Ìjọba jáwé ìkìlọ̀ fún South Africa bí ọmọ Nàìjíríà méjì míì ṣe tún pàdánú ẹ̀mí wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọmọ Naijiria meji ṣe tun padanu ẹmi wọn ni orilẹ ede South Africa.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣe sọ, wọn ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn nigba ti awọn gbọ nipa iroyin iku Biṣọọbu Taiwo Michael Fakunle ati James Uchechukwu.
Atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Oluwafemi Adeniyi fi lede bu ẹnu atẹ lu iku awọn eeyan naa paapaa lasiko tawon eeyan ilẹ Africa ṣe n koju ipa ti ikọlu Xenophobic ati Aphrophobic n ni lara awọn eeyan ni South Africa.
Ni ile Biṣọọbu Taiwo Michael Fakunle to wa ni Kensington, Johannesburg ni wọn pa a si lọjọ Kẹrin, oṣu Kẹsan-an gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ.
Bakan naa ni wọn sọ pe James Uchechukwu jade laye nigba tawọn ọlọpaa Sommerset, Cape Town lo ọna ipa lati fi fọrọ wa lẹnuwo ni ọjọ Karun-un, oṣu Kẹsan-an.
Ijọba Naijiria ni o jẹ ohun to ba eeyan lọkan jẹ wi pe awọn ẹṣọ aabo to yẹ ki wọn maa da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, awọn to yẹ ki wọn maa ṣe atunse sawọn nnkan to ti bajẹ ni wọn tun ṣokunfa iku ajoji.
Ijọba wa n rọ awọn alaṣẹ tọrọ kan lati ṣe iwadii iku awọn eeyan naa, ki wọn si fi imu awọn to ba lọwọ ninu rẹ jofin.
Atẹjade ileeṣẹ naa ni awọn nigbagbọ pe ijọba South Africa maa gbe igbesẹ ni kiakia, ti wọn si ni awọn gbagbọ pe ijiroro nikan lo le tan iṣoro to n waye lori Xenophobia ati Aphrophobia.
Femi Fani-Kayode sọrọ lori iku Biṣọọbu Fakunle
Aṣoju Naijiria nilẹ South Africa, Femi Fani-kayode naa ti da si ọrọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn padanu ẹmi wọn ni South Africa naa.
Ninu atẹjade kan to gbe sori ikanni ayelujara rẹ, o ni iyalẹnu lo jẹ fun oun lati gbọ nipa iku Biṣọọbu Michael Taiwo Fakunle tawọn eeyan kan lọ pa sinu ile rẹ ni Johannesburg lọjọ Kẹrin, oṣu Kẹsan-an.
"Lẹyin ti ọpọlọpọ idunkoko, awọn to pa a lọ sile rẹ, wọn si yinbọn pa a mọle."
Fani-Kayode ni iku awọn eeyan yii lo sọ awọn ọmọ Naijiria to ti padanu ẹmi wọn ni South Africa di mẹjọ ninu ọdun yii nikan.
O fi kun pe ko din mẹrin ninu awọn eeyan naa to jẹ pe latọwọ awọn ọlọpaa South Africa ni iku wọn ti wa.
Bakan naa lo ni awọn ọmọ Naijiria to le ni ọgọrun-un ni wọn ti padanu ẹmi wọn laaarin ọdun 2022 si asiko yii to si jẹ pe ọwọ awọn ọlọpaa South Africa ni iku awọn to le ni ọgbọn ninu wọn ti wa.
"Eleyii ko le jẹ itẹwọgba. A n kepe ijọba South Africa lati gbe igbesẹ akin lati da aabo bo awọn eeyan wa to wa lorilẹ ede wọn, ki wọn si fi awọn to lọwọ ninu ipaniyan yii atawọn to n gbero lati pa awọn mii jofin."
Aṣoju Naijiria naa sọ pe ko yẹ lati pa eeyan mii nitori wọn jẹ ọmọ Naijiria, ti eyi si n ba ọpọ ọmọ Naijiria to w ani orilẹ South Africa lẹru nitori wọn o mọ ohun to le ṣẹlẹ si wọn.
Naijiria, atawọn orilẹ ede mii bii Ghana, Malawi, Kenya ati Zimbabwe ti n ko awọn eeyan wọn kuro ni South Africa nitori aabo ẹmi ati dukia wọn.
'Ohun to buru jai ni' – South Africa fi itara han lori ofin ile aṣofin Naijiria
Ijọba Naijiria sọ pe awọn ti fi ẹhonu wọn si ajọ Ecowas ati ajọ iṣọkan ilẹ Africa, AU lori bi awọn ọmọ South Africa ṣe n ṣekọlu sawọn ọmọ orilẹ ede mii to n gbe ni South Africa.
Ni ọjọ Ẹti ni ile aṣofin Naijiria sọ pe awọn ti wọgile ṣiṣe irinajo lọ silẹ South Africa fun igba kan ati pe awọn ko ni kopa nibi eto awọn aṣofin kan ti South Africa n ṣe agbatẹru rẹ.
Ijọba Naijiria ni ipaniyan, ikọlu ati bawọn ọmọ South Africa ṣe n ba ohun ini awọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ ilẹ Africa mii to n gbe ni orilẹ ede naa ti pọju, to si n nilo amojuto.
Minisita fọrọ ilẹ okeere South Africa, Ronald Lamola sọ fun ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ orilẹ ede naa, SABC pe ipinnu Naijiria naa jẹ ohun to buru.
O fi kun pe South Africa ṣetan lati jiroro, to si fi kun pe Naijiria ti pese orukọ awọn ọmọ Naijiria to ti padanu ẹmi wọn sinu ikọlu naa eyi ti wọn fidi rẹ mulẹ.
Lamola fi kun pe ko yẹ ki wọn foju tẹmbẹlu ajọṣepọ laaarin orilẹ ede mejeeji, to si fidi rẹ mulẹ pe awọn n ṣiṣẹ lati koju ipenija tawọn ọmọ Naijiria n koju kaakiri South Africa to fi mọ ni Johannesburg.
Aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio ati olori ile aṣojuṣpfin, Abbas Tajudeen juwe igbesẹ wọn bi ohun ti wọn nilo ni idahun si idunkoko tawọn ọmọ Naijiria n koju nilẹ okeere.





























