You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìgbákejì alága ìjọba ìbílẹ̀ l'Ekiti tí ọlọ́pàá ló jí ara rẹ̀ gbé dèrò àtìmọ́lé
Igbakeji alaga ijọba ibilẹ Ilememeje l'Ekiti, Grace Ogunleye, ti dero atimọle lẹyin ti aṣiri tu.
Ogunjọ osu karun ọdun 2026 niroyin kan jade wi pe wọn ji arabinrin Ogunleye, igbakeji alaga ijọba ibilẹ ilejemeje gbe lọ nipinlẹ Ekiti.
Eyi lo ṣokunfa b'awọn oṣiṣẹ agbofinro ṣe bọ soju iṣẹ lati doola arabinrin naa.
Ọjọ Kejì ti iṣẹlẹ naa waye lawọn ọlọpaa ri obinrin naa.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn ọlọpaa kọ lati yọnda rẹ, tori pe iwadii wọn lori ọrọ naa fi han pe arabinrin Ogunleye mọọ mọ ji ara rẹ gbe ko le fi rowo gba lọwọ ijọba ni.
Leyin o reyin, igbakeji alaga ijọba ibilẹ ilejemeje naa ati awọn meji mii pada dero ile ẹjọ majisreeti to wa niluu Ado Ekiti.
Adajọ majisreeti tile ẹjọ naa, Abayomi Adeosun, wa paṣẹ lọjọ keta osu kẹfa ọdun 2026, wi pe ki wọn fi arabinrin Ogunleye satimọle ọgba ẹwọn ti ilu Ado Ekiti.
Adajọ Adeosun wa sun igbẹjọ oun siwaju digba ti amọran yoo jade lori ọrọ naa, tori pe ọkan o jokan ẹsun to ni i ṣe pẹlu ipete pero lati ji ara ẹni gbe nile ẹjọ ka siwọn lẹsẹ.
Ṣaaju ni Họnarebu Pius Alaba Dada, alaga ijọba ibilẹ ilejemeje ipinle Ekiti ti koro oju si iṣẹlẹ jiji ara ẹni gbe eyi to ni i ṣe pẹlu igbakeji rẹ
Họnarebu Dada sapejuwe ọrọ naa bi eyi ti ko ṣee feti gbọ rara to si bani lọkan jẹ.