Mo ti tẹ̀ fún Ọlọ́rùn, mi ò lè yẹ̀bá fún èèyàn mọ́, ẹ lọ fọkàn balẹ̀, mo máa dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2027 – Oriyomi Hamzat

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X
Oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, ti sọ pe oun ko ni yẹba fun ẹnikẹni fun eto idibo gomina ọdun 2027 nipinlẹ Oyo.
Oriyomi toun ati Họnarebu Olakunle Busari tawọn eeyan mọ si Gudugudu jọ n sọ pe awọn mejeeji ni oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo sọrọ yii ninu fọnran kan to fi lede lori ayelujara.
Oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo FM niluu Ibadan ṣalaye ninu fidio naa wi pe oun ko ni yẹba fun ẹnikẹni tori oun ti yẹba fun Ọlọrun.
''Mo ti yẹba fun Ọlọrun lo jẹ ki n wa ṣe oṣelu tori pe oṣelu ko si ninu ohun to wu mi tẹlẹ.
To ba jẹ wi pe mo ti n gbero lati ṣe oṣelu ni, n ko ba ti maa ṣiṣẹ rẹ bọ tipẹ.
Awọn iṣẹ kan wa ti mo ti ṣe sẹyin nigba ti mo ha ọkọ Micra ati alupupu ọkada fawọn eeyan.
Bakan naa ni mo tun fawọn eeyan kan lowo, wọn sọ fun mi pe n ko ni akọsilẹ awọn nnkan yii nigba ti mo beere fun un.
Awọn ọmọlẹyin mi sọ pe mo ni mi o nilo rẹ tori mo sọ pe mi o ni ṣe oṣelu nigba naa,’’ Oriyomi lo sọ bẹẹ.
Ọmọ Amusa ni Ọlọrun ni oun gba fun un loun ṣe fẹ dupo oṣelu, o ni ko si ṣee ṣe ki eeyan yẹba lẹẹmeji.
Oriyomi fikun ọrọ rẹ pe awọn araalu lo pe oun wi pe koun jade dupo oṣelu.
O wa rọ awọn alatako rẹ wi pe ki wọn maa da omi tutu sawọn eeyan lọkan mọ.
Oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo FM sọ pe ‘’ẹyin araalu ẹ lọ fọkan bale tori n ko to bẹẹ lati wa sọ fun yin pe n ko ṣe mọ.
Gbogbo ẹyin ti ẹ ti lọ forukọ silẹ tori Oriyomi, ẹyin ti ẹ ti pinnu wi pe ẹ o dibo fun igba akọkọ tori Oriyomi, ẹyin ti ẹ ti sọ pe ki aye tẹ le Oriyomi, ẹ fọkan balẹ.
Emi Abdulrahman Oriyomi Hamzat, n ko ni yẹba fun ẹda Ọlọrun kankan.
A o dibo, a o wọlẹ, a o si ṣe daadaa laṣẹ Ọlọrun.''





























