Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n lẹ òkò mọ́ Peter Obi ní Benue? Ohun tí a mọ̀ rèé

Peter Obi lo n sọrọ lọwọ yii pẹlu ẹrọ gbohungbohun to mu dani

Oríṣun àwòrán, Peter Obi/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni ọrọ tun yiwọ fun Peter Obi nigba ti wọn fi oṣelu han an nipinlẹ Benue to ti fẹẹ lọ ba wọn kẹdun.

Niṣe la gbọ pe awọn olufẹhonuhan gbegi dina opopona marosẹ Gboko to wa niluu Makurdi, lati ma jẹ ki oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, Peter Obi, wọle.

Peter Obi lo lọ si ipinlẹ Benue pẹlu erongba lati kẹdun ikọlu to waye lagbegbe Yelwata laipẹ yii, nibi ti ọpọ eeyan ti ba ikọlu naa lọ sọrun aremabọ, ti ọpọ si farapa.

Ninu fọnran to n fo kaakiri ori ayelujara ni awọn kan ti fẹsun kan ijọba ipinlẹ Benue wi pe awọn lo wa nidi bi awọn tọọgi ṣe dena de Peter Obi, lati ma jẹ ko wọ ipinlẹ naa.

Ọkan lara awọn fọnran to n lọ lori ayelujara ni awọn kan ti n pariwo, "a ko fẹ Peter Obi,".

Itosi ileeṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu ti a mọ si NAF ati papakọ ofurufu Makurdi la gbọ pe awọn olufẹhonuhan naa ti gbegi dina mọ Obi ati ikọ rẹ fun ọpọ wakati.

Wo ohun tí Peter Obi sọ

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nibi iṣẹlẹ naa, Peter Obi sọ pe o le ni ọgbọn iṣẹju toun fi wa lori iduro, ti wọn ko jẹ koun kọja lọ sibi toun ti fẹẹ ba awọn eeyan kẹdun.

"Wọn sọ fun mi pe awọn ọdọ kan, ti amugbalẹgbẹ pataki fun ijọba, ti pinnu lati di opopona, lati rii pe nko kọja lọ sibẹ," Obi sọ bẹẹ fawọn akọroyin.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ṣapejuwe gbigbe igi dina naa, gẹgẹ bi eyi to ku diẹ kaato, to si fẹsun kan gbogbo awọn to wa nidi iwan aa wi pe wọn n lo ebi ati awọn ọdọ alaimọkan fun ọrọ oṣelu.

"Awọn iwa jagidijagan ti wọn n mu wa si orileede yii ko jẹ itẹwọgba rara. Wọn n pa awọn eeyan lojoojumọ nipinlẹ Benue. Awọn eeyan fẹẹ jẹ ki wọn mọ pe awọn pẹlu wọn, idi ree ti mo fi wa sibi laaarọ yii, lati ọna to jin, ṣugbọn ti wọn n sọ fun mi pe ko saaye, gẹgẹ bi ẹyin naa ṣe ti ri I," Obi kọminu.

O wa sọ pe wọn gbe awọn olufẹhonu han naa dide lai wo awọn nnkan ti yoo tẹyin rẹ yọ.

"Wọn n lo awọn ọdọ yii lati ṣe nnkan wọnyi ni. Ohun ti wọn n ṣe lonii yoo ni atubọtan to n pada bọ wa ba wọn. Wọn ko mọ eyi. O ṣeni laanu wi pe ẹnikan jokoo si ọfiisi rẹ, o si faaye gba iru nnkan to n ṣẹlẹ yii."

O wa fidi rẹ mulẹ pe boun ṣe wa si ipinlẹ naa, kii ṣe nnkan to bọ, tabi wi pe oun yọ wa. O sọ pe gbogbo eeyan lo ti mọ ṣaaju pe oun yoo wọ ipinlẹ Benue.

"Gbogbo eeyan lo mọ pe mo n bọ nibi lonii. Kii ṣe nnkan aṣiri rara wi pe mọ n bọ," Obi jẹ ko di mimọ.

Kí ni àwọn èèyàn n sọ?

Awọn eeyan lori ayelujara ti bẹrẹ sii sọ pe ọna lati ṣe ipolongo fun idibo aarẹ ni igbesẹ ti Peter Obi gbe, nipa erongba rẹ lati ba awọn eeyan kẹdun.

Ọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni @Christbeloved00, lori ikanni 'X', sọ pe ko yẹ ko jẹ pe asiko ti oṣelu ti wọle de lo yẹ ki Obi ṣẹṣẹ pinnu lati ba awọn eeyan kẹdun ni Yelwata.

"Ṣugbọn ṣa, ki lo de ti o fi duro de asiko ipolongo oṣelu ki o too pinnu lati bẹ awọn eeyan wo lori ikọlu yii? To ba jẹ nitori awọn ara Yelwata ni lootọ, ki lo de ti o ko ti wa tipẹ ṣaaju asiko yii?", ọkunrin naa beere bẹẹ.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ọjọ kẹtala si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 ni ikọlu Yelwata ṣẹlẹ, nigba ti awọn janduku agbebọn ya wọ ilu naa lati pa awọn eeyan nipakupa.

Awọn ti ko din ni marundinlaadọta la gbọ pe awọn janduku agbebọn naa pa loru ọganjọ, ọjọ naa.

Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn darandaran lo ṣe ik]olu ọhun nigba naa.

Yatọ si awọn ti wọn pa danu yii, ọpọ ile ni awọ janduku agbebọn naa dana sun.