Ìdí tí ìjọba fi fòfin de títa ọtí tí kò bá ní nọ́mbà NAFDAC lára l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Ondo ti fi ofin de tita gbogbo oniruuru ọti lile ati awọn miran to n gba ẹnu wọle sinu ara, eyi ti ko ba ti ni ontẹ ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo, iyẹn NAFDAC.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin iku awọn ti ko din ni ọgbọn, to waye laipẹ yii nipinlẹ naa.
Atẹjade ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ naa, Idowu Ajanaku fi sita lọjọ Abamẹta to kọja fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lati dẹkun iku awọn araalu lọna aitọ.
Ajanaku sọ pe iku awọn eeyan ọgbọn naa lo nii ṣe pẹlu ọti lile ti wọn mu, to si lawọn ko tun gbọdọ jẹ ko tan kaakiri ipinlẹ ọhun.
Àwọn wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí?
O tun fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti kọmiṣanna feto ilera, Dokita Banji Awolowo-Ajaka fidi rẹ mulẹ pe eeyan mọkandinlọgbọn ku lẹyin ti wọn mu ọti lile tan, ati pe iṣẹle to to ọgọta iru rẹ ni awọn ti ṣe akọsilẹ rẹ.
Kọmiṣanna feto ilera sọ pe awọn mẹta lo ti wa lori bẹẹdi, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, nigba ti wọn n wo iṣesi awọn mẹtadinlọgbọn miran.
O ni ida marundinlaadọrun awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni wọn jẹ ọkunrin ti wọn wa laaarin ọdun mẹrindinlogun si marundinlọgọta.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn agbegbe bii Orita Odigbo, Araromi-Obu, Newtown, Odole, Okele ati Oniparaga ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Ajaka tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn aisan bii ori fifọ, ara riro, irẹwẹsi ara, ailẹ min daadaa ati awọn miran lo jẹyọ lara awọn eeyan naa.
O ni ọrọ ilera awọn miran tete yiwọ patapata, leyi to ṣokunfa iku wọn laarin wakati perete.
A gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀
"Irufẹ awọn aisan to n jẹyọ ati itan bi awọn eeyan ṣe n kagbako aisan lo mu ifura nipa lilo ọti lile to ti gbabọde lọwọ.
"Ṣugbọn ṣa, a ko tii fidi rẹ mulẹ daadaa nipa ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan naa," Komiṣanna feto ilera sọ bẹẹ.
Bakan naa ni Kọmiṣanna feto ilera sọ pe awọn ti gba ẹjẹ ati itọ awọn eeyan mẹrindinlogoji lati lọ fi ṣayẹwo, lati mọ ojulowo ohun to ṣẹlẹ, fun iwadii kikun.
Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun
Siwaju sii ni ijọba ipinlẹ naa jẹ ko di mimọ pe wọn ti ran awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ eto ilera sawọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, fun iwadii nipa ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan naa.
Ijọba wa rọ awọn araalu lati dẹkun rira ọti lile ti wọn ko le fidi ibi ti wọn ti ṣe e mulẹ, paapaa awọn nnkan miran ti wọn ko mọ ipilẹ rẹ.
Bakan naa ni ijọba sọ pe ohunkohun ti ajọ NAFDAC ko ba ti fontẹ lu, ni awọn araalu yago fun patapata, ko ma ba a tun ṣe akoba.
Siwaju sii ni ijọba sọ pe ki gbogbo awọn alagbata ati awọn to n ta awọn ọti ati ohun mimu ati jijẹ wọnyi dẹkun rira ọja ti wọn ko ba mọ ibi ti wọn ti wa.
"Ẹnikẹni ti a ba ri wi pe o tapa si aṣẹ ati ilana yii, yoo foju winna ofin," ijọba sọ bẹẹ.
Àwọn agbófinró náà bẹ̀rẹ iṣẹ́ ìwádìí
Ijọba sọ pe gbogbo awọn ileeṣẹ agbofinro patapata ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati gbogun ti tita ati rira awọn ohun ti ko ni ontẹ ileeṣẹ alakoso tọrọ kan nipinlẹ naa.
Ijọba tun rọ gbogbo araalu lati maa w ani ojufo, ki wọn si tete pariwo sita, nigba ti wọn ba kofiri ohunkohun to mu ifura dani.
Siwaju sii ni wọn sọ pe igbesẹ yii lo wa lara igbesẹ Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa lati ṣawari ẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan, lati le daabo bo awọn araalu, ki iru iṣẹlẹ bẹẹ ma ba a tun waye.





























