Àwọn ẹ̀ṣọ́ Iru Ekun yóò máa lo ìfúnpá, olóńdè àti ayẹta yàtọ̀ sí ìbọn - Sunday Igboho ṣàlàyé níbi ìfilọ́lẹ̀ Iru Ekun ní ìpínlẹ̀ Èkó

Oríṣun àwòrán, Koiki Media/Facebook
Oloye Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti ṣe ifilọlẹ ẹṣọ eleto aabo Iru Ekun nipinlẹ Eko.
L'Ọjọbọ ọkọ kẹwaa oṣu Kẹsan an yii ayẹyẹ ifilọlẹ naa waye niluu Eko nibi tawọn eeyan peju pesẹ si.
Ninu ọrọ rẹ, Igboho sọ pe Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, sọ foun pe ijọba lawọn lawọn ni ẹṣọ eleto aabo Iru Ekun.
Owo Baba Dami ni Ooni tun fi da oun loju wi pe gbogbo agbara tawọn ọba ilẹ Yoruba ba ni lawọn ori ade naa yoo fi gbaruku ti ẹṣọ eleto aabo Iru Ekun ko le ṣe aṣeyọri.
Igboho tun fi idi rẹ mulẹ wi pe ijọba yoo ṣe igbaradi fawọn ẹṣọ Iru Ekun ni ipinlẹ Eko ki wọn to bẹrẹ iṣẹ.
O ni lẹyin ti ijọba ba ṣe igbaradi fawọn ẹṣọ Iru Ekun tan ni ijọba yoo fun wọn ni kaadi idanimọ ki wọn to le maa ṣiṣẹ.
Igboho ṣalaye wi pe aṣẹ ijọba lo jẹ kawọn ẹṣọ Iru Ekun lanfaani lati maa lo ibọn gidi, o ni ẹṣọ Iru Ekun kii lo ibọn ṣakabula tori ibọn to wa lọwọ awọn ọdaran naa ko dẹrun.
''Bi awọn ọdaran ba yinbọn si wa, awa naa yoo da a pada fun wọn lẹsẹ kẹsẹ.
Amọ, ikilọ fun gbogbo ẹṣọ Iru Ekun l'Eko ni pe ẹ ma ṣe bi ẹni pe ẹ mọ iṣẹ ṣe ju ọlọpaa, DSS ati sọja lọ.
Nitori pe awọn ẹṣọ eleto aabo yii ni wọn ti n ṣiṣẹ aabo ilu tipẹ tipẹ, awa kan fẹ ṣe iranwọ fun wọn nitori pe a jẹ ọmọ Yoruba.
Awa ti a jẹ ọmọ oniluu la o maa tọ awọn ẹṣọ eleto aabo yoku sọna lati ṣẹgun awọn ọdaran atawọn agbesumọmi ti wọn n da alaafia ilu ru,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
Owo Baba Dami ni nnkan ti Iru Ekun fi yatọ ni pe awọn ẹṣọ maa n ṣe ogun ibọn sara.
''Awa yoo maa lo ayẹta awọn baba wa tawọn oloyinbo n pe ni ''bullet proof'', a o de igbadi ati ifunpa, a o si kọju ija sawọn ọdaran tori a ko fẹ wọn mọ niluu wa,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
Igboho ni awọn alamojuto kan yoo tun wa ti wọn yoo maa kaakiri gbogbo ilẹ Yoruba lati maa wo bawọn ẹṣọ Iru Ekun ṣe n ṣiṣẹ.






























