Ṣé lóòótọ́ làwon jàndùkú agbébọn fẹ́ ṣèkọlù sáwọn ilé ijọ́sìn àti ọjà ní ìpínlẹ̀ Osun? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Osun ti sọ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti kepe awọn adari ẹsin Islam atawọn ọmọlẹyin Kristi wi pe ki wọn wa lojufo tori o ṣee ṣe kawọn agbesunmọmi ṣe ikọlu sawọn ṣọọṣi, mọṣalaaṣi ati ọja ni ipinlẹ naa.
Ajọ DSS ni a gbọ pe o sọ ninu ikilọ ti o fi lede naa wi pe awọn agbesunmọmi fẹ ṣe eleyii lati da eto idibo ọdun 2027 to n bọ ru.
L'Ọjọru ọsẹ to kọja ni iroyin sọ pe ajọ DSS ṣepade pẹlu awọn musulumi atawọn krristẹni l'Osun nibi ti wọn ti gbawọn nimọran wi pe ki wọn wa lojufo.
Igbesẹ yii waye lẹyin iṣẹ iwadii kan tawọn ẹṣọ eleto aabo naa ṣe eyi ti wọn lo fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku agbebọn n gbero lati ṣekọlu silẹ Yoruba lati da ibẹru-bojo silẹ ṣaaju ibo aarẹ ọdun 2027.
Alhaji Mustapha Olawuyi to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn musulumi nipnlẹ Osun sọ fun iwe iroyin Punch wi pe otitọ ni ipade naa lori ọrọ eto aabo waye pẹlu ajọ DSS.
Alhaji Olawuyi ṣalaye wi pe ajọ DSS ti ṣe alakalẹ oniruuru ọna ti wọn fẹ fi dena mawọn janduku agbebọn naa.
''A gbọdọ ṣọra ṣe bayii ki a si wa lojufo, tori awọn agbesunmọmi ti n gbiyanju lati wọ ipinlẹ Osun tipẹ''
Adari awọn musulumi nipinlẹ Osun sọ pe ''a gbọdọ ṣọra ṣe bayii ki a si wa lojufo, tori awọn agbesunmọmi ti n gbiyanju lati wọ ipinlẹ Osun tipẹ.
A ti da awọn darandaran ti wọn le ni igba ti wọn fẹ fi ipa wọ ipinlẹ Osun pada laipẹ yii.
Awọn kan tun wa ti wọn gun ọkada wa si ipinlẹ Osun ti wọn ko gbọ ede wa, gbogbo wọn ni a da pada sibi ti wọn ti n bọ.
Iṣẹ ribi ribi ni ajọ DSS n ṣe pẹlu bi wọn ṣe n tawa lolobo wi pe ka wa lojufo.''
Aarẹ awọn musulumi nipinlẹ Osun fikun ọrọ rẹ pe iwadii fi han pe awọn janduku agbebọn n gbero lati ṣekọlu si apa guusu Naijiria papaa julọ ilẹ Yoruba lati da rogbodiyan silẹ ki eto idibo le ma ba waye.
Alhaji Olawuyi ṣalaye pe ajọ DSS gbawọn nimọran wi pe kawọn ile ijọsin ma gba ẹnikẹni laye lati gbe ọkọ sun mọ ibi tawọn eeyan ba ti pejọ lati jọsin papọ.
''Wọn ni a ko gbọdọ gba ẹnikẹni laye lati sun sinu mọṣalaaṣi, bakan naa ni wọn tun kilọ fun wa lati ṣọra fawọn ọlọkada atawọn darandaran to le gbabọde.
Ajọ DSS tun rọ awa musulumi wi pe ki a gbọ ọlọdẹ si gbogbo mọṣalaaṣi,'' Alhaji Olawuyi lo sọ bẹẹ.
''Ajọ DSS ni a ko gbọdọ gba ẹnikẹni laye lati gbe ọkọ siwaju ṣọọṣi tori wọn le fi ado oloro sinu rẹ''
Alaga ajọ ọmọlẹyin Kristi CAN nipinlẹ Osun, Pasitọ John Adeleke, naa ṣalaye wi pe ajọ DSS ni kawọn sọ fun gbogbo ijọ Ọlọrun atawọn ile ẹkọ lati wa lojufo lori ọrọ aabo.
Alufaa Adeleke sọ pe ''ajọ DSS fidi rẹ mulẹ pe awọn agbesunmọmi ti ka ipinlẹ Osun mawọn ipinlẹ ti wọn fẹ ṣe ikọlu si ṣaaju eto idibo aarẹ to n bọ.
DSS sọ pe ipinlẹ Kaduna ni wọn fẹ gba lọ si Jos, lati ibẹ ni wọn ti fẹ wa si ipinlẹ Osun.
Awọn ibi tawọn agbesunmọmi naa n gbenro lati ṣekọlu si ni ṣọọṣi, mọṣalaaṣi, ọja, ile ẹkọ atawọn ibi tawọn eeyan ba ti pejọ.
''Ajọ ọtẹlẹmuyẹ rọ wa wi pe ki a wa lojufo ni gbogbo ṣọọṣi kaakiri ipinlẹ Osun.
Ajọ DSS ni a ko gbọdọ gba ẹnikẹni laye lati gbe ọkọ siwaju ṣọọṣi tori wọn le fi ado oloro sinu rẹ.
Bakan naa ni DSS tun ni ka ṣọra pẹlu iṣọ oru kawọn janduku agbebọn naa maa lọ fi okunkun boju ṣiṣẹ ibi, wọn'' alaga CAN lo sọ bẹẹ.






























