peléke síi

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba Naijiria ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ko gbogbo awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa to fẹ pada si orilẹ ede baba wọn páda sile.

Igbesẹ yii lo n waye bi iwọde tako awọn ajoji ṣe n peleke si ni South Africa, tawọn orilẹ ede si n kọminu lori awọn eeyan wọn to wa ni South Africa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, Kimiebi Ebienfa sọ fun BBC pe awọn ti n ṣayẹwo awọn ti wọn ti wọn ti fi ifẹ han lati pada sile amọ to ni awọn ko i tii le sọ iye eeyan ti wọn maa da pada sile ni pato.

O ni lẹyin ti ayẹwo ba ti pari ni awọn maa mọ iye eeyan ti wọn fẹ pada si Naijiria ati pe awọn ko i tii mu ọjọ ti wọn maa bẹrẹ si ni ko awọn eeyan naa pada sile.

Eyi fi han pe Naijiria ti darapọ mọ awọn orilẹ ede to fẹ ko awọn eeyan wọn kuro ni South Africa latari ikọlu tawọn eeyan naa n ṣe si wọn.

Ṣaaju asiko yii ni ijọba Naijiria ti ṣekilọ fawọn eeyan rẹ to n gbe ni South Africa lati w ani oju lalakan fi n ṣọri lẹyin tawọn ọmọ bibi ilẹ South Africa ṣe bẹrẹ ikọlu sawọn ajoji to n gbe ni orilẹ ede naa.

Ajọ to n ri si ọrọ ọmọ Naijiria to n gbe nilẹ okeere, Nigerians in Diaspora Commission, NiDCom lọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin sọ pe oniruuru iroyin nipa iwọde to la itajẹsilẹ lọ ni awọn n gbo pe o waye ni South Africa.

Ajọ naa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma ba a ẹnikẹni ni gbolohun a sọ tabi fa wahala, ki wọn si jina si gbogbo ibi ti iwọde ti n waye, ki wọn si maa gbọ iroyin ni gbogbo igba lati mọ bi nnkan ṣe n lọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ṣekilọ fawọn ọmọ Naijiria lati ma gbiyanju lati gbẹsan tabi gbe igbesẹ lati kọlu awọn ọmọ South Africa to n gbe ni Naijiria.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹnikẹni ti wọn ba mu pe o gbe igbesẹ bẹẹ ni wọn maa fi ẹsun ọdaran kan, to si maa foju wina ofin.

Awọn ilẹ Africa to n ko awọn eeyan wọn kuro ni South Africa

Lati igba ti iwọde ati ikọlu sawọn ajoji ti n waye ni South Africa ni awọn orilẹ ede kọọkan ti bẹrẹ igbesẹ lati ko awọn eeyan wọn kuro.

Ghana lo ti kọkọ ko awọn eeyan rẹ, ti awọn abala akọkọ si ti balẹ si orilẹ ede wọn lati ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un.

Lara awọn orilẹ ede ti wọn fẹ ko awọn eeyan wọn ni:

  • Naijiria

Igbesẹ lati ko awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa ti n lọ lọwọ gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣe sọ.

Bi o tilẹ jẹ pe Naijiria ko i tii mọ iye awọn eeyan ti wọn maa ko, wọn ni ijiroro ati ayẹwo ṣi n lọ lọwọ.

  • Malawi

Malawi sọ pe awọn naa ti n gbe igbesẹ lati ko awọn eeyan wọn kuro ni SoutH Africa.

Atẹjade ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni orilẹ ede naa sọ pe awọn eeyan to ba fi ifẹ han lati kuro ni orilẹ ede naa ni wọn maa ko kuro nibẹ.

Bakan naa ni wọn kede awọn ilana ti wọn maa gba lati fi ko awọn eeyan wọn kuro ni kete ti wọn ba ti pari gbogbo igbesẹ.

  • Mozambique

Ni ibẹrẹ ọsẹ yioi ni awọn alaṣẹ orilẹ ede sọ pe ọmọ Mozambique meji ni wọn pa si South Africa Mossel Bay.

Bakan naa ni wọn ni eeyan marun-un to jẹ ọmọ Mozambique lo ti padanu ẹmi wọn latari ikọlu naa.

Mozambique ni awọn eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹta lo ti pada sile to si ṣeeṣe ki ọpọ mii tun pada sii.

  • Ghana

Ghana ti n gbero lati tun ko awọn ọmọ orilẹ ede rẹ mii kuro ni South Africa lẹyin ti wọn ti ko awọn akọkọ.

Awọn mii ti Ghana fẹ ko kuro ni South Africa ni ko i tii ribi kuro latari bi ijọba South Africa ko ṣe fun wọn laṣẹ lati f oni ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un ti wọn fẹ gbera.

Minisita fọrọ ilẹ okeere Ghana, Samuel Okudzeto Ablakwa sọ pe awọn ti ṣeatn lati ko awọn eeyan wọn mii kuro.