Bí ilé aṣojú-ṣòfin ṣe fòńtẹ̀ lu àbá ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, wo ìlànà ìṣẹ́ wọn, àǹfààní àti ewu rẹ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lojuna ati wa ọna abayọ si iṣoro ai si aabo to kari orilẹede Naijiria, Ile igbimọ Aṣoju ti da aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ kọọkan lorilẹede yii.

Orukọ ti wọn fun aba naa ni: Aba kan to wa fun ayioada ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999, lati fi aaye silẹ fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ atawọn ohun to ba farapẹ ẹ.

Lasiko ti wọn dibo lori aba naa lati gba a wọle, aṣofin 288 lo faramọ ọn, nigba ti awọn mẹrin sọ pe awọn ko fẹ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ.

Bi aba yii ba pada di ofin, yoo fi aaye silẹ fawọn ọlọpaa ijọba apapọ lati wa lọtọ, awọn to wa fun ipinlẹ naa yoo si lagbara lati mojuto aabo ipinlẹ kaluku wọn.

O pẹ ti ọpọ eeyan ti n beere ọlọpaa ipinlẹ lorilẹede yii, bi eto aabo si ṣe n fojoojumọ buru si i lo mu kawọn aṣoju-ṣofin gbe e yẹwo bayii.

Ki lo wa ninu aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?

Labẹ aba tuntun yii, ọlọpaa ijọba apapọ ko ni i yọju si iṣẹ awọn tipinlẹ, afi awọn eyi to ba le gidi ti apa ipinlẹ ko ka.

Gomina ipinlẹ tọrọ kan ni yoo pe ọlọpaa apapọ ki wọn too le dide iranwọ fun wọn.

Bakan naa ni aba tuntun yii n pe fun ayipada nipa bi wọn ṣe n yan ọlọpaa sipo.

Ninu aba naa ni wọn ti ni ki Aarẹ maa yan ọga agba ọlọpaa pata, pẹlu imọran latọdọ igbimọ apapọ ọlọpaa Naijiria, ṣugbọn aba naa sọ pe gomina ni yoo maa yan kọmiṣanna ọlọpaa fun ipinlẹ rẹ.

Yoo maa yan kọmiṣanna naa lara awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ fun ilu rẹ, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ni yoo si pada buwọlu u.

Ninu aba yii, gomina lagbara lati paṣẹ fun kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ rẹ lori ọrọ aabo ilu.

Ṣugbọn bi kọmiṣanna naa ba ri i pe aṣẹ ọhun ko ba ofin mu, tabi ti lodi si ofin iṣẹ ọlọpaa, wọn le dari ọrọ naa si ọdọ igbimọ ọlọpaa ijọba apapọ, ohun ti awọn iyẹn ba si sọ ni abẹ ge.

Ṣugbọn ṣa, aba tuntun yii ṣi nilo kawọn aṣofin agba pinnu lori rẹ ko to le di ofin.

Bakan naa ni ìdá meji ninu mẹta ninu awọn ile igbimọ aṣofin Naijiria gbọdọ buwọ lu u, ki Aarẹ too fọwọ si i pe ko di ofin.

Nigba to n ṣalaye lori aba yii, Igbakeji Abẹnugan ile igbimọ aṣoju, Benjamin Kalu,sọ pe ọpọ apero lo ti waye lori ọrọ yii, bẹẹ ni wọn ti gbe e yẹwo daadaa.

Ki ni ewu to wa ninu idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?

O ti pẹ gidi ti ọrọ nipa idasilẹ ọlọpaa yii ti n waye lorilẹede Naijiria, ọpọ eeyan lo si gbagbọ pe ohun to yẹ lati ni ni.

Ṣugbọn awọn nnkan wa ti awọn awoye ọrọ n kọminu si ninu idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, lara awọn nnkan naa si ni pe:

Awọn gomina le lo agbara ọwọ wọn lati lo awon ọlọpaa naa sibi ti wọn ba fẹ.

Ẹru keji to n ba awọn eeyan ni pe gomina le sọ ọlọpaa ipinle rẹ di irinṣẹ ti yoo fi maa ba awọn alatako ja, ti wọn yoo si maa da rogbodiyan silẹ pẹlu aṣilo agbara.

Koda, wọn le lo wọn lati da eto idibo ru gẹgẹ bi oju tawọn awoye fi wo o.

Amọ awọn to gbe aba yii kalẹ ti sọ pe iru awọn nnkan wọnyi ko le waye.

Wọn ni awọn ti ṣe awọn eto ti yoo dena aṣilo agbara.

"Ẹ dẹ́kun ìdúnàá-dúrà pẹ̀lú àwọn agbésùnmọ̀mí"

Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin Naijiria ti rọ awọn ijọba ipinlẹ kaakiri orilẹede yii lati dẹkun idunaa-dura pẹlu awọn agbesunmọmi, agbebọn.

Ikilọ yii waye pẹlu alaye pe idunaa-dura pẹlu awọn eeyan yii ko le tan iṣoro to wa nilẹ, kaka bẹẹ o tun le jẹ ọna kan fun wọn lati maa lagbara idojukọ araalu si i.

Bakan naa ni ile ni ki ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria atawọn to n ri si aabo lori ayelujara, ri i daju pe wọn tọpasẹ awọn agbebọn to n lo oju opo ayelujara yii, ki wọn si mu wọn ṣinkun.

Wọn fi kun un pe paapaa awọn ti wọn n lo oju opo TikTok lati ba awọn eeyan sọrọ, ti wọn yoo si tun maa ṣafihan owo nla ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn ji gbe.

Arọwa yii lo waye lẹyin ti Aṣofin Sunday Karimi, koro oju si ikọlu to waye ni Kogi laarin ọsẹ yii, nibi ti awọn agbebọn ti pa eeyan mẹta nijọba ibilẹ Kabba/Bunu.