Àwọn agbébọn ti ń dúnkokò láti wọ ilẹ̀ Ibadan - Balogun ké gbàjarè

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Balogun ilẹ Ibadan ati eekan ninu igbimọ Olubadan, Oba Tajudeen Ajibola ti ke gbajare lori ẹsun pe awọn Fulani to jẹ agbebọn n gbero lati ṣe ikọlu si ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.
Ọba Ajibola sọrọ yii nibi ifilọlẹ awọn alaṣẹ tuntun fun ẹgbẹ Agbekoya to waye niluu Ibadan.
Balogun naa rọ ẹgbẹ awọn agbẹ lati wa ni oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn si wa iṣọkan lojuna ati wa ni igbaradi fun didena idunkoko eto aabo ti yoo ba koju ilu naa atawọn ilu to wa ni agbegbe rẹ.
O rọ awọn Agbekoya naa lati ji giiri nitori awọn Fulani ti n dunkoko lati ṣekọlu si Ibadan.
Balogun naa tẹmpẹlẹmọ pe o pọn dandan lati maa ṣamulo awọn ohun ti awọn babanla Yoruba fi jinki wọn lati da aabo bo ara wọn ati pe wọn ko gbọdọ gba ipinya laaye.
Nigba to n sọrọ, Aarẹ agba fun ẹgbẹ Agbekoya kaakiri Naijiria, Oloye Kamorudeen Okikiola sọ pe awọn ti ṣetan lati koju awọn agbebọn kankan ti wọn ba n gbero lati ṣekọlu sawọn ilu kankan ni ilẹ Yoruba.
Okikiola ṣalaye pe lakọ ni awọn wa bi ibọn ati pe awọn n gbọ pe awọn agbebọn n bọ wa silẹ Yoruba, pe oogun tawọn babanla wọn fi silẹ fun wọn ṣi wa lati fi koju awọn eeyan naa.
O fẹsun kan pe awọn Fulani darandaran lo ti n ṣekọlu sawọn agbẹ, ti wọn si n da ẹran jẹ oko awọn eeyan ni ilẹ Yoruba fun igba pipẹ, to si ni niṣe ni iṣẹlẹ naa n peleke si lọdọọdun.
O fi kun pe ọpọ akitiyan ni ẹgbẹ Agbekoya ti ṣe lori eto aabo Naijiria amọ ti wọn maa n mọọmọ lati ma pariwo gbogbo awọn nnkan ti wọn n ṣe sita.
"Ọpọlọpọ ipa lati ko lori eto aabo ni ẹkun iwọ oorun Naijiria ṣugbọn a kii pariwo bii awọn to maa n kede pe awọn ti pa agbebọn mẹwaa ati ogun."
O ni gbogbo igbesẹ awọn jẹ lati dena atawọn ọdaran lati maa di awọn agbẹ lọwọ lati ṣe iṣẹ wọn.
Okikiola juwe iṣelẹ kan to waye ni ipinlẹ Ondo nibi to ti sọ pe ẹgbẹ Agbekoya gba itusilẹ awọn eeyan kan tawọn agbebọn ji gbe.
O fi kun pe awọn ọmọ ẹgbẹ Agbekoya to gba itusilẹ awọn eeyan naa tun fi pampẹ ofin mu awọn agbebọn ti wọn ṣiṣẹ ibi naa.
O tẹsiwaju pe awọn n ri atilẹyin ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo to si jẹ pe awọn ṣi ba aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ṣe ipade lori eto aabo.
Gomina Seyi Makinde, ẹni ti Olubadamọran rẹ lori eto aabo, Abayomi Fagbenro ṣoju fun juwe awọn agbẹ gẹgẹ bi awọn ti wọn ṣe pataki si eto aabo ilu.
Makinde ṣalaye pe ibaṣepọ toi lagbara lo wa laaarin ipese ounjẹ ati eto aabo bo ṣe woye pe aisi aabo le mu ikurẹtẹ ba ipese ounjẹ ati pipese ounje to to laaarin ilu.
O ni laisi aabo, ko le si ounjẹ to to laaarin ilu, ti ko si le si ounjẹ bi ko ba si aabo fun awọn agbe.

Oríṣun àwòrán, WhatsApp
Ṣaaju ni lẹta kan ti n lọ lori ayelujara eyi ti eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ A M Sodiq kọ ranṣe si ileeṣẹ Ologun Naijiria lati fẹsun kan pe awọn agbebọn tun ti n gbero lati ṣekọlu sawọn aaye kan ni ẹkun ila oorun, iwọ oorun ati aarin gbungbun ariwa Naijiria to fi mọ guusu iwọ oorun Naijiria.
Ninu lẹta naa ni wọn ti fẹsun kan pe lara awọn ibi ti awọn agbebọn naa n gbero lati ṣekọlu si ile ijọsin Aguda, awọn ile ijọsin mii, awọn ile ẹkọ alakọọbẹrẹ, atawọn ile ẹkọ girama.
O sọ ninu lẹta naa pe awọn eeyan n gbero yii bi awọn akẹkọọ ṣe n gbaradi lati wọle fun saa eto ẹkọ 2026/2027.
O wa rọ awọn ẹṣọ aabo Ologun Naijiria lati tete ji giri si ojuṣe wọn, ki wọn mojuto eto aabo ko to di pe awọn oniṣẹ ibi naa ṣe iṣẹ ọwọ wọn.






























