Kí ló dé tí àwọn ẹ̀yà Tigray ní Ethiopia ṣe ń sọ pé àgbà Olóyè Obasanjo kò tolé?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti gbọnri lori ẹsun ti ikọ ajijangbara Tigray People's Liberation Front (TPLF) lorilẹede Ethipia pe agba rẹ ko tole ati pe o n ṣegbe sẹyin igun kan nibi ipade eto alaafia ti wọn n ṣe lati dena atunṣẹ ina ogun lagbegbe naa.
Oloye Ọbasanjọ lo n lewaju ikọ ipẹtu si aawọ eyi ti ajọ awọn orilẹede Afrika, AU gbe kalẹ lati wagbo dẹkun si aawọ to n waye laarin ikọ ọmọ ogun ijọba apapọ orilẹede Ethiopia ati ikọ ọmọogun ajijangbara TPLF pẹlu bi ina ogun ṣe n sọ ni ẹkun ariwa Tigray.
Oloye Ọbasanjọ sọ pe irọ ni ẹsun ti wọn fi n kan oun pe ijọba apapọ orilẹede Ethiopia lo n fun un laṣẹ ohun gbogbo to n ṣe.
Agbẹnusọ fun Oloye Ọbasanjọ, Kẹhinde Akinyemi ṣalaye pe, "yoo jẹ nnkan itiju fun ẹni ti wọn fi joye apẹtu si aawọ lati maa yọ aṣiri ọrọ ti wọn ba fi si ikawọ rẹ sita fun gbogbo aye lati gbọ nitori ṣekarimi"
Ẹgbẹ ajijagbara TPLF fẹsun kan Ọbasanjọ pe o n ṣegbe lẹyin igun kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọṣu kẹfa ni Ọbasanjọ bẹrẹ igbesẹ ipẹtusaawọ laari nigun mejeeji lẹyin ti iporuru ọkan n waye eto alaafia to waye lọdun 2022 le fo lọ.
Adehun alaafia naa to waye lọjọ keji oṣu kọkanla ọdun 2022 ni ilu Pretoria lorilẹede South Africa, lo fopin si aawọ ati ogun ọdun meji to ti n waye ni Tigray eleyii to ti gbẹmi ọpọlọpọ eeyan ti ẹgbẹlẹgbẹ miran si ti di alainile lori.
Laipẹ yii ni Ọbasanjọ rinrinajo lọ si olu ilu ẹkun Tigray, Mekelle nibi to ti jiroro pẹlu aarẹ ẹkun naa, Debretsion Gebremichael atawọn alaṣẹ miran lẹkun naa.
Nibayii, orilẹede Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi pẹlu ti kan saara si akọtun igbesẹ ipẹtusaawọ ti ajọ orilẹede Afrika, AU n gbe bayii.
Lọjọ karundinlọgbọ̀n oṣu kẹjọ ni ileeṣẹ aṣoju ijọba amẹrika lorilẹe Ethiopia kede pe ipa pataki ni ajọ AU ni lati ko pẹlu bi ibẹru ati ifoya ti n gbakoso lawọn ileto to wa lẹkun ariwa orilẹede Ethiopia.
Ẹgbẹ ajijagbara TPLF fẹsun kan Ọbasanjọ pe o n ṣegbe lẹyin igun kan
Ninu atẹjade kan to fi sit ani ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa oṣu kẹsan , ẹgbẹ ajijagbara TPLF sọ pe igbesẹ ti Obasanjọ n gbe lọwọ yii 'ti n mu ifura dani' lori boya igbesẹ rẹ ko maa gbe sẹyin ijọba apapọ orilẹede Ethiopia.
Wọn ni ijiroro to waye kẹyin lori ọrọ naa "ko tii maa ni ipa kankan to niiṣe pẹlu alaafia ti wọn n lepa".


























