Àwọn agbébọn jí àwọn olórí ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí gbé ní Zamfara, lẹ́yìn àdúrà àṣeyọrí ìbò fún Tinubu

Awọn janduku agbebọn kan ni wọn gbe ibọn dani yii ninu igbo

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni ọgọrun awọn olori ẹlẹsin Islam ti wọn lawọn janduku agbebọn ti jigbe nipinlẹ Zamfara bayii, ti ko sit ii sẹni to le sọ pato ibi ti wọn wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Ijọba ibilẹ Talata Mafara ni awọn janduku agbebọn naa ti ṣe ikọlu ọhun, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.

BBC News Yoruba gbọ pe awọn aṣoju ẹsin naa lọ si ile alakoso agba fun igbimọ ipolongo idibo fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Abdul'aziz Abubakar Yari lati ṣeto adura fun aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu naa ninu eto idibo ọdun 2027.

Asiko ti wọn n bọ lati ibi eto adura naa la gbọ pe awọn janduku yii da wọn lọna pẹlu ibọn ati awọn nnkan ija oloro.

Oniroyin iṣẹlẹ kayeefi lẹkun Ariwa-Iwọ-Oorun, Bakatsine lo fidi iroyin ọhun mulẹ loju opo 'X' rẹ lọjọ Abamẹta to kọja.

Bakatsine jẹ ko di mimọ pe awọn aṣoju ẹsin naa to le ni ẹgbẹrun meji, leyi ti wọn jẹ agba Imaamu ati Aaf ani wọn lọ sile Sẹnetọ Yari lati lọ gba adura naa ṣaaju eto idibo 2027.

Oniroyin naa sọ pe lara awọn Imaamu ti wọn jigbe ni Imaamu Yahuza to jẹ Imaamu akọkọ ni Dogon Madacci; Imaamu Magawata Abdullahi, Malaamu Shehu Dakko; Imaamu Bala Fagon; ati Na'ibi Tasi'u ti Tungar Nagudai.

Kaakiri ijọba ibilẹ Bakura ati Talata Mafara la gbọ pe awọn olori ẹlẹsin naa ti rin irin ajo lọ sie Yari lati kopa nibi eto adura ọhun.

Awọn olori ẹlẹsin naa gbadura fun alaafia, iṣọkan ati aṣeyọri Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, to fi mọ gbogbo oludije sipo oṣelu lẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2027.

Bakatsine ṣapejuwe ikọlu ijinigbe naa gẹgẹ bi eyi to ko iporuru ọkan ba awọn eeyan, paapaa bo tun ṣe jẹ ile agba oloṣelu ni awọn olori ẹsin naa ti pe jọ.

Bakan naa lo sọ pe ikọlu tuntun yii lo ṣapejuwe ipo ti ọrọ eto aabo wa nipinlẹ Zamfara, nibi ti oniruuru ikọlu awọn agbebọn ati ijinigbe ti n waye ni gbogbo.

"Bi wọn ba le ji awọn eeyan gbe lasiko ti wọn lọ pejọ nile agba oloṣelu nilẹ Naijiria, ki ni yoo wa jẹ aridaju eto aabo fawọn araalu lasan?" Bakatsine beere bẹẹ.

Njẹ́ ọlọ́pàá ti gbọ́?

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, bẹẹ si ni wọn ko ti gbe atẹjade sita nipa iṣẹlẹ ọhun.