You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yinka Alaseyori ṣàlàyé ara rẹ̀ lórí fídíò tó ṣe nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso
Ilumọọka akọrin ẹmi, Yinka Alaseyori, ti tọrọ aforijin lọwọ ọmọ Naijiria lori fidio kan to ṣe nipa iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọ atawọn olukọ l'Ogbomoso, eyi ti ọpọ eeyan ti n bu u le lori.
Yinka tọrọ aforijin ninu fidio kan to gbe sori ayelujara l'Ọjọru ọjọ kẹta oṣu Kẹfa yii ninu eyi to ti sọ pe oun kabamọọ pe ọpọ eeyan lo ri oun bi abiyamọ ti ko bikita nipa awọn ọmọ ti wọn ji gbe.
Alaseyori ṣalaye wi oun o foju kikere wo iṣẹlẹ ijinigbe naa pẹlu fidio ti oun ṣe.
Akọrin ẹmi naa sọ pe ''ni ọjọ meji sẹyin ni mo ṣe fidio nipa awọn ọmọde ti wọn ji gbe, eyi to si ta ba ijọba atawọn lajọ lajọ.
Awọn eeyan kan si lọ ge diẹ lara fidio naa to to wakati kan ati aabọ.
Amọ, nigba ti mo ji lanaa ni mo ri wi pe ọpọ ọmọ Naijiria ni inu wọn ko dun si mi nitori fidio ọhun.''
Alaseyori ni ọrọ tawọn eeyan n sọ soun ti ba oun lọkan jẹ, o si tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan papaa julọ awọn obi awọn ọmọ to wa lakata awọn ajinigbe.
Gbajugbaja olorin ẹmi naa sọ pe ''gbogbo eeyan lo mọ mi daadaa wi pe mi o le ronu bayẹn laelae.
Ẹyin abiamọ, ẹ ma binu, ẹ forijin mi, mi o le ronu bayẹn laelae, ẹ forijin mi.''
Ṣaaju ni Yinka ti sọ ninu fidio kan to gbe jade wi pe kawọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju lati maa gbadura lori eto aabo to mẹhẹ.
Alaseyori tọrọ aforijin yii lẹyin ti ọpọ eeyan ti sọ oriṣiiriṣii ọrọ kobakungbe si i lori ayelujara.
Bakan naa ni o tun sọ pe ijọba papaa julọ Aarẹ Bola Tinubu n gbiyanju agbara rẹ lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria .
O ni ijọba n gbiyanju lati doola awọn to wa lakata awọn ajinigbe.
Ọrọ yii lo bi ọpọ eeyan ninu ti wọn si bẹrẹ sii bu u lori itakun ayelujara.
Ọpọ eeyan lo da a lohun wi pe ijọba lo gbọdọ wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ wi pe adura nikan ko le yanju ọrọ naa.
Ijinigbe to waye ni ijọba ibilẹ Oriire niluu Ogbomoso ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ ti wọn si n ke si ijọba lati doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa kiakia.